ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 9/22 ojú ìwé 12-14
  • Kí Ló Burú Nínú Wíwá Owó?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ló Burú Nínú Wíwá Owó?
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Ìgbì Ìfẹ́ Ọrọ̀ Àlùmọ́nì”
  • “Wọ́n Pilẹ̀pinnu Láti Di Ọlọ́rọ̀”
  • ‘Rírì Sínú Ìrunbàjẹ́’
  • Rírí Ìwọ̀ntúnwọ̀nsì
  • Ṣé Owó Ni Gbòǹgbò Ohun Búburú Gbogbo?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Èrò Tó Yẹ Ká Ní Nípa Owó
    Jí!—2015
  • Owó
    Jí!—2014
  • Kí Lèrò Tó Tọ́ Kéèyàn Ní Nípa Owó?
    Jí!—2007
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 9/22 ojú ìwé 12-14

Awọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Kí Ló Burú Nínú Wíwá Owó?

“NÍ GIDI, owó ni ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ láyé.” Ohun tí ọmọ ilẹ̀ Britain náà, George Bernard Shaw, tí í ṣe òǹkọ̀wé eré onítàn, sọ nìyẹn. Ìwọ ha fara mọ́ ohun tó sọ bí? Bóyá èrò rẹ fẹ́rẹ̀ẹ́ jọ ti Tanya, ọmọ ọdún 17, tó sọ pé: “N kò fẹ́ láti di ọlọ́rọ̀, kí owó máà ṣáà wọ́n mi ni.” Avian ọ̀dọ́ pẹ̀lú ka owó sí ohun tó wúlò, kì í ṣe bí ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ láyé, àmọ́ bí ohun wíwúlò tí a fi ń ṣe nǹkan. Ó sọ pé: “Ohun kòṣeémánìí ni owó jẹ́ nítorí àwọn ohun tí mo nílò, bí aṣọ àti ọkọ̀ wíwọ̀.”

O ha mọ̀ pé Bíbélì sọ ohun kan tí ó jọ ìyẹn bí? Ó sọ ní Oníwàásù 7:12 (NW) pé: “owó . . . jẹ́ fún ìdáàbòbò.” A ṣàpèjúwe ipò àìní gẹ́gẹ́ bí “olùdènà gíga fún ayọ̀ ẹ̀dá ènìyàn.” Níní ànító owó sì lè dáàbò bò ọ́—ó kéré tán dé ìwọ̀n àyè kan—kúrò lọ́wọ́ àwọn ìṣòro tí ipò àìní sábà máa ń mú wá. Owó tún lè bá ọ dín bí ìjábá àìròtẹ́lẹ̀ ì bá ṣe le tó kù. Phyllis ọ̀dọ́ sọ pé: “Bíbélì sọ pé, ‘ìgbà àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀ ni ó ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wa.’ A kò mọ ìgbà tí nǹkan lè nira fún wa, nítorí náà, a ní láti fi owó pa mọ́.” (Oníwàásù 9:11, NW) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé owó lè dà bí ohun tó ṣe pàtàkì sí ọ nísinsìnyí, ó lè kó ipa tí ó tilẹ̀ ṣe pàtàkì jù bẹ́ẹ̀ lọ nínú ọjọ́ ọ̀la rẹ.

“Ìgbì Ìfẹ́ Ọrọ̀ Àlùmọ́nì”

Ṣùgbọ́n bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àníyàn kan nípa níní ànító owó dára, tí ó sì bójú mu, owó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ di ìsúnniṣe tipátipá fún àwọn èwe kan. Nígbà tí a bi àwọn èwe tó lé ní 160,000 léèrè pé, “Kí ni o fẹ́ jù lọ nínú ìgbésí ayé?,” ìpín 22 nínú ọgọ́rùn-ún sọ pé, “Láti di ọlọ́rọ̀.”

Láìsíyèméjì, ohun tí ń fún ìyánhànhàn fún owó yìí níṣìírí ni ìwé ìròyìn Newsweek pè ní “ìgbì ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́nì” tí ó ti gba gbogbo ayé kan. Martin, ọmọ ọdún 18, sọ pé: “Mo jẹ́ olùfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́nì gan-an, mo sì nífẹ̀ẹ́ sí àwọn nǹkan tí àwọn tó ṣe é jẹ́ àwọn lóókọlóókọ. Mo gbà gbọ́ dájúdájú pé owó ní ń pinnu irú ọjà tí o máa rí rà. Nítorí náà, mo máa ń náwó púpọ̀ gan-an sórí ohun tí mo bá fẹ́.” Kì í ṣe Martin nìkan ni èwe tí ‘ń náwó púpọ̀ gan-an.’ Ìwé ìròyìn U.S.News & World Report sọ pé: “Lọ́dún tó kọjá, àwọn ọmọ tí ọjọ́ orí wọ́n wà láàárín ọdún 12 sí 19 [ní United States] náwó tó pọ̀ jù lọ tí wọ́n tí ì ná rí, wọ́n fi àròpọ̀ bílíọ̀nù 109 dọ́là ra nǹkan, iye tó fi ìpín 38 nínú ọgọ́rùn-ún ju ti 1990 lọ.”

Bí ó ti wù kí ó rí, ibo ni àwọn èwe ti ń rí owó tí wọ́n fi ń ra gbogbo aṣọ, ike ìkósọfúnnisí olórin, àti ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà tuntuntuntun? Ìwé ìròyìn U.S.News & World Report sọ pé: “Nǹkan bí ìdajì gbogbo àwọn ọmọ tí wọ́n wà láàárín ọdún 16 sí 19 ni wọ́n ní iṣẹ́ àṣepawọ́.” Bí iṣẹ́ tí a ń ṣe lẹ́yìn ilé ẹ̀kọ́ bá wà ní ipò ìwọ̀ntúnwọ̀nsì, ó lè ní àwọn àǹfààní tirẹ̀, bíi kíkọ́ èwe kan láti bójú tó ẹrù iṣẹ́. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn èwe kan ń ṣe àṣejù nínú èyí. Ìwé ìròyìn Newsweek sọ pé: “Àwọn afìṣemọ̀rònú àti àwọn olùkọ́ ń rí ipa náà lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ [tí ń ṣiṣẹ́]. Àyè díẹ̀ ni wọ́n ní fún iṣẹ́ àṣetiléwá, àwọn olùkọ́ tí wọ́n sì máa ń rí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ti rẹ̀ tẹnutẹnu, tí ń tiraka láti wà lójúfò nígbà gbogbo sábà máa ń hùwà pa dà nípa dídín ohun tí wọ́n retí kù.”

Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìwọ̀nba díẹ̀ lára àwọn èwe tí ń ṣiṣẹ́ ló ń fẹ́ láti jáwọ́ lára àwọn ohun tí ń mú owó wọlé fún wọn. Vanessa ọ̀dọ́ sọ pé: “Ilé ẹ̀kọ́ ṣe pàtàkì, bẹ́ẹ̀ sì ni owó ṣe pàtàkì. Owó kì í yọ nídìí iṣẹ́ àṣetiléwá.” Báwo ni wíwá owó ti ṣe pàtàkì sí ọ tó? Wíwá ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ rẹ̀ ha ni ìlépa rẹ nínú ìgbésí ayé bí?

“Wọ́n Pilẹ̀pinnu Láti Di Ọlọ́rọ̀”

Bíbélì jíròrò àwọn ìbéèrè yìí kan náà. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn wọnnì tí wọ́n pilẹ̀pinnu láti di ọlọ́rọ̀ máa ń ṣubú sínú ìdẹwò àti ìdẹkùn àti ọ̀pọ̀ àwọn ìfẹ́ ọkàn òpònú àti aṣenilọ́ṣẹ́, èyí tí ń ri ènìyàn sínú ìparun àti ìrunbàjẹ́. Nítorí ìfẹ́ owó ni gbòǹgbò onírúurú ohun aṣeniléṣe gbogbo, àti nípa nínàgà fún ìfẹ́ yìí a ti mú àwọn kan ṣáko lọ kúrò nínú ìgbàgbọ́ wọ́n sì ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrora gún ara wọn káàkiri.”—Tímótì Kíní 6:9, 10.

Ó dájú pé Pọ́ọ̀lù mọ ohun tó ń sọ. Kí ó tó di Kristẹni, ó ti jẹ́ ọ̀kan lára àwọn aṣáájú ìsìn tí a mọ̀ sí “àwọn Farisí,” tí Bíbélì ṣàpèjúwe bí “olùfẹ́ owó.” (Lúùkù 16:14) Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àpọ́sítélì náà kò dẹ́bi fún wíwá owó fúnra rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó kìlọ̀ fún àwọn tí wọ́n “pilẹ̀pinnu láti di ọlọ́rọ̀” tàbí, bí ìtumọ̀ míràn ti sọ ọ́, fún àwọn tí wọ́n “gbé ọkàn wọn sórí dídi ọlọ́rọ̀.” (Phillips) Àmọ́, kí ló burú tó bẹ́ẹ̀ nípa ṣíṣe ìyẹn?

Gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ṣe ṣàlàyé, irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ “máa ń ṣubú sínú ìdẹwò àti ìdẹkùn.” Òwe 28:20 (NW) ṣe àlàyé tí ó jọra nígbà tí ó wí pé: “Ẹni tí ó bá ń ṣe kánkán láti jèrè ọrọ̀ kì yóò máa bá a nìṣó láti jẹ́ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀.” Ní ríronú pé àwọn kò ní ànító, àwọn èwe kan ti fàbọ̀ sórí olè jíjà.

A gbà pé ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn èwe kò ní ronú nípa jíjalè. Àmọ́, àwọn kan lè hu àwọn ìwà tó léwu bákan náà. Ìwé ìròyìn Christianity Today sọ pé: “Àwọn ògbóǹkangí kan gbà gbọ́ pé tẹ́tẹ́ títa látajù ti di àṣà tí ń yára pọ̀ sí i tí àwọn ọ̀dọ́langba ń sọ di bárakù jù lọ.” Ní àdúgbò kan ní United States, “ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìpín 90 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn ọ̀dọ́langba tó ti ra tíkẹ́ẹ̀tì tẹ́tẹ́ láìbófinmu nígbà tí wọ́n wà ní ìpele gíga ní ilé ẹ̀kọ́ gíga.” Àwọn èwe kan fàbọ̀ sórí àwọn ìgbésẹ̀ tí ó tilẹ̀ burú jù bẹ́ẹ̀ lọ. Matthew, ọmọ ọdún 16, sọ pé: “Kò yá láti rí iṣẹ́ tó dára. Nítorí náà, ibi ṣíṣòwò àti títa àwọn nǹkan ni mo ti ń rí èyí tó pọ̀ jù lọ lára owó tí mo ní. . . . [Tẹ́lẹ̀ rí], mo máa ń ta [oògùn líle] lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan.”

‘Rírì Sínú Ìrunbàjẹ́’

Òtítọ́ ni pé níní owó lè fúnni ní èrò pé a wà lómìnira. Ṣùgbọ́n bí Pọ́ọ̀lù ṣe ṣàlàyé, níkẹyìn, lílépa owó lè sọni di ẹrú “ìfẹ́ ọkàn òpònú àti aṣenilọ́ṣẹ́, èyí tí ń ri ènìyàn sínú ìparun àti ìrunbàjẹ́” ní gidi. Òtítọ́ ni, gbàrà tí ìfẹ́ owó bá ti gbá ọ mú, ojúkòkòrò, owú oníkúpani, àti àwọn ìfẹ́ ọkàn aṣenilọ́ṣẹ́ mìíràn lè gba àkóso. (Fi wé Kólósè 3:5.) Àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn ’Teen sọ pé, àwọn ọ̀dọ́langba kan lè di onílara nípa àwọn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ àti aṣọ tí àwọn èwe mìíràn ní tó bẹ́ẹ̀ “tí wọn óò fi banú jẹ́.” Àpilẹ̀kọ náà fi kún un pé, nígbà míràn, irú ìlara bẹ́ẹ̀ “máa ń burú dé orí kíkórìíra ara ẹni, ọ̀dọ́langba kan kì í sì í lè ronú nípa ohunkóhun àyàfi ohun tí kò ní.”

Nígbà náà, ṣàkíyèsí pé kì í ṣe pé ìfẹ́ ọkàn fún ọrọ̀ lè mú kí ènìyàn “ṣubú sínú ìdẹwò” nìkan ni, àmọ́ ó tún lè mú kí ènìyàn ‘rì sínú ìparun àti ìrunbàjẹ́.’ Alálàyé Bíbélì náà, Albert Barnes, sọ pé: “Èrò àfọkànyàwòrán náà jẹ́ ti rírì, bí ọkọ̀ òkun kan àti gbogbo àwọn tó wà nínú rẹ̀, ti jùmọ̀ rì. Ìparun náà jẹ́ pátápátá. Ayọ̀, ìwàfunfun, ìfùsì, àti ọkàn pa run pátápátá.”—Fi wé Tímótì Kíní 1:19.

Nígbà náà, ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ tọ́ pé, ìgbanilọ́kàn pátápátá “ìfẹ́ owó ni gbòǹgbò onírúurú ohun aṣeniléṣe gbogbo.” Ní àbáyọrí rẹ̀, ọ̀pọ̀ ti “ṣáko lọ kúrò nínú ìgbàgbọ́ wọn sì ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrora gún ara wọn káàkiri.” Wo àpẹẹrẹ èwe kan tí a óò pè ní Rory. Nígbà tí ó jẹ́ ọmọ ọdún 12, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ta tẹ́tẹ́. Ó rántí pé: “Ó jẹ́ ọ̀nà kan láti rí owó láìṣe ohunkóhun.” Láìpẹ́ láìjìnnà, ó ti kó sínú gbèsè ọgọ́rọ̀ọ̀rún dọ́là, ó sì ń pa àwọn ọ̀rẹ́, ìdílé, àti iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ tì. Ó jẹ́wọ́ pé: “Mo gbìyànjú láti jáwọ́” àmọ́ léraléra ni ó ń kùnà. Ó ń bá a lọ ní ‘fífi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrora gún ara rẹ̀ káàkiri’ títí di ìgbà tí ó fi wá ìrànlọ́wọ́ nígbà tó pé ọmọ ọdún 19. Nípa bẹ́ẹ̀, òǹkọ̀wé Douglas Kennedy kò sọ àsọdùn nígbà tí ó pe ìlépa owó ní “ìrírí tí ń kó hílàhílo báni” nínú ìwé rẹ̀ Chasing Mammon.

Rírí Ìwọ̀ntúnwọ̀nsì

Nípa bẹ́ẹ̀, àmọ̀ràn Sólómọ́nì bá a mu gẹ́lẹ́ nísinsìnyí bí ó ti rí ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn pé: “Má ṣe làálàá láti jèrè ọrọ̀. Ṣíwọ́ kúrò nínú òye ara rẹ. Ìwọ ha ti jẹ́ kí ojú rẹ wò ó fìrí bí, nígbà tí kò jámọ́ nǹkan kan? Nítorí láìsí àní-àní, ó máa ń ṣe ìyẹ́ apá fún ara rẹ̀ bíi ti idì, a sì fò lọ sí ojú ọ̀run.” (Òwe 23:4, 5, NW) Ọrọ̀ àlùmọ́nì jẹ́ fún ìgbà díẹ̀, nítorí náà, ó jẹ́ ìwà òmùgọ̀ láti sọ lílépa ọrọ̀ di lájorí ète rẹ nínú ìgbésí ayé. Èwe Kristẹni kan tí ń jẹ́ Maureen sọ pé: “N kò fẹ́ kira bọ àwọn ìlépa onífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì pátápátá.” Ó wí pé: “Mo kàn mọ̀ pé ipò tẹ̀mí mi ni yóò jìyà rẹ̀, bí mo bá kira bọ wíwulẹ̀ máa wá owó.”

Òtítọ́ ni pé ohun kòṣeémánìí ni owó jẹ́. Níní ànító owó tí ń wọlé yóò jẹ́ kí o lè bójú tó àwọn ohun tí o nílò—tí ó bá sì ṣeé ṣe, kí o tilẹ̀ máa fi àwọn ohun ìní ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. (Éfésù 4:28) Kọ́ bí a ti ń ṣiṣẹ́ kára kí o baà lè ní owó láìṣàbòsí. Bákan náà, kọ́ bí o ṣe lè máa fowó pa mọ́, bí o ṣe lè wéwèé ìnáwó, àti bí o ṣe lè máa fi òye ná owó rẹ. Ṣùgbọ́n má ṣe sọ owó di ohun tí ó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé rẹ. Gbìyànjú láti ní ojú ìwòye wíwàdéédéé tí ẹni tó kọ ìwé Òwe 30:8 (NW) ní, tó fi gbàdúrà pé: “Má ṣe fún mi ní ipò òṣì tàbí ti ọrọ̀.” Nípa fífi ire tẹ̀mí sí ipò iwájú, ìwọ yóò lè jèrè irú ọrọ̀ tó dára jù lọ. Bí Òwe 10:22 (NW) ti sọ, “ìbùkún Jèhófà—èyíinì ni ohun tí ń sọni di ọlọ́rọ̀, kì í sì í fi ìrora kún un.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Ọ̀pọ̀ èwé ń fẹ́ láti lówó kí wọn baà lè bá àwọn ojúgbà wọn dọ́gba

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́