ORÍ 21
Kí Ni Mo Lè Ṣe Táwọn Òbí Mi Bá Ń Rí Sí Mi Ṣáá?
“Bí ọlọ́pàá ni Mọ́mì ṣe máa ń ṣe, ibi tí mo bá kù sí ni wọ́n máa ń wá. Mi ò tíì ní parí iṣẹ́ ilé tí wọ́n á ti bẹ̀rẹ̀ sí yẹ àwọn nǹkan tí mo ṣe wò, bóyá wọ́n á lè rí ibi tí mo ti ṣàṣìṣe.”—Craig.
“Kò sígbà táwọn òbí mi kì í rí ohun tí wọ́n máa bá mi wí lé lórí. Wọ́n ní kò sí nǹkan tí mo mọ̀-ọ́n ṣe rárá. Wọ́n á sọ̀rọ̀ sí mi lórí àwọn nǹkan tí mo ṣe níléèwé, nílé, nínú ìjọ, wọn kì í fi mí lọ́rùn sílẹ̀ rárá.”—James.
ṢÓ MÁA ń ṣe ẹ́ bíi pé kò sí nǹkan kan tó o ṣe tó tẹ́ àwọn òbí ẹ lọ́rùn rí? Àbí o rò pé awò tó ń sọ nǹkan di ńlá ni wọ́n fi ń wò ẹ́, ìyẹn ni pé wọ́n ń ṣọ́ ẹ lọ́wọ́ lẹ́sẹ̀, kò sì sí ohun tó o ṣe tó dáa tó lójú wọn?
Èwo nínú àwọn nǹkan tá a tò sísàlẹ̀ yìí ni wọ́n máa ń torí ẹ̀ sọ̀rọ̀ sí ẹ jù?
□ Yàrá ẹ ò mọ́ rí.
□ O ò mọ̀ ju tẹlifíṣọ̀n lọ.
□ O máa ń pẹ́ jù kó o tó sùn.
□ O ò mọ̀ ju oorun lọ.
Lórí ìlà tó wà nísàlẹ̀, kọ èyí tó máa ń bí ẹ nínú jù lọ lára àwọn nǹkan táwọn òbí ẹ máa ń tìtorí ẹ̀ sọ̀rọ̀ sí ẹ.
․․․․․
Ká sòótọ́, inú lè máa bí ẹ báwọn òbí ẹ bá ń pàṣẹ fún ẹ tí wọ́n sì ń wá àṣìṣe ẹ. Àmọ́ wo òdì kejì ẹ̀ ná: Báwọn òbí ẹ bá pa ẹ́ tì, tí wọn ò gbà ẹ́ nímọ̀ràn tí wọn ò sì bá ẹ wí, ṣe wàá gbà pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ ẹ? (Hébérù 12:8) Ká sòótọ́, ẹ̀rí pé àwọn òbí ẹ nífẹ̀ẹ́ ẹ ni ìbáwí jẹ́. Bíbélì sọ pé ‘ọmọ tí bàbá bá dunnú sí’ ló máa ń bá wí.—Òwe 3:12.
Bó o bá mọ̀ bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wàá máa dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn òbí ẹ pé wọ́n fẹ́ràn ẹ débi tí wọ́n fi ń tọ́ ẹ sọ́nà! Ó ṣe tán, o ṣì kéré, o ò sì nírìírí tó bẹ́ẹ̀. Bó pẹ́ bó yá, wàá nílò ìbáwí. Láìsí ìtọ́sọ́nà, “ìfẹ́-ọkàn tí ó máa ń bá ìgbà èwe rìn” lè lé ẹ bá.—2 Tímótì 2:22.
Ó Máa Ń Káni Lára!
Ká sòótọ́, “kò sí ìbáwí tí ó dà bí ohun ìdùnnú nísinsìnyí, bí kò ṣe akó-ẹ̀dùn-ọkàn-báni.” (Hébérù 12:11) Àgàgà tó o bá ṣì kéré. Kò sì yẹ kíyẹn yà ẹ́ lẹ́nu! Torí kò sẹ́ni tó ṣì mọ irú ẹni tó o máa jẹ́. O ṣì ń dàgbà, ìwọ alára ò sì tíì mọ ara ẹ. Torí náà, kò sí bí wọ́n ṣe lè rọra bá ẹ sọ̀rọ̀ tó tí kò ní bí ẹ nínú.
Bó ṣe yẹ kó rí náà nìyẹn, torí ohun táwọn èèyàn bá sọ nípa ẹ lè kan irú ojú tó o fi ń wo ara ẹ. Ohun táwọn òbí ẹ sì ń sọ nípa ẹ ṣe pàtàkì gan-an, torí ìyẹn máa nípa lórí irú ojú tí wàá fi máa wo ara ẹ. Torí náà, táwọn òbí ẹ bá bá ẹ wí tàbí tí wọ́n rí sí ẹ nítorí ohun kan tó ò ṣe dáadáa, ó lè bí ẹ nínú.
Ṣó wá yẹ kó o parí èrò sí pé kò sí nǹkan tó o mọ̀-ọ́n ṣe, tàbí pé o ò tiẹ̀ lè ṣe ohunkóhun yọrí torí pé àwọn òbí ẹ máa ń sọ ibi tó o kù sí? Rárá o. Gbogbo èèyàn pátá ni ò kúnjú ìwọ̀n torí pé aláìpé ni gbogbo wa. (Oníwàásù 7:20) Ara ẹ̀kọ́ sì ni àṣìṣe jẹ́. (Jóòbù 6:24) Bó bá wá jẹ́ pé àwọn òbí ẹ máa ń rí ọ̀rọ̀ sọ bó o bá ṣàṣìṣe àmọ́ tí wọ́n máa ń ṣe bíi pé wọn ò rí ẹ bó o bá ṣe ohun tó tọ́ ńkọ́? Ìyẹn lè dùn ẹ́ gan-an. Síbẹ̀, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé o ò já mọ́ nǹkan kan.
Ìdí Tí Wọ́n Fi Ń Rí sí Ẹ
Nígbà míì, àwọn òbí lè ṣìwà hù, kì í ṣe nítorí pé o ṣe nǹkan kan tí ò dáa, àmọ́ torí pé inú wọn ò dùn lásìkò yẹn. Ṣé mọ́mì ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ tibi iṣẹ́ dé ni? Bóyá ó rẹ̀ wọ́n? Wọ́n lè fìkanra ìyẹn mọ́ ẹ bó o bá da yàrá ẹ rú. Ṣé inú ń bí dádì ẹ torí pé ipò ìṣúnná owó ìdílé yín ò fara rọ? Ìyẹn lè jẹ́ kí wọ́n sọ̀rọ̀ láìronú jinlẹ̀ “bí ẹni pé pẹ̀lú àwọn ìgúnni idà.” (Òwe 12:18) Ká sòótọ́, irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ máa ń dunni gan-an. Àmọ́, kàkà kó o máa ronú lórí ohun tí ò dáa tí wọ́n ṣe sí ẹ, torí ìyẹn á túbọ̀ dá kún inú tó ń bí ẹ ni, yá a gbójú fo àṣìṣe wọn dá. Rántí pé: “Gbogbo wa ni a máa ń kọsẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà. Bí ẹnì kan kò bá kọsẹ̀ nínú ọ̀rọ̀, ẹni yìí jẹ́ ènìyàn pípé, tí ó lè kó gbogbo ara rẹ̀ pẹ̀lú níjàánu.”—Jákọ́bù 3:2.
Torí pé aláìpé làwọn òbí, ó máa ń ṣe àwọn náà bíi pé kò sí nǹkan kan tí wọ́n mọ̀-ọ́n ṣe. Ká sòótọ́, bó ò bá gbọ́ràn sí wọn lẹ́nu, o lè jẹ́ káwọn náà máa ronú pé àwọn ò tọ́ ẹ dáadáa ni. Bí àpẹẹrẹ, ìyá kan lè fìbínú sọ̀rọ̀ sí ọmọbìnrin ẹ̀ torí pé kò rọ́wọ́ mú nínú ìdánwò tí wọ́n ṣe níléèwé. Àmọ́, ohun tó ṣeé ṣe kí ìyá yẹn máa rò ni pé, ‘Ẹ̀rù ń bà mí, kó má lọ jẹ́ pé mi ò ṣe ojúṣe mi gẹ́gẹ́ bí ìyá torí mi ò ran ọmọ mi lọ́wọ́ láti ṣàṣeyọrí.’
Ní Sùúrù Tí Wọ́n Bá Ń Sọ̀rọ̀ sí Ẹ
Ohun yòówù tí ì báà jẹ́ tí wọ́n ń tìtorí ẹ̀ sọ̀rọ̀ sí ẹ, ìbéèrè tó ṣe pàtàkì ni pé, Báwo lo ṣe lè fara dà á? Ohun àkọ́kọ́ ni pé, má sọ ohunkóhun. Ìwé Òwe 17:27 sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó bá fawọ́ àwọn àsọjáde rẹ̀ sẹ́yìn kún fún ìmọ̀, ènìyàn tí ó ní ìfòyemọ̀ sì tutù ní ẹ̀mí.” Báwo lo ṣe lè rí i pé o “tutù ní ẹ̀mí” tí wọ́n bá ń gbé e gbóná fún ẹ? Gbìyànjú àwọn àbá wọ̀nyí:
Fetí sílẹ̀. Kàkà kó o máa gbawájú kó o máa gbẹ̀yìn torí pé o fẹ́ jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé o ò jẹ̀bi, panu ẹ mọ́, kó o sì gbọ́ ohun táwọn òbí ẹ ń bá ẹ sọ lágbọ̀ọ́yé. Ọmọ ẹ̀yìn náà Jákọ́bù sọ fáwọn Kristẹni pé kí wọ́n “yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ, lọ́ra nípa ìrunú.” (Jákọ́bù 1:19) Bó o bá ń gbó àwọn òbí ẹ lẹ́nu tí wọ́n bá ń bá ẹ sọ̀rọ̀, ńṣe ni wọ́n máa rò pé o ò fetí sóhun tí wọ́n ń sọ. Ìyẹn máa bí wọn nínú, ìgbà yẹn gan-an ni wọ́n á sì túbọ̀ tẹra mọ́ bíbá ẹ wí dípò kí wọ́n dákẹ́.
Pọkàn pọ̀. Nígbà míì, ó lè ṣe ẹ́ bíi pé báwọn òbí ẹ ṣe bá ẹ sọ̀rọ̀ yẹn ò dáa tó. Kàkà kó o máa ronú nípa ọ̀nà tí wọ́n gbà bá ẹ sọ̀rọ̀, pọkàn pọ̀ sórí ohun tí wọ́n bá ẹ sọ. Bi ara ẹ pé: ‘Èwo nínú àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ ló jóòótọ́? Ṣáwọn òbí mi ti bá mi wí lórí ọ̀rọ̀ yìí rí? Kí ló máa ná mi láti gbọ́ràn sí wọn lẹ́nu?’ Má gbàgbé pé kò sí bí ọ̀rọ̀ náà ṣe lè rí lára ẹ báyìí, ìfẹ́ ló sún àwọn òbí ẹ láti bá ẹ wí. Bó bá jẹ́ pé wọ́n kórìíra ẹ ni, wọn ò ní bá ẹ wí rárá.—Òwe 13:24.
Má ṣe bá wọn jiyàn. Bó ò bá báwọn òbí ẹ jiyàn, tó o sì gbà pé ohun tí wọ́n sọ yé ẹ, ńṣe lo fi ń dá wọn lójú pé o gba ohun tí wọ́n sọ. Bí àpẹẹrẹ, òbí kan lè sọ pé: “O ò tún yàrá ẹ ṣe rí, wúruwùru ló máa ń wà ṣáá. Bó ò bá lọ tún un ṣe báyìí, màá fojú ẹ rí màbo!” Ó lè jẹ́ pé lójú tìẹ kò sí nǹkan kan tó ṣe yàrá ẹ. Àmọ́, o lè ba nǹkan jẹ́ bó o bá sọ ọ́ kò wọ́n lójú. Ìwọ ṣáà gbìyànjú láti fojú táwọn òbí ẹ fi wo ọ̀ràn náà wò ó. Ó máa dáa bó o bá lè rọra sọ nǹkan bí: “Ẹ ò kúkú purọ́. Yàrá mi dọ̀tí lóòótọ́. Ṣé kí n lọ tún un ṣe báyìí ni àbí tá a bá jẹun alẹ́ tán?” Bó o bá ń gbà sí wọn lẹ́nu báyìí, wọn ò ní bá ẹ fà á ju bó ṣe yẹ lọ. Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, o ní láti gbọ́ràn sáwọn òbí ẹ lẹ́nu.—Éfésù 6:1.
Ní sùúrù. Bó o bá tiẹ̀ máa wí àwíjàre, kọ́kọ́ ṣe ohun táwọn òbí ẹ fẹ́ ná. Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí ń ṣàkóso ètè rẹ̀ ń hùwà tòyetòye.” (Òwe 10:19) Táwọn òbí ẹ bá ti rí i pé ò ń fetí sí wọn, àwọn náà á máa fẹ́ láti fetí sí ẹ.
Kọ èyí tó o gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ ṣiṣẹ́ lé lórí lára àwọn kókó mẹ́rin yìí síbí. ․․․․․
Ó Tó Bẹ́ẹ̀ Ó Jù Bẹ́ẹ̀ Lọ
Ṣé wàá fẹ́ fara da ìyà kó o lè wa góòlù jáde látinú ilẹ̀? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, Bíbélì sọ pé ọgbọ́n níye lórí ju ohun ìṣúra èyíkéyìí lọ. (Òwe 3:13, 14) Báwo lo ṣe lè di ọlọgbọ́n? Òwe 19:20 sọ pé: “Fetí sí ìmọ̀ràn kí o sì gba ìbáwí, kí o lè di ọlọ́gbọ́n ní ọjọ́ ọ̀la rẹ.” Òótọ́ ni pé, ìmọ̀ràn àti ìbáwí lè máà bára dé. Àmọ́, bó o bá fi kékeré lára àwọn ìmọ̀ràn tó o rí gbà nígbà táwọn òbí ẹ ń bá ẹ sọ̀rọ̀ ṣèwà hù, èrè tó o máa rí níbẹ̀ á níye lórí ju góòlù lọ.
Jẹ́ ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà: Ìbáwí kì í ṣe nǹkan tuntun. Àwọn òbí ẹ àtàwọn olùkọ́ ẹ ṣáà máa ń bá ẹ wí. Bó bá yá, àwọn tó máa gbà ẹ́ síṣẹ́ ṣì máa sọ̀rọ̀ sí ẹ. Yáa fara balẹ̀ kọ́ bó o ṣe lè fara dà á nílé, wàá sì wá rí i pé o máa di ọmọ iléèwé tó já fáfá, òṣìṣẹ́ táwọn èèyàn ń bọ̀wọ̀ fún àtẹni táwọn èèyàn gbọ́kàn lé. Ó dájú nígbà náà pé fífara da ọ̀rọ̀ táwọn òbí ẹ bá ń sọ sí ẹ tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ, kó o lè ráwọn èrè wọ̀nyí gbà!
Ṣé wọ́n ń fòfin dé ẹ mọ́lé? Kà nípa bí òmìnira tó o ní ṣe lè tẹ́ ẹ lọ́rùn àti bó o ṣe lè rí púpọ̀ gbà sí i.
ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́
“Ọlọ́gbọ́n yóò fetí sílẹ̀, yóò sì gba ìtọ́ni púpọ̀ sí i.”—Òwe 1:5.
ÌMỌ̀RÀN
Ohun tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti gba ìbáwí àwọn òbí ẹ ni pé
● Kó o máa fi ìmọrírì hàn fún bí wọ́n ṣe kọ́kọ́ yìn ẹ́ kí wọ́n tó sọ ibi tó o kù sí.
● Kó o ní kí wọ́n ṣàlàyé àwọn nǹkan tí ò bá yé ẹ nípa ìṣòro tí wọ́n sọ pé o ní tàbí ohun tó o máa ṣe láti yanjú ìṣòro náà.
ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?
Ó máa ń nira fáwọn bàbá àtàwọn màmá kan láti fìfẹ́ hàn sáwọn ọmọ wọn torí àwọn òbí tiwọn náà ò fi ojúlówó ìfẹ́ hàn sí wọn.
OHUN TÍ MÀÁ ṢE!
Báwọn òbí mi bá tún rí sí mi, màá ․․․․․
Bí mo bá rí i pé tàwọn òbí mi ti fẹ́ pọ̀ jù, màá ․․․․․
Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․
KÍ LÈRÒ Ẹ?
● Kí nìdí tó fi lè ṣòro fún ẹ láti gba ìbáwí?
● Kí ló lè mú káwọn òbí ẹ máa rí sí ẹ?
● Báwo lo ṣe lè jàǹfààní látinú ìmọ̀ràn tó o bá rí gbà?
[Ìsọfúnni tó wà ní ojú ìwé 177]
“Gbogbo ìgbà ni Mọ́mì máa ń jágbe mọ́ mi témi náà sì máa ń gbó wọn lẹ́nu. Àmọ́ ní báyìí, mo ti ń gbìyànjú láti fàwọn ìmọ̀ràn inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò. Ó sì wúlò fún mi. Mọ́mì ti ń yíwà pa dà báyìí. Ìmọ̀ràn Bíbélì tí mò ń fi sílò ti wá jẹ́ kí n lóye Mọ́mì dáadáa. Ọ̀rọ̀ wa ti wọ̀ gidi gan-an báyìí.”—Marleen
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 180]
Bó o bá wá ọgbọ́n tó wà nínú ìbáwí àwọn òbí ẹ rí, bó ti wù kó kéré mọ, èrè tó o máa rí níbẹ̀ á níye lórí ju góòlù lọ