Orin 111
Òun Yóò Pè
1. Bí ìkùukùu ni ọmọ èèyàn rí,
Báa ríi lónìí kìí dọ̀la.
Gbogbo báa ṣe jẹ́ lè dìgbàgbé kíá,
Yóò wá ku tẹkúntòṣé,
Bí èèyàn bá kú, ṣé ó tún lè yè?
Gbọ́ ìlérí Ọlọ́run:
(ÈGBÈ)
Òun yóò pè; Wọn yóò sì dáhùn.
Àwọn òkú yóò jíǹde.
Torí yóò ṣe àfẹ́rí
Èèyàn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.
Gbà á gbọ́ sì fọkàn balẹ̀,
Ọlọ́run lè mú ká jí.
Aó sì wà láàyè láéláé,
Gẹ́gẹ́ bí’ṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.
2. Báwọn ọ̀rẹ́ Ọlọ́run wa bá kú,
Kò ní gbàgbé wọn láéláé.
Gbogbo òkú tó wà níràn’tí rẹ̀,
Lòun yóò jí dìde pa dà.
Ayọ̀ àìlópin á wá jẹ́ tèèyàn:
Párádísè títí láé.
(ÈGBÈ)
Òun yóò pè; Wọn yóò sì dáhùn.
Àwọn òkú yóò jíǹde.
Torí yóò ṣe àfẹ́rí
Èèyàn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.
Gbà á gbọ́ sì fọkàn balẹ̀,
Ọlọ́run lè mú ká jí.
Aó sì wà láàyè láéláé,
Gẹ́gẹ́ bí’ṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.
(Tún wo Jòh. 6:40; 11:11, 43; Ják. 4:14.)