Orin 91
Baba Mi, Ọlọ́run Mi àti Ọ̀rẹ́ Mi
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Ojú ńpọ́nni láyé yìí.
Ẹkún, ìrora kún ayé yìí.
Ṣùgbọ́n mo ṣì gbà wí pé,
“Asán kọ́ layé mi.”
(ÈGBÈ)
Jáà kìí ṣe àìṣòdodo,
Ó ńrántí ìfẹ́ mi fóokọ rẹ̀.
Ó máa ńwà nítòsí mi;
Jèhófà kìí fi mí sílẹ̀.
Ọlọ́run lolùpèsè
àti aláàbò mi títí láé.
Jèhófà yìí lọ̀rẹ́, Baba,
Ọlọ́run mi.
2. Ìgbà èwe mi ti lọ;
Ọjọ́ ogbó, oníyọnu dé.
Ṣùgbọ́n lọ́lá ìgbàgbọ́,
Ìrètí mi dájú.
(ÈGBÈ)
Jáà kìí ṣe àìṣòdodo,
Ó ńrántí ìfẹ́ mi fóokọ rẹ̀.
Ó máa ńwà nítòsí mi;
Jèhófà kìí fi mí sílẹ̀.
Ọlọ́run lolùpèsè
àti aláàbò mi títí láé.
Jèhófà yìí lọ̀rẹ́, Baba,
Ọlọ́run mi.
(Tún Wo Sm. 71:17, 18.)