Orin 59
Ọlọ́run Ni A Ya Ara Wa sí Mímọ́ Fún!
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Jèhófà Ọlọ́run fà wá sọ́dọ̀ Kristi
Ká dọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ látòní.
Ìmọ́lẹ̀ òótọ́ ńtàn yòò,
Látorí ìtẹ́ Jáà wá.
Ìgbàgbọ́ wa ń pọ̀ síi;
A gbà láti sẹ́ ara wa.
(ÈGBÈ)
A ṣèyàsímímọ́ fún Jáà; A pinnu ni.
A ńyọ̀ nínú Jèhófà òun Jésù.
2. Àwa ti gbàá ládùúrà sí Jèhófà pé
Òun ni aó máa sìn títí ayé.
Ayọ̀ aláìlẹ́gbẹ́ ni,
Tí a ńfi ìdùnnú pín,
Báa ti ńjẹ́ orúkọ Jáà,
Táa sì ńkéde Ìjọba rẹ̀.
(ÈGBÈ)
A ṣèyàsímímọ́ fún Jáà; A pinnu ni.
A ńyọ̀ nínú Jèhófà òun Jésù.