Orin 81
“Fún Wa Ní Ìgbàgbọ́ Sí I”
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Jèhófà, nítorí a jẹ́ aláìpé,
Àìdára ni ọkàn wa máa ńfà sí.
Ẹ̀ṣẹ̀ kan wà tó máa ńtètè wé mọ́ wa
Àìgbà’wọ Ọlọ́run alààyè gbọ́.
(ÈGBÈ)
Fún wa nígbàgbọ́ síi, jọ̀wọ́ Jèhófà.
Jọ̀wọ́ fún wa báa ṣe nílò rẹ̀ tó.
Fún wa nígbàgbọ́ síi, nínú àánú rẹ.
Ká lè yìn ọ́, ká lè máa gbé ọ ga.
2. Láìsí ’gbàgbọ́, kò sẹ́ni tó lè wù ọ́.
A gbọ́dọ̀ gbà pé wàá pín wa lérè.
Ìgbàgbọ́ wa sì máa ń dáàbò bò wá.
Aò bẹ̀rù ọ̀la, ọkàn wa balẹ̀.
(ÈGBÈ)
Fún wa nígbàgbọ́ síi, jọ̀wọ́ Jèhófà.
Jọ̀wọ́ fún wa báa ṣe nílò rẹ̀ tó.
Fún wa nígbàgbọ́ síi, nínú àánú rẹ.
Ká lè yìn ọ́, ká lè máa gbé ọ ga.
(Tún wo Jẹ́n. 8:21; Héb. 11:6; 12:1.)