Orin 72
Bá A Ṣe Lè Ní Ìfẹ́
Bíi Ti Orí Ìwé
1. A wólẹ̀ àdúrà s’Ọ́lọ́run,
Kó fún wa láwọn ànímọ́ rẹ̀.
Èyí tó ṣe pàtàkì jù ni
Ìfẹ́, tí ẹ̀mí rẹ̀ ńjẹ́ ká ní.
A lè lẹ́bùn, ọgbọ́n, ìgboyà,
Asán ni, tí ìfẹ́ bá tutù.
Torí náà, ká nífẹ̀ẹ́ tí kìí yẹ̀;
Ká lè nífaradà, ká wu Jáà.
2. Bí a ti ńkọ́ àgùntàn lẹ́kọ̀ọ́,
Ká ní ìfẹ́ wọn lérò kò tó.
Ká nífẹ̀ẹ́ wọn lọ́rọ̀ àtìṣe,
Báa ti ńfọ̀rọ̀ Ọlọ́run bọ́ wọn.
Ìfẹ́ tó lágbára ńmú ká lè
Fara da àìtọ́, òun ìnira.
Rántí pé nínú gbogbo ’ṣòro,
Ìfẹ́ ńfara dà; kìí kùnà láé.
(Tún wo Jòh. 21:17; 1 Kọ́r. 13:13; Gál. 6:2.)