ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • bm apá 3 ojú ìwé 6
  • Aráyé La Ìkún Omi Já

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Aráyé La Ìkún Omi Já
  • Kí Ló Wà Nínú Bíbélì?
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọlọ́run Pa Nóà “Mọ́ Láìséwu Pẹ̀lú Àwọn Méje Mìíràn”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Ó “Bá Ọlọ́run Tòótọ́ Rìn”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Nígbà Ìkún Omi, Àwọn Wo Ló Tẹ́tí sí Ọlọ́run? Àwọn Wo Ni Kò Tẹ́tí sí I?
    Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé
  • Ó “Bá Ọlọ́run Tòótọ́ Rìn”
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
Àwọn Míì
Kí Ló Wà Nínú Bíbélì?
bm apá 3 ojú ìwé 6
Ọkọ̀ áàkì léfòó bí òjò ṣe ń rọ̀ tí omi òjò sì ń ga sí i

Apá 3

Aráyé La Ìkún Omi Já

Ọlọ́run pa ayé búburú kan run àmọ́ ó pa Nóà àti ìdílé rẹ̀ mọ́

BÁWỌN èèyàn ṣe ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀ṣẹ̀ àti ìwà ibi ń yára gbilẹ̀ sí i lórí ilẹ̀ ayé. Wòlíì kan ṣoṣo tó ń sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run nígbà náà, ìyẹn Énọ́kù, ṣèkìlọ̀ pé ọjọ́ kan ń bọ̀ tí Ọlọ́run máa pa àwọn èèyàn búburú run. Síbẹ̀, ìwà ibi ń gbilẹ̀ ó sì ń burú sí i. Àwọn áńgẹ́lì kan ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà nígbà tí wọ́n fi àyè wọn sílẹ̀ lọ́run, tí wọ́n gbé àwọ̀ èèyàn wọ̀ wá sí ilẹ̀ ayé, tí ojú kòkòrò sì sún wọn láti gbé àwọn ọmọbìnrin èèyàn níyàwó. Irú àjọṣe tí kò bá bí Ọlọ́run ṣe dá wọn mu yìí mú kí wọ́n bí àwọn àdàmọ̀dì ọmọ, àwọn òmìrán abúmọ́ni tó ń jẹ́ Néfílímù, tí wọ́n mú kí ìwà ọ̀daràn àti ìtàjẹ̀sílẹ̀ pọ̀ sí i lórí ilẹ̀ ayé. Ó dun Ọlọ́run gan-an láti rí bí àwọn tó dá sórí ilẹ̀ ayé ṣe ń pa ara wọn run.

Lẹ́yìn ikú Énọ́kù, ọkùnrin kan wà tó dá yàtọ̀ pátápátá nínú ayé búburú yẹn. Nóà ni orúkọ rẹ̀. Òun àti ìdílé rẹ̀ gbìyànjú láti ṣe ohun tó tọ́ lójú Ọlọ́run. Nígbà tí Ọlọ́run pinnu láti pa àwọn èèyàn búburú tó ń gbé nínú ayé yẹn run, ó fẹ́ láti dáàbò bo Nóà àtàwọn ẹranko tó wà lórí ilẹ̀ ayé. Torí náà, Ọlọ́run sọ fún Nóà pé kó kan ọkọ̀ áàkì, ìyẹn ọkọ̀ ńlá kan tó ní igun mẹ́rin. Ó fẹ́ pa Nóà àti ìdílé rẹ̀ mọ́ nínú ọkọ̀ náà, kí òun àti onírúurú ẹranko bàa lè la ìkún omi tó ń bọ̀ náà já. Nóà ṣe ohun tí Ọlọ́run pa láṣẹ fún un. Láàárín nǹkan bí ogójì sí àádọ́ta ọdún tí Nóà fi kan ọkọ̀ yẹn, ó tún jẹ́ “oníwàásù òdodo.” (2 Pétérù 2:5) Ó kìlọ̀ fáwọn èèyàn nípa Ìkún-omi tó ń bọ̀, àmọ́ wọn ò kọbi ara sí ohun tó ń sọ. Ìgbà tó yá, àkókò tó fún Nóà, ìdílé rẹ̀ àtàwọn ẹranko náà láti wọnú ọkọ̀ áàkì. Nígbà tí wọ́n sì wọnú ẹ̀ tán, Ọlọ́run pa ilẹ̀kùn ọkọ̀ náà dé. Òjò sì bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀.

Òjò náà ya bolẹ̀ gan-an fún ogójì [40] ọjọ́ àti ogójì [40] òru, títí tí omi fi bo gbogbo ilẹ̀ ayé. Àwọn ẹni ibi bómi lọ. Ọ̀pọ̀ oṣù lẹ́yìn náà, omi tó wà lórí ilẹ̀ fọn, ọkọ̀ áàkì náà sì gúnlẹ̀ sórí òkè ńlá kan. Ọdún kan gbáko ni Nóà àtàwọn ẹranko tó wà pẹ̀lú rẹ̀ lò nínú áàkì náà kí wọ́n tó jáde kúrò nínú ẹ̀. Nígbà tí wọ́n jáde kúrò nínú ẹ̀ tán, Nóà rúbọ sí Jèhófà láti fi dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Inú Ọlọ́run dùn sí ẹbọ Nóà ó sì mú kó dá òun àti ìdílé rẹ̀ lójú pé Òun ò ní fi Ìkún-omi pa gbogbo ohun alààyè tó wà lórí ilẹ̀ ayé run mọ́. Láti fìdí ìlérí yìí múlẹ̀, Jèhófà fi òṣùmàrè sójú sánmà gẹ́gẹ́ bí àmì tó ṣeé fojú rí, èyí tí yóò máa rán an létí ìlérí tí ń tuni nínú yìí.

Lẹ́yìn Ìkún-omi náà, Ọlọ́run tún fún aráyé láwọn òfin tuntun mìíràn. Ó yọ̀ọ̀da fún wọn láti máa jẹ ẹran. Àmọ́, ó ní wọn kò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀. Ó tún pàṣẹ fáwọn àtọmọdọ́mọ Nóà pé kí wọ́n gbilẹ̀ kárí ayé, àmọ́ àwọn kan lára wọn ṣàìgbọràn. Àwọn èèyàn gbìmọ̀ pọ̀ lábẹ́ aṣáájú kan tó ń jẹ́ Nímírọ́dù wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ilé ìṣọ́ gogoro kan sí ìlú Bábélì, èyí tá a wá mọ̀ sí Bábílónì nígbà tó yá. Wọ́n pinnu láti ta ko òfin Ọlọ́run pé kí wọ́n gbilẹ̀ kárí ayé. Àmọ́ Ọlọ́run sọ èrò àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà dasán nípa dída èdè kan ṣoṣo tí wọ́n ń sọ rú, ó sì mú kí wọ́n máa sọ onírúurú èdè. Nígbà tó wá di pé wọn ò lóye ara wọn mọ́, wọ́n pa ilé gogoro náà tì, wọ́n sì fọ́n káàkiri ayé.

—A gbé e ka Jẹ́nẹ́sísì orí 6 sí 11; Júúdà ẹsẹ 14, 15.

  • Báwo ni ìwà ibi ṣe gbilẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé?

  • Báwo ni Nóà ṣe fi hàn pé òun jẹ́ olóòótọ́?

  • Kí ni Ọlọ́run kà léèwọ̀ fáwọn èèyàn lẹ́yìn Ìkún-omi?

BÍBÁ ỌLỌ́RUN RÌN

Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ọmọ Ádámù àti Éfà ni kò fara mọ́ ìṣàkóso Jèhófà. Àmọ́, bẹ̀rẹ̀ látorí ọmọ wọn Ébẹ́lì, tó jẹ́ olóòótọ́, a rí àwọn tó bẹ̀rẹ̀ sí í fara mọ́ ìṣàkóso Ọlọ́run. Nígbà tó ṣe, a sọ nípa Énọ́kù àti Nóà pé wọ́n bá Ọlọ́run rìn, èyí tó fi hàn pé wọ́n gbé ìgbé ayé wọn lọ́nà tó mú inú Jèhófà dùn. (Jẹ́nẹ́sísì 5:22; 6:9) Ọ̀pọ̀ lára àwọn àkọsílẹ̀ inú Bíbélì sọ nípa tọkùnrin tobìnrin táwọn náà yan Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Olùṣàkóso wọn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́