ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • bm apá 7 ojú ìwé 10
  • Ọlọ́run Dá Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Nídè

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọlọ́run Dá Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Nídè
  • Kí Ló Wà Nínú Bíbélì?
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Mọ Àwọn Ọ̀nà Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Mósè Pinnu Láti Jọ́sìn Jèhófà
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Mósè Àti Áárónì Lọ Rí Fáráò
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Ẹ́kísódù
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
Àwọn Míì
Kí Ló Wà Nínú Bíbélì?
bm apá 7 ojú ìwé 10
Àwọn wàláà méjì tí Òfin Mẹ́wàá wà lára rẹ̀ wà ní ọwọ́ Mósè

Apá 7

Ọlọ́run Dá Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Nídè

Jèhófà mú ìyọnu wá sórí Íjíbítì, Mósè sì kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní ilẹ̀ náà. Ọlọ́run tipasẹ̀ Mósè fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Òfin

Ọ̀PỌ̀ ọdún làwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi gbé ní ilẹ̀ Íjíbítì, wọ́n ń láásìkí, wọ́n sì ń pọ̀ sí i. Nígbà tó ṣe Fáráò tuntun gorí oyè. Olùṣàkóso yìí ò mọ Jósẹ́fù. Òṣìkà tó rorò gan-an ni, ẹ̀rù sì ń bà á pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń pọ̀ sí i, torí náà ó sọ wọ́n di ẹrú ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n máa ju gbogbo ọmọkùnrin tí wọ́n bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bí sínú Odò Náílì. Àmọ́, ìyá kan tó jẹ́ onígboyà dáàbò bo ọmọkùnrin rẹ̀ jòjòló, ó gbé e sínú apẹ̀rẹ̀ ó sì tọ́jú ẹ̀ pa mọ́ sáàárín esùsú lẹ́bàá odò. Ọmọbìnrin Fáráò rí ọmọ kékeré náà, ó sọ ọ́ ní Mósè, ó sì tọ́ ọ dàgbà láàfin ọba ilẹ̀ Íjíbítì.

Nígbà tí Mósè pé ọmọ ogójì [40] ọdún, ó wọ wàhálà níbi tó ti fẹ́ gba ọmọ Ísírẹ́lì kan tó jẹ́ ẹrú sílẹ̀ lọ́wọ́ ará Íjíbítì tó jẹ́ akóniṣiṣẹ́. Mósè sá lọ sí ilẹ̀ kan tó jìnnà réré, ó sì wà ní ìgbèkùn níbẹ̀. Nígbà tí Mósè pé ọmọ ọgọ́rin [80] ọdún, Jèhófà rán an pa dà sí Íjíbítì pé kó lọ fara hàn níwájú Fáráò kó sì sọ fún un pé kó dá àwọn èèyàn Ọlọ́run sílẹ̀.

Fáráò kọ̀ jálẹ̀. Torí náà, Ọlọ́run mú ìyọnu mẹ́wàá wá sórí Íjíbítì. Gbogbo ìgbà tí Mósè bá fara hàn níwájú Fáráò pé bóyá ó lè yí ọkàn rẹ̀ pa dà kí ìyọnu náà lè dúró, ńṣe ni Fáráò ń ta kú, tó sì ń fi Mósè àti Ọlọ́run rẹ̀, Jèhófà ṣẹlẹ́yà. Níkẹyìn, ìyọnu kẹwàá pa gbogbo àkọ́bí tó wà nílẹ̀ Íjíbítì, àwọn ìdílé tó ṣègbọràn sí Jèhófà nípa fífi ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́ àgùntàn tí wọ́n fi rúbọ sára àwọn òpó ilẹ̀kùn ilé wọn nìkan ni àkọ́bí wọn yè. Áńgẹ́lì tí Ọlọ́run rán wá láti pa gbogbo àkọ́bí run ré ilé àwọn tó bá ṣe bẹ́ẹ̀ kọjá. Lẹ́yìn ìgbà yẹn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń ṣèrántí ìgbàlà àgbàyanu yìí, nípa ṣíṣe ayẹyẹ ọdọọdún tí wọ́n ń pè ní Ìrékọjá.

Lẹ́yìn tí àkọ́bí ọmọkùnrin Fáráò ti kú, Fáráò pàṣẹ pé kí Mósè àti gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò nílẹ̀ Íjíbítì. Kò sì pẹ́ táwọn ogunlọ́gọ̀ náà fi kóra jọ, tí wọ́n sì jáde kúrò ní Íjíbítì. Àmọ́, Fáráò yí ọkàn rẹ̀ pa dà. Ó fi ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ogun àti kẹ̀kẹ́ ogun lé wọn. Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì dé bèbè Òkun Pupa, ó dà bíi pé kò sọ́nà àbáyọ fún wọn mọ́. Jèhófà pín Òkun Pupa sí méjì, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì rìn kọjá lórí ilẹ̀ gbígbẹ, láàárín omi òkun tó pínyà náà! Nígbà táwọn ará Íjíbítì rọ́ tẹ̀ lé wọn, Ọlọ́run jẹ́ kí omi náà ya bò wọ́n mọ́lẹ̀, Fáráò àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì rì sínú òkun.

Nígbà tó yá, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pàgọ́ sórí Òkè Sínáì, Jèhófà sì bá wọn dá májẹ̀mú. Ọlọ́run lo Mósè gẹ́gẹ́ bí alárinà, ó sì fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì láwọn òfin táá máa tọ́ wọn sọ́nà táá sì máa dáàbò bò wọ́n nínú gbogbo nǹkan tí wọ́n bá ń ṣe. Níwọ̀n ìgbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá ń fòótọ́ ọkàn tẹ́wọ́ gba ìṣàkóso Ọlọ́run, Jèhófà á máa wà pẹ̀lú wọn á sì mú kí orílẹ̀-èdè náà máa kóre ran àwọn orílẹ̀-èdè míì.

Pẹ̀lú gbogbo èyí, èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò múnú Ọlọ́run dùn torí àìnígbàgbọ́ wọn. Torí náà, Jèhófà mú kí ìran àwọn tí kò nígbàgbọ́ náà rìn káàkiri nínú aginjù fún ogójì [40] ọdún. Lẹ́yìn náà, Mósè pàṣẹ fún Jóṣúà tó jẹ́ adúróṣinṣin pé kó gbapò òun. Níkẹyìn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì múra tán láti wọ ilẹ̀ tí Ọlọ́run ti ṣèlérí fún Ábúráhámù.

​—A gbé e ka Ẹ́kísódù; Léfítíkù; Númérì; Diutarónómì; Sáàmù 136:10-15; Ìṣe 7:17-36.

  • Báwo ni Ọlọ́run ṣe lo Mósè láti dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè?

  • Kí ló fà á táwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi ń ṣe ayẹyẹ Ìrékọjá?

  • Báwo ni Jèhófà ṣe dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè kúrò lóko ẹrú ní Íjíbítì?

ÒFIN TÓ GA JÙ LỌ

Àfàìmọ̀ ni kì í ṣe Àṣẹ Mẹ́wàá, tó wà nínú Ẹ́kísódù 20:1-17, làwọn èèyàn mọ̀ jù lọ lára nǹkan bí ẹgbẹ̀ta [600] òfin tí Ọlọ́run tipasẹ̀ Mósè fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Àmọ́, nígbà tí wọ́n bi Jésù Kristi pé èwo ló tóbi jù lọ nínú gbogbo òfin Ọlọ́run, èyí tó yàn lára wọn ni pé: “Kí ìwọ sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò-inú rẹ àti pẹ̀lú gbogbo okun rẹ.”—Máàkù 12:28-30; Diutarónómì 6:5.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́