Ẹ̀KỌ́ 17
Mósè Pinnu Láti Jọ́sìn Jèhófà
Ìdílé Jékọ́bù túbọ̀ ń pọ̀ sí i nílẹ̀ Íjíbítì, àwọn la wá mọ̀ sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Lẹ́yìn tí Jékọ́bù àti Jósẹ́fù kú, Fáráò míì di ọba nílẹ̀ Íjíbítì. Ẹ̀rù ń ba ọba yẹn pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń pọ̀ sí i àti pé ọwọ́ àwọn ará Íjíbítì ò ní lè ká wọn. Torí náà, Fáráò sọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì di ẹrú. Ó wá fipá mú wọn pé kí wọ́n máa ṣe búlọ́ọ̀kù, kí wọ́n sì tún máa ṣe àwọn iṣẹ́ míì tó le. Àmọ́ bí àwọn ará Íjíbítì ṣe ń fipá mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣiṣẹ́, bẹ́ẹ̀ làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń pọ̀ sí i. Inú Fáráò ò dùn pé wọ́n ń pọ̀ sí i, torí náà ó pàṣẹ pé tí ọmọ Ísírẹ́lì kan bá bí ọmọkùnrin, kí wọ́n pa ọmọ náà. Báwo lo ṣe rò pé ó máa rí lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì? Ṣé ọkàn wọn máa balẹ̀?
Obìnrin kan wà tó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì, Jókébédì lorúkọ ẹ̀. Nígbà tí obìnrin yẹn bí ọmọkùnrin kan, kò fẹ́ kí wọ́n pa ọmọ náà, ó wá gbé e sínú apẹ̀rẹ̀ kan, ó sì gbé e pa mọ́ sáàárín àwọn koríko tó wà létí Odò Náílì. Míríámù tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n ọmọ náà dúró sítòsí kó bàa lè rí ohun tó máa ṣẹlẹ̀.
Ọmọbìnrin Ọba Fáráò wá wẹ̀ lódò yẹn, ó sì rí apẹ̀rẹ̀ náà. Nígbà tó ṣí i, ó rí i tí ọmọ náà ń sunkún, àánú ẹ̀ sì ṣe é. Míríámù ẹ̀gbọ́n ọmọ jòjòló náà wá béèrè pé: ‘Ṣé kí n bá yín wá obìnrin kan tó máa bá yín tọ́jú ọmọ náà?’ Nígbà tí ọmọ ọba yẹn sọ pé kí Míríámù ṣe bẹ́ẹ̀, ó lọ pe Jókébédì màmá wọn. Ọmọbìnrin Fáráò wá sọ fún Jókébédì pé: ‘Gbé ọmọ yìí, bá mi tọ́jú ẹ̀, màá sanwó fún ẹ.’
Nígbà tí ọmọ kékeré náà dàgbà, Jókébédì mú un lọ sọ́dọ̀ ọmọbìnrin Fáráò. Obìnrin yẹn wá gbà á ṣọmọ. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í tọ́jú ẹ̀, ó sì pe orúkọ ẹ̀ ní Mósè. Inú ilé ọba ni Mósè dàgbà sí, kò sì sóhun tó fẹ́ tí wọn ò ní lè ṣe fún un. Àmọ́ Mósè ò gbàgbé Jèhófà. Ó mọ̀ pé òun kì í ṣe ọmọ Íjíbítì, pé ọmọ Ísírẹ́lì lòun. Torí náà, ó pinnu pé Jèhófà lòun máa sìn.
Nígbà tí Mósè pé ẹni ogójì (40) ọdún, ó pinnu pé òun máa ran àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́wọ́. Inú Mósè ò dùn nígbà tó rí ọmọ Íjíbítì kan tó ń lu ọmọ Ísírẹ́lì kan. Torí bẹ́ẹ̀, ó lu ọmọ Íjíbítì náà pa, ó wá fi erùpẹ̀ bo òkú rẹ̀ mọ́lẹ̀. Nígbà tí Fáráò gbọ́ ohun tí Mósè ṣe, ó wá ọ̀nà láti pa Mósè. Àmọ́ Mósè sá lọ sílẹ̀ Mídíánì. Jèhófà rí Mósè níbi tó wà, ó sì tọ́jú ẹ̀.
“Ìgbàgbọ́ mú kí Mósè kọ̀ kí wọ́n máa pe òun ní ọmọ ọmọbìnrin Fáráò . . . ó yàn pé kí wọ́n fìyà jẹ òun pẹ̀lú àwọn èèyàn Ọlọ́run.”—Hébérù 11:24, 25