ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 4/8 ojú ìwé 4-9
  • Ṣé Mósè Ti Gbáyé Rí àbí Ẹni Ìtàn Àròsọ Ni?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Mósè Ti Gbáyé Rí àbí Ẹni Ìtàn Àròsọ Ni?
  • Jí!—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Lóòótọ́ Làwọn Nǹkan Wọ̀nyí Ṣẹlẹ̀?
  • Wọ́n Gbà Á Ṣọmọ Lágboolé Fáráò
  • Ó Dèrò Ìgbèkùn Nílẹ̀ Mídíánì
  • Ìdáǹdè Kúrò ní Íjíbítì
  • Ohun Kan Tó Níye Lórí Ju Àwọn Ìṣúra Íjíbítì Lọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Mósè Pinnu Láti Jọ́sìn Jèhófà
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Ìdí Tí Mósè Fi Sá Lọ
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • Mọ Àwọn Ọ̀nà Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
Àwọn Míì
Jí!—2004
g04 4/8 ojú ìwé 4-9

Ṣé Mósè Ti Gbáyé Rí àbí Ẹni Ìtàn Àròsọ Ni?

ABẸ́ òjìji ikú ni wọ́n bí Mósè sí. Inú ìdílé àwọn èèyàn kan tó máa ń ṣí kiri ni wọ́n bí i sí. Kébi má bàa pa àwùjọ àwọn èèyàn wọ̀nyí kú làwọn àti baba wọn Jékọ́bù, tàbí Ísírẹ́lì, ṣe ṣí wá sí Íjíbítì. Fún ọ̀pọ̀ ọdún táwọn àtàwọn ọmọ ilẹ̀ Íjíbítì tí wọ́n jọ ń gbé fi wà pa pọ̀, wọn ò jà, wọn ò ta. Ṣùgbọ́n, bìrí ni nǹkan ṣàdédé yí padà. Àkọsílẹ̀ ìtàn kan tí ò ṣeé já ní koro sọ pé: “Ọba tuntun . . . jẹ lórí Íjíbítì. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ pé: ‘Ẹ wò ó! Àwọn ènìyàn tí ó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì pọ̀ níye jù wá, wọ́n sì jẹ́ alágbára ńlá jù wá lọ. Ó yá! Ẹ jẹ́ kí a ta ọgbọ́n fún wọn, kí wọ́n má bàa di púpọ̀.’” Ọgbọ́n wo ni wọ́n dá? Ìyẹn ni láti dín pípọ̀ táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń pọ̀ sí i kù, nípa lílò wọ́n bí “ẹrú lábẹ́ ìfìkà-gboni-mọ́lẹ̀” àti nípa pípàṣẹ fáwọn tó ń gbẹ̀bí fáwọn Hébérù pé kí wọ́n pa gbogbo àwọn ọmọkùnrin tí wọ́n bá bí. (Ẹ́kísódù 1:8-10, 13, 14) Nítorí ìgboyà àwọn tó ń gbẹ̀bí fún wọn, tí wọn ò tẹ̀ lé àṣẹ ọba, ńṣe làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń pọ̀ sí i ṣáá. Nítorí náà, ọba Íjíbítì pàṣẹ pé: “Olúkúlùkù ọmọkùnrin tí a bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bí ni kí ẹ sọ sínú odò Náílì.”—Ẹ́kísódù 1:22.

Àwọn tọkọtaya kan tí wọ́n jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì, Ámúrámù àti Jókébédì, “kò sì bẹ̀rù àṣẹ ìtọ́ni ọba.” (Hébérù 11:23) Jókébédì bí ọmọkùnrin kan, tí wọ́n máa sọ nípa rẹ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn pé “ó sì rẹwà lójú Ọlọ́run.”a (Ìṣe 7:20) Ó dà bí ẹni pé wọ́n fòye gbé e pé àyànfẹ́ Ọlọ́run lọmọ náà. Lédè kan ṣá, wọn ò yọ̀ọ̀da ọmọ náà fún pípa. Wọ́n pinnu láti gbé ọmọ náà pa mọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń fi ẹ̀mí ara wọn wewu ni.

Lẹ́yìn oṣù mẹ́ta, àwọn òbí Mósè ò lè gbé e pa mọ́ mọ́. Nígbà tí wọ́n sún kan ògiri wọ́n ní láti wá nǹkan ṣe. Jókébédì gbé ọmọ ọwọ́ náà sínú àpótí tí wọ́n fi òrépèté ṣe, èyí sì mú kó léfòó níbi tí wọ́n gbé e sí nínú Odò Náílì. Kò sì mọ̀ nígbà náà pé ohun tó máa sọ ọ́ dẹni tí wọ́n mọ̀ nílé lóko nìyẹn!—Ẹ́kísódù 2:3, 4.

Ṣé Lóòótọ́ Làwọn Nǹkan Wọ̀nyí Ṣẹlẹ̀?

Lóde òní, ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀mọ̀wé ló ka ìṣẹ̀lẹ̀ yìí sí ìtàn àròsọ lásán. Ìwé Christianity Today sọ pé: “Òótọ́ tó wà níbẹ̀ ni pé, kò tíì sí ẹ̀rí tààràtà kankan, bó ti wù ó kéré mọ, látọ̀dọ̀ àwọn awalẹ̀pìtàn, tó fi hàn pé lóòótọ̀ làwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbé ní ilẹ̀ Íjíbítì ní [gbogbo ọdún] tí ìtàn sọ pé wọ́n fi gbé níbẹ̀.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè ṣàìrí ẹ̀rí tá a lè fojú rí, ẹ̀rí jaburata tí kò ṣe tààràtà wà pé kò sírọ́ nínú àkọsílẹ̀ inú Bíbélì yìí. Nínú ìwé rẹ̀, Israel in Egypt, James K. Hoffmeier, onímọ̀ nípa àwọn ohun ìṣẹ̀ǹbáyé ilẹ̀ Íjíbítì sọ pé: “Ìsọfúnni látọ̀dọ̀ àwọn awalẹ̀pìtàn mú kó ṣe kedere pé lemọ́lemọ́ làwọn èèyàn tó ń gbé láwọn orílẹ̀-èdè tó múlé gbe ìlà oòrùn Mẹditaréníà máa ń lọ sí Íjíbítì, pàápàá jù lọ nítorí ìyípadà ojú ọjọ́ tó mú kí ọ̀dá dá . . . Nítorí náà, fún àwọn àkókò kan, bíi látọdún 1800 sí ọdún 1540 Sànmánì Tiwa, Íjíbítì jẹ́ ibi fífanimọ́ra táwọn ará ìwọ̀ oòrùn Éṣíà tí ń sọ èdè àwọn Júù máa ń fẹ́ láti ṣí lọ.”

Síwájú sí i, ó ti pẹ́ táwọn èèyàn ti ń sọ pé àlàyé tó péye ni Bíbélì ṣe nípa báwọn ará Íjíbítì ṣe lo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bí ẹrú. Ìwé náà, Moses—A Life, ròyìn pé: “Ó dà bíi pé àwòrán kan tí wọ́n sábà máa ń lò, èyí tí wọ́n yà sára ibojì kan nílẹ̀ Íjíbítì ìgbàanì, tí wọ́n ya agbo àwọn ẹrú tó ń fi amọ̀ mọ bíríkì sí, ti jẹ́rìí sí àkọsílẹ̀ Bíbélì nípa bí wọ́n ṣe ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lára.”

Òótọ́ la tún bá nídìí bí Bíbélì ṣe ṣàpèjúwe àpótí kékeré tí Jókébédì lò. Bíbélì sọ pé òrépèté ni wọ́n fi ṣe é. Gẹ́gẹ́ bí ìwé Commentary, látọwọ́ Cook ṣe sọ, òrépèté yìí ni “àwọn ará Íjíbítì sábà máa ń lò láti fi ṣe àwọn ọkọ̀ ojú omi tó fẹ́rẹ̀ tó sì yára.”

Síbẹ̀, ṣé kò ṣòro láti gbà gbọ́ pé olórí orílẹ̀-èdè kan á pàṣẹ pé kí wọ́n pa àwọn ọmọ ọwọ́ nípakúpa? Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀, George Rawlinson, rán wa létí pé: “Pípa ọmọ ọwọ́ . . . ti di ohun tó gbilẹ̀ nígbà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àti níbi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ohun tí ò tó nǹkan ni wọ́n sì kà á sí.” Kódà, lóde òní, kò ṣòro láti rí irú àpẹẹrẹ ìpànìyàn lápalù bẹ́ẹ̀. Bí Bíbélì ṣe ròyìn ìtàn náà lè ṣeni bákan o, àmọ́ òótọ́ pọ́ńbélé ni.

Ṣé Ìtàn Àwọn Kèfèrí Ni Bí Wọ́n Ṣe Gba Mósè Là?

Àwọn olùṣelámèyítọ́ kan sọ pé ara fu àwọn pé bí wọ́n ṣe gba Mósè là nínú Odò Náílì yẹn fẹ́ jọ ìtàn àtẹnudẹ́nu ìgbàanì nípa Ọba Ságónì ti ìlú Ákádì, ìtàn táwọn kan sọ pé ó ti wáyé kí wọ́n tó bí Mósè. Ó tún sọ nípa ọmọ ọwọ́ kan tó wà nínú apẹ̀rẹ̀, tí wọ́n sì fà yọ nínú odò.

Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn ohun tó jọra pọ̀ nínú ìtàn. Kò sì dà bí ẹni pé ohun tójú ò rí rí ni gbígbé ọmọ ọwọ́ sínú odò. Ìwé Biblical Archaeology Review sọ pé: “A ní láti rántí pé ìlú etí odò làwọn ìlú Babilóníà àti Íjíbítì, nítorí náà ọ̀nà tó dára jù lọ tí ẹnì kan á fẹ́ láti gbà gbé ọmọ sọ nù ni pé kó gbé e sínú apẹ̀rẹ̀ tómi ò lè wọnú ẹ̀ dípò tí ì bá kúkú fi gbé e sọ sí àkìtàn, èyí táwọn èèyàn sábà máa ń ṣe. . . . Ó lè dà bíi pé wọ́n sábà máa ń pìtàn ọmọ ọwọ́ tí wọ́n rí he tó dẹni pàtàkì, àmọ́ nítorí pé ó máa ń ṣẹlẹ̀ lemọ́lemọ́ nínú ìtàn ló jẹ́ kó rí bẹ́ẹ̀.”

Nínú ìwé rẹ̀ Exploring Exodus, Nahum M. Sarna sọ pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìtàn náà jọra láwọn ọ̀nà kan, “ìyàtọ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀ gbọọrọ” ló wà nínú “Ìtàn Àtẹnudẹ́nu Nípa Ságónì” àti ìtàn Mósè. Nítorí náà, irọ́ tó jìnnà sóòótọ́ gbáà ni àwáwí náà pé inú ìtàn àwọn kèfèrí ni àkọsílẹ̀ inú Bíbélì ti wá.

Wọ́n Gbà Á Ṣọmọ Lágboolé Fáráò

Jókébédì ò fi ọ̀ràn ọmọ rẹ̀ ṣeré rárá o. ‘Àárín àwọn esùsú ní bèbè odò Náílì ló gbé àpótí náà sí.’ Níbi tó rò pé ó ṣeé ṣe kí wọ́n ti rí àpótí náà. Ó sì dà bí ẹni pé ọmọbìnrin Fáráò ò lè ṣe kó máà wá wẹ̀ níbẹ̀.b—Ẹ́kísódù 2:2-4.

Kò pẹ́ tí wọ́n fi rí àpótí kékeré náà. “Nígbà tí [ọmọbìnrin Fáráò] ṣí i, ó wá rí ọmọ náà, kíyè sí i, ọmọdékùnrin náà ń sunkún. Látàrí èyí, ó yọ́nú sí i, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó wí pé: ‘Ọ̀kan lára àwọn ọmọ Hébérù nìyí.’” Bó kúkú ṣe pinnu láti gbà á ṣọmọ nìyẹn o. Ọjọ́ pẹ́ tórúkọ yòówù káwọn òbí ọmọ náà sọ ọ́ ti dìgbàgbé. Lóde tòní, orúkọ tí ìyá tó gbà á ṣọmọ sọ ọ́ làwọn èèyàn fi mọ̀ ọ́n kárí ayé, ìyẹn ni Mósè.c—Ẹ́kísódù 2:5-10.

Àmọ́ ṣá o, ṣé kò ti pọ̀ jù láti retí pé kí ọmọbìnrin ọba Íjíbítì dáàbò bo irú ọmọ bẹ́ẹ̀? Ó tì o, nítorí pé ẹ̀sìn àwọn ará Íjíbítì fi kọ́ wọn pé ṣíṣoore jẹ́ ọ̀kan lára ohun tó lè mú kí wọ́n rí ọ̀run wọ̀. Ní ti gbígbà tó gbà á ṣọmọ, awalẹ̀pìtàn Joyce Tyldesley sọ pé: “Ipò kan náà làwọn obìnrin àtàwọn ọkùnrin wà nílẹ̀ Íjíbítì. Ká ṣáà sọ pé ẹ̀tọ́ kan náà ni wọ́n ní lábẹ́ òfin àti nínú ọ̀ràn ìṣòwò, . . . àwọn obìnrin sì lè gbani ṣọmọ.” Ó wà lákọọ́lẹ̀ nínú òrépèté ìgbàanì kan pé obìnrin kan ní Íjíbítì gba àwọn ẹrú rẹ̀ ṣọmọ. Wàyí o, ní ti gbígbà tí wọ́n gba ìyá Mósè láti bá wọn tọ́jú ọmọ náà, ìwé The Anchor Bible Dictionary sọ pé: “Sísanwó fún ìyá tó bí Mósè láti bá wọn tọ́jú ọmọ náà . . . rán wa létí irú ìṣètò kan náà tó fara jọ èyí tó máa ń wáyé nínú àdéhùn ìgbàṣọmọ táwọn ara Mesopotámíà máa ń ṣe.”

Léyìí tí Mósè sì ti wá dẹni tí wọ́n gbà sọmọ yìí, ǹjẹ́ wọ́n á fi àṣírí jíjẹ́ tí òun fúnra rẹ̀ jẹ́ Hébérù hàn án? Àwọn sinimá kan tí wọ́n ń gbé jáde ní Hollywood ti mú kó jọ bí ẹni pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí. Àmọ́, Ìwé Mímọ́ fi hàn pé ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀. Ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obìnrin, Míríámù, ló fọgbọ́n ṣe é tó fi jẹ́ pé Jókébédì, ìyá ọmọ náà, ló pàpà tọ́jú rẹ̀. Dájúdájú, obìnrin olùbẹ̀rù Ọlọ́run yìí ò ní ṣàì sọ bọ́rọ̀ ṣe jẹ́ gan-an fún ọmọ rẹ̀! Níwọ̀n ìgbà tó sì jẹ́ pé ó máa ń tó ọdún mélòó kan kí wọ́n tó já ọmọ lẹ́nu ọmú láyé ìgbàanì, àkókò tó pọ̀ tó wà fún Jókébédì láti kọ́ Mósè nípa ‘Ọlọ́run Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù.’ (Ẹ́kísódù 3:6) Irú ìpìlẹ̀ tẹ̀mí bẹ́ẹ̀ ran Mósè lọ́wọ́ gan-an, nítorí pé lẹ́yìn tí wọ́n ti gbé e padà fún ọmọbìnrin Fáráò, “Mósè ni a fún ní ìtọ́ni nínú gbogbo ọgbọ́n àwọn ará Íjíbítì.” Josephus sọ pé nígbà tí Mósè bá àwọn ara Etiópíà jagun, wọ́n sọ ọ́ di ọ̀gágun. Ṣùgbọ́n kò sí ẹ̀rí kankan láti fi ti ìyẹn lẹ́yìn. Àmọ́ ṣá o, Bíbélì sọ pé Mósè “jẹ́ alágbára nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe rẹ̀.”d—Ìṣe 7:22.

Nígbà tí Mósè dẹni ogójì ọdún, ó dà bí i pé ara ẹ̀ ti wà lọ́nà láti di aṣáájú pàtàkì nílẹ̀ Íjíbítì. Ì bá di alágbára àti ọlọ́rọ̀ ká ní kò kúrò lágboolé Fáráò. Ṣùgbọ́n ohun kan ṣẹlẹ̀ tó yí ìgbésí ayé rẹ̀ padà.

Ó Dèrò Ìgbèkùn Nílẹ̀ Mídíánì

Lọ́jọ́ kan, Mósè “tajú kán rí ọmọ Íjíbítì kan tí ń lu Hébérù kan tí ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn arákùnrin rẹ̀.” Ohun tí jíjẹ́ Hébérù àti jíjẹ́ ará Íjíbítì túmọ̀ sí kò ṣàjèjì sí Mósè, nítorí pé ọ̀pọ̀ ọdún ló ti lò bí ọmọ orílẹ̀-èdè méjèèjì. Ṣùgbọ́n nígbà tó rí i tí wọ́n ń lu ọmọ Ísírẹ́lì kan bíi tiẹ̀ bí ẹni máa kú, Mósè kúkú yàn láti ṣe ìṣe akin. (Ẹ́kísódù 2:11) Ó “kọ̀ kí a máa pe òun ní ọmọkùnrin ti ọmọbìnrin Fáráò, ó yàn pé kí a ṣẹ́ òun níṣẹ̀ẹ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn Ọlọ́run.”—Hébérù 11:24, 25.

Ní kíá mọ́sá, Mósè gbé ìgbésẹ̀ kan tí àtẹ̀yìnbọ̀ rẹ̀ ò ní dáa: “Ó ṣá ọmọ Íjíbítì náà balẹ̀, ó sì pa á mọ́ sínú iyanrìn.” (Ẹ́kísódù 2:12) Kì í ṣe bí ẹni tó “máa ń bínú fùfù,” ṣe ń hùwà nìyí, gẹ́gẹ́ bí olùṣelámèyítọ́ kan ṣe rò. Ó ní láti jẹ́ pé ìgbàgbọ́ tí Mósè ní nínú ìlérí Ọlọ́run pé a óò dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì ló sún un láti ṣe bẹ́ẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ki àṣejù bọ̀ ọ́. (Jẹ́nẹ́sísì 15:13, 14) Bóyá àìláròjinlẹ̀ ló sún Mósè tó fi ronú pé ìwà akin tóun bá hù ló máa ru àwọn èèyàn òun sókè tí wọ́n á fi dìde ọ̀tẹ̀. (Ìṣe 7:25) Àmọ́, ẹnu Mósè rọ nígbà tó rí i pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yòókù ò gba òun gẹ́gẹ́ bí aṣáájú. Nígbà tó détígbọ̀ọ́ Fáráò pé ó ti pààyàn, ó di dandan fún Mósè láti sa lọ sí ìgbèkùn. Ó fìdí kalẹ̀ sí Mídíánì, ó sì fẹ́ obìnrin kan tó ń jẹ́ Sípórà, ọmọbìnrin Jẹ́tírò, tó jẹ́ ìjòyè àwọn aṣíkiri.

Fún ogójì ọdún tán-n-tán, Mósè ń bá ìgbésí ayé ẹ̀ lọ bí olùṣọ́ àgùntàn kan tí kì í kọjá àyè ẹ̀, gbogbo àgbọ́kànlé rẹ̀ láti di ẹni tí yóò gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì là ti dòfo. Àmọ́, lọ́jọ́ kan, ó da agbo ẹran Jẹ́tírò lọ síbì kan lẹ́bàá Òkè Hórébù. Níbẹ̀ ni Jèhófà ti fara han Mósè níbi tí iná ti ń jó lára igi kékeré kan. Fojú inú yàwòrán ohun tó ṣẹlẹ̀: Ọlọ́run pàṣẹ fún Mósè pé, “mú àwọn ènìyàn mi àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò ní Íjíbítì.” Ṣùgbọ́n, ẹní bá rí Mósè nígbà tó ń dá Ọlọ́run lóhùn á mọ̀ pé ó ń ṣiyèméjì, ó ń lọ́ tìkọ̀ kò sì dára ẹ̀ lójú. Ó bẹ Ọlọ́run pé: “Ta ni èmi tí èmi yóò fi lọ bá Fáráò, tí n ó sì fi mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò ní Íjíbítì?” Ó tiẹ̀ tún mẹ́nu kan àléébù tí àwọn onísinimá kan máa ń fi bò, ìyẹn ni ti àìlèsọ̀rọ̀ já gaara. Ẹ ò wá rí i báyìí pé Mósè yàtọ̀ gbáà sáwọn akọni inú ìtàn àròsọ ìgbàanì! Ogójì ọdún tó lò lẹ́nu iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn ti sọ ọ́ di onírẹ̀lẹ̀ àtẹni tí ara ẹ̀ balẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Mósè ń ṣiyè méjì nípa ara ẹ̀, Ọlọ́run mọ̀ pé iṣẹ́ aṣáájú yẹ ẹ́!—Ẹ́kísódù 3:1-4:20.

Ìdáǹdè Kúrò ní Íjíbítì

Mósè fi ilẹ̀ Mídíánì sílẹ̀ ó sì tọ Fáráò lọ láti sọ fún un pé kó jọ̀wọ́ àwọn ènìyàn Ọlọ́run lọ́wọ́ lọ. Nígbà tí ọba olórí kunkun náà fàáké kọ́rí, Ọlọ́run mú ìyọnu mẹ́wàá wá sórí Íjíbítì. Ìyọnu kẹwàá yọrí sí ikú àwọn àkọ́bí nílẹ̀ Íjíbítì, Fáráò tí ìbànújẹ́ ti dorí ẹ̀ kodò, sì wá yọ̀ọ̀da pé káwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa lọ.—Ẹ́kísódù, orí 5 sí 13.

Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń ka Bíbélì ló mọ̀ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí bí ẹní mowó. Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ èyíkéyìí nínú wọn ṣẹlẹ̀ rí? Àwọn kan sọ pé níwọ̀n bí ìtàn náà ò ti mẹ́nu kan orúkọ Fáráò, a jẹ́ pé àròsọ lásán ni.e Ṣùgbọ́n, Hoffmeier, tá a ti fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ nínú àpilẹ̀kọ yìí, sọ pé ńṣe làwọn akọ̀wé ilẹ̀ Íjíbítì máa ń mọ̀ọ́mọ̀ yọ orúkọ àwọn ọ̀tá Fáráò dà nù. Ó ṣàlàyé pé: “Dájúdájú, àwọn òpìtàn ò jẹ́ sọ pé ogun tí Thutmose Kẹta jà ní Mẹ́gídò kò wáyé nítorí pé orúkọ àwọn ọba Kádéṣì àti Mẹ́gídò ò sí nínú àkọsílẹ̀.” Hoffmeier sọ pé “ọ̀ràn tó jẹ mọ́ ti ẹ̀kọ́ ìsìn pọ́ńbélé” ni ò jẹ́ kí wọ́n dárúkọ Fáráò. Ohun kan ni pé, àìdárúkọ Fáráò ló jẹ́ kí àkọsílẹ̀ náà pe àfiyèsí sí Ọlọ́run.

Síbẹ̀ náà, àwọn olùṣelámèyítọ́ ò gbà pé òótọ́ ni ìgbà kan wà táwọn Júù rẹpẹtẹ rọ́ kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì. Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀, Homer W. Smith, sọ pé rírọ́ gìrọ́gìrọ́ bẹ́ẹ̀ “ì bá ti di ohun táwọn ará Íjíbítì tàbí àwọn ará Síríà á kọ sílẹ̀ nínú ìtàn wọn . . . Àfàìmọ̀ ni ìtàn àtẹnudẹ́nu nípa báwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe jáde kúrò ní Íjíbítì kì í ṣe àròsọ àti àsọdùn nípa bí ìwọ̀nba èèyàn kéréje ṣe sá kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì lọ sí Palẹ́sìnì.”

Òótọ́ ni pé ọwọ́ ò tíì tẹ ìwé èyíkéyìí táwọn ará Íjíbítì kọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ yìí. Ṣùgbọ́n, àwọn ará Íjíbítì ò kọjá ẹni tó lè yí àkọsílẹ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ìtàn padà, pàápàá bí wọ́n bá rí i pé ó tàbùkù àwọn tàbí tó bá máa jin ohun táwọn èèyàn mọ̀ nípa agbára ìṣèlú àwọn lẹ́sẹ̀. Nígbà tí Thutmose Kẹta gorí àlééfà, ó fẹ́ káwọn èèyàn gbàgbé pátápátá nípa Hatshepsut, ọba tó jẹ ṣáájú ẹ̀. John Ray, onímọ̀ nípa àwọn ohun ìṣẹ̀ǹbáyé ilẹ̀ Íjíbítì, sọ pé: “Ó pa gbogbo àkọlé tó wà nípa rẹ̀ rẹ́, ó mọ ògiri yí ọwọ̀n rẹ̀ ká, ibojì rẹ̀ sì dìgbàgbé. Orúkọ rẹ̀ ò fara hàn nínú àwọn àkọsílẹ̀ ìtàn lẹ́yìn ìgbà náà.” Bákan náà, lóde òní, àwọn kan ti gbìdánwò láti fọwọ́ bo òtítọ́ tí wọ́n rò pé ó lè tàbùkù àwọn lójú.

Ní ti pé kò sí ẹ̀rí kankan látọ̀dọ̀ àwọn awalẹ̀pìtàn tó tì í lẹ́yìn pé òótọ́ làwọn ọmọ Ísírẹ́lì rìn nínú aginjù, a gbọ́dọ̀ rántí pé ńṣe làwọn Júù ń ṣí kiri. Wọn ò tẹ ìlú kankan dó; wọn ò sì gbin irúgbìn èyíkéyìí. Bóyá lohun kan wà, yàtọ̀ sí ipasẹ̀ wọn, tá a lè máa fi rántí wọn. Síbẹ̀, a lè rí ẹ̀rí tí ò ṣeé já ní koro nípa ìrìn wọn nínú aginjù nínú Bíbélì fúnra rẹ̀. A sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ lápá ibi tó pọ̀ nínú ìwé mímọ́ yẹn. (1 Sámúẹ́lì 4:8; Sáàmù 78; Sáàmù 95; Sáàmù 106; 1 Kọ́ríńtì 10:1-5) Èyí tó tún wá ṣe pàtàkì jù lọ ni pé Jésù Kristi pẹ̀lú jẹ́rìí sí i pé òótọ́ làwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú aginjù.—Jòhánù 3:14.

Láìsíyèméjì, nígbà náà, òtítọ́ pọ́ńbélé, àtèyí tí kò lábùlà ni ohun tí Bíbélì sọ nípa Mósè. Àmọ́ ṣá o, ọjọ́ ti pẹ́ tí Mósè gbé láyé. Báwo ni ohun tí Mósè gbélé ayé ṣe ṣe kàn ọ́ lónìí?

a Ní ṣáńgílítí, ó túmọ̀ sí, “tí Ọlọ́run kà sí ẹni rírẹwà.” Gẹ́gẹ́ bí ìwé The Expositor’s Bible Commentary ṣe sọ, ó lè ṣàìjẹ́ pé ẹwà àbímọ́ni tí ọmọ náà ní nìkan ni gbólóhùn náà ń sọ nípa rẹ̀, bí kò ṣe “àwọn ànímọ́ ti inú ọkàn rẹ̀” lọ́hùn-ún.

b Ìwé Commentary látọwọ́ Cook sọ pé “àṣà tó wọ́pọ̀ nílẹ̀ Íjíbítì ìgbàanì ni” pé káwọn èèyàn lọ máa wẹ̀ nínú odò Náílì. “Wọ́n máa ń bọ odò Náílì tí wọ́n gbà gbọ́ pé ó tọ̀dọ̀ . . . Ósírísì wá, ó sì lágbára láti fúnni ní ìyè, wọ́n sì tún gbà pé omi odò náà lè sọ àgàn di ọlọ́mọ.”

c Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ṣì ń jara wọn níyàn nípa ibi tórúkọ yẹn ti wá. Lédè Hébérù, Mósè túmọ̀ sí “Fà Jáde; Tá A Gbà Là Látinú Omi.” Òpìtàn Flavius Josephus jiyàn pé ọ̀rọ̀ àwọn ará Íjíbítì méjì ló pa pọ̀ di orúkọ náà, Mósè, ìyẹn ni “omi” àti “tá a gbà là.” Bákan náà làwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan lóde òní gbà pé orúkọ àwọn ará Íjíbítì ni Mósè, ṣùgbọ́n wọ́n ronú pé ó ṣeé ṣe jù kó túmọ̀ sí “Ọmọkùnrin.” Àmọ́ ṣá o, ohun tó mú wọn sọ bẹ́ẹ̀ ni pé bí wọ́n ṣe ń pe orúkọ náà “Mósè” fara jọ bí wọ́n ṣe ń pe àwọn orúkọ kan nílẹ̀ Íjíbítì. Níwọ̀n bí kò ti sẹ́ni tó mọ bí àwọn Hébérù àtàwọn ará Íjíbítì ṣe ń sọ̀rọ̀ látijọ́, àròbájọ ni irú àwọn àlàyé bẹ́ẹ̀.

d Ìwé náà, Israel in Egypt, sọ pé: “Èrò náà pé ààfin ọba ni wọ́n ti tọ́ Mósè dàgbà lè dà bí ìtàn àròsọ kan lásán. Ṣùgbọ́n bá a bá fara balẹ̀ kíyè sí bí nǹkan ṣe máa ń rí láàfin láwọn sáà tí wọ́n ń pè ní sáà Ìjọba Tuntun, a ó rí i pé ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀. Ọba Thutmose Kẹta . . . ló bẹ̀rẹ̀ àṣà pé kí wọ́n máa mú ọmọ àwọn ọba ìwọ̀ oòrùn Éṣíà tí wọ́n bá ṣẹ́gun wá sí Íjíbítì kí wọ́n lè fi àṣà Íjíbítì kọ́ wọn . . . Nítorí náà, ojú àwọn ọmọ ọba ilẹ̀ àjèjì, yálà wọ́n jẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin, ṣálẹ̀ sí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láàfin ilẹ̀ Íjíbítì.”

e Àwọn òpìtàn kan sọ pé Fáráò tí ìwé Ẹ́kísódù sọ nípa rẹ̀ ni Thutmose Kẹta. Àwọn kan sọ pé Fáráò náà ni Amenhotep Kejì, Ramses Kejì, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Nítorí pé àwọn ará Íjíbítì kò ní àkọsílẹ̀ gígún régé nípa àwọn ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀, kò ṣeé ṣe láti sọ ẹni táwọn Fáráò yìí jẹ́ ní pàtó.

Ta Ló Kọ “Àwọn Ìwé Mósè”?

Mósè ni ìtàn sọ pé ó kọ àwọn ìwé márùn-ún àkọ́kọ́ nínú Bíbélì. Ó ṣeé ṣe kí Mósè ti ṣàkójọ díẹ̀ lára àwọn ìsọfúnni tó kọ látinú àwọn ìwé ìtàn tó ti wà tẹ́lẹ̀. Àmọ́ ṣá o, ọ̀pọ̀ àwọn olùṣelámèyítọ́ gbà pé Mósè ò lọ́wọ́ sí kíkọ àwọn ìwé náà rárá. Spinoza, onímọ̀ ọgbọ́n orí kan ní ọ̀rúndún kẹtàdínlógún tiẹ̀ sọ pé: “Nítorí náà, ó dájú tádàá pé Mósè kọ́ ló kọ ìwé márùn-ún àkọ́kọ́ nínú Bíbélì.” Ní apá tó kẹ́yìn ọ̀rúndún kọkàndínlógún, ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ará Jámánì náà, Julius Wellhausen, tiẹ̀ ṣagbátẹrù àbá èrò orí kan tó pè ní “àwọn ìwé àkọsílẹ̀.” Ibẹ̀ ló ti sọ pé ìwé táwọn òǹkọ̀wé mélòó kan tàbí ẹgbẹ́ àwọn òǹkọ̀wé kọ ni wọ́n jàn pọ̀ tó wá di àwọn ìwé Mósè.

Ìwà ìrẹ̀lẹ̀ Mósè ló mú kó ṣàkọsílẹ̀ àwọn ìkùnà rẹ̀ kó lè fògo fún Ọlọ́run

Wellhausen sọ pé lemọ́lemọ́ ni òǹkọ̀wé kan lo orúkọ Ọlọ́run, Jèhófà. Òǹkọ̀wé mìíràn sì pe Ọlọ́run ní ‘Elohim.’ Wọ́n sì ní òmíràn ló ṣàkọsílẹ̀ ìlànà táwọn àlùfáà ń lò, èyí tó wà nínú ìwé Léfítíkù, nígbà tí òǹkọ̀wé mìíràn sì kọ ìwé Diutarónómì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan ti ń lo àbá èrò orí yìí láti ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún, ìwé The Pentateuch, látọwọ́ Joseph Blenkinsopp, pe àbá Wellhausen ni àbá èrò orí “tó ti fẹ́ forí ṣánpọ́n.”

Ìwé náà, Introduction to the Bible, látọwọ́ John Laux, ṣàlàyé pé: “Orí àwọn ọ̀rọ̀ tó jẹ́ àdábọwọ́ tara ẹni tàbí èyí tó jẹ́ irọ́ pátápátá ni wọ́n gbé Àbá Èrò Orí Nípa Àwọn Ìwé Àkọsílẹ̀ kà. . . . Bí Àbá Èrò Orí Nípa Àwọn Ìwé Àkọsílẹ̀, tí wọ́n gbé gbòdì yìí bá sì jóòótọ́, a jẹ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dẹni tí a fẹ̀tàn mú nìyẹn, nígbà tí wọ́n gbà pé kí a gbé ẹrù Òfin wíwúwo ka àwọn lórí. Ẹ̀tàn tó lágbára jù lọ látijọ́ táláyé ti dáyé ni ìyẹn ì bá sì jẹ́.”

Àríyànjiyàn míì tún ni pé ìyàtọ̀ tó wà nínú bí wọ́n ṣe kọ ìwé márùn-ún àkọ́kọ́ nínú Bíbélì jẹ́ ẹ̀rí pé àwọn tó kọ ìwé náà pọ̀. Àmọ́ ṣá o, K. A. Kitchen sọ nínú ìwé rẹ̀ Ancient Orient and Old Testament pé: “Ìyàtọ̀ nínú ọ̀nà ìgbàkọ̀wé ò já mọ́ nǹkan, ńṣe ló wulẹ̀ ń jẹ́ ká rí ìyàtọ̀ tó wà nínú kókó tá à ń jíròrò rẹ̀.” A lè rí àwọn ìyàtọ̀ tó jọ èyí náà “nínú àwọn àyọkà ìgbàanì kan tó dájú hán-ún hán-ún pé ẹnì kan ṣoṣo ló kọ wọ́n.”

Èyí tí wọ́n sì tún sọ pé lílo àwọn orúkọ àti orúkọ oyè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ fún Ọlọ́run jẹ́ ẹ̀rí pé òǹkọ̀wé ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló kọ ọ́, kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀. Ní apá ibi kékeré lásán nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì, a pe Ọlọ́run ní “Ọlọ́run Gíga Jù Lọ,” “Ẹni tí Ó Ṣe ọ̀run àti ilẹ̀ ayé,” “Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ,” “Ọlọ́run ìrí,” “Ọlọ́run Olódùmarè,” “Ọlọ́run,” “Ọlọ́run tòótọ́” àti “Onídàájọ́ gbogbo ilẹ̀ ayé.” (Jẹ́nẹ́sísì 14:18, 19; 15:2; 16:13; 17:1, 3, 18; 18:25) Ṣé òǹkọ̀wé ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló kọ àwọn ẹsẹ Bíbélì wọ̀nyẹn ni? Jẹ́nẹ́sísì 28:13 sì tún ń kọ́, níbi tí a ti lo ọ̀rọ̀ náà “Elohim” (Ọlọ́run) àti “Jèhófà” pa pọ̀? Ṣé òǹkọ̀wé méjì náà ló pawọ́ pọ̀ kọ ẹsẹ kan ṣoṣo yìí?

A lè rí i kedere pé ríronú lọ́nà yìí ò fẹsẹ̀ múlẹ̀ tá a bá fi ohun tó sọ wéra pẹ̀lú ìwé kan tí wọ́n kọ ní sáà yìí. Nínú ìwé kan tí wọ́n kọ nípa Ogun Àgbáyé Kejì lẹ́nu àìpẹ́ yìí, wọ́n pe olórí ìjọba Jámánì ní “Führer,” “Adolf Hitler,” wọ́n sì tún pè é ní “Hitler” lójú ewé tí ò fi bẹ́ẹ̀ jìn síra. Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni jẹ́ dá a láṣà láti sọ pé èyí ni ẹ̀rí tó fi hàn pé òǹkọ̀wé mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló kọ̀wé náà?

Síbẹ̀síbẹ̀, ọ̀kan-ò-jọ̀kan ìyípadà ló ṣì ń bá àbá èrò orí Wellhausen. Lára wọn ni àbá èrò orí nípa òǹkọ̀wé tó lo orúkọ Jèhófà Ọlọ́run lemọ́lemọ́. Kì í wá ṣe pé wọ́n ní kì í ṣe Mósè ló kọ̀ ọ́ nìkan ni o, wọ́n tiẹ̀ tún sọ pé obìnrin ni òǹkọ̀wé ọ̀hún pàápàá.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́