ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • bm apá 12 ojú ìwé 15
  • Ọgbọ́n Ọlọ́run Tó Ń Mú Ká Wà Láàyè

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọgbọ́n Ọlọ́run Tó Ń Mú Ká Wà Láàyè
  • Kí Ló Wà Nínú Bíbélì?
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ní Ọgbọ́n, Kí O Sì Gba Ìbáwí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Òwe 22:6—“Tọ́ Ọmọdé ní Ọ̀nà Tí Yóò Tọ̀”
    Àlàyé Àwọn Ẹsẹ Bíbélì
  • Sólómọ́nì Fọgbọ́n Ṣàkóso
    Kí Ló Wà Nínú Bíbélì?
  • Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Òwe
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
Àwọn Míì
Kí Ló Wà Nínú Bíbélì?
bm apá 12 ojú ìwé 15
Àwọn èèyàn tó gbé ayé ní ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì ń kó ọkà jọ

Apá 12

Ọgbọ́n Ọlọ́run Tó Ń Mú Ká Wà Láàyè

Ìwé Òwe jẹ́ àkójọ àwọn ìmọ̀ràn tí Ọlọ́run mí sí, èyí tó máa ń pèsè ìtọ́sọ́nà téèyàn nílò láti máa gbé ìgbé ayé ojoojúmọ́. Sólómọ́nì ló kọ èyí tó pọ̀ jù lọ nínú wọn

ṢÉ OLÙṢÀKÓSO tó gbọ́n ni Jèhófà? Ọ̀nà tó ṣe tààràtà jù lọ tá a lè gbà dáhùn ìbéèrè yẹn ni pé ká ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ìmọ̀ràn tó máa ń fúnni. Ṣé àwọn ìmọ̀ràn náà máa ń ranni lọ́wọ́? Ṣé bá a bá fàwọn ìmọ̀ràn náà sílò, ó máa mú kí ìgbé ayé wá dára sí i kó sì túbọ̀ nítumọ̀? Ọlọ́gbọ́n Ọba Sólómọ́nì kọ ọgọ́rọ̀ọ̀rún òwe. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ohun téèyàn ń gbélé ayé ṣe táwọn òwe náà ò sọ̀rọ̀ bá. Gbé àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò.

Bá a ṣe lè gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run. Ìgbẹ́kẹ̀lé ṣe kókó béèyàn bá máa ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. Sólómọ́nì kọ̀wé pé: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ. Ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.” (Òwe 3:5, 6) Bá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run nípa wíwá ìtọ́sọ́nà rẹ̀ tá a sì ń ṣègbọràn sí i, ó máa mú kí ìgbésí ayé wa nítumọ̀ gan-an. Irú ìgbé ayé bẹ́ẹ̀ máa ń jẹ́ ká múnú Ọlọ́run dùn, ìyẹn á sì mú kí Jèhófà lè pèsè ìdáhùn sáwọn ìpèníjà Sátánì, tó jẹ́ alátakò Rẹ̀.—Òwe 27:11.

Bá a ṣe lè máa fọgbọ́n báni lò. Ìmọ̀ràn tí Ọlọ́run fún àwọn ọkọ, àwọn aya, àtàwọn ọmọ bọ́ sí i gẹ́lẹ́ lákòókò yìí ju ti ìgbàkigbà rí lọ. Nígbà tí Ọlọ́run ń fáwọn ọkọ ní ìtọ́sọ́nà pé kí wọ́n má ṣe dalẹ̀ àwọn aya wọn, ó gbà wọ́n níyànjú pé: “Máa yọ̀ pẹ̀lú aya ìgbà èwe rẹ.” (Òwe 5:18-20) Nínú ìwé Òwe, àwọn obìnrin tó ti lọ́kọ lè rí àpèjúwe tó jíire nípa obìnrin tó dáńgájíá, ẹni tí ọkọ rẹ̀ àtàwọn ọmọ rẹ̀ ń kan sáárá sí. (Òwe, orí 31) Ìtọ́ni sì tún wà níbẹ̀ fáwọn ọmọ pé kí wọ́n máa ṣègbọràn sáwọn òbí wọn. (Òwe 6:20) Ìwé Òwe tún fi hàn pé ìbánidọ́rẹ̀ẹ́ dára, torí pé ẹni tó bá ń ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ á máa lépa ìmọtara-ẹni-nìkan. (Òwe 18:1) Àwọn ọ̀rẹ́ lè nípa rere tàbí ipa búburú lórí wa, torí náà ó yẹ ká fọgbọ́n yan àwọn ọ̀rẹ́ wa.—Òwe 13:20; 17:17.

Bá a ṣe lè máa fọgbọ́n gbé ìgbé ayé wa. Ìwé Òwe ní ọ̀pọ̀ ìmọ̀ràn ṣíṣeyebíye tó dá lórí yíyẹra fún ọtí àmujù, béèyàn ṣe lè máa ní èrò rere, béèyàn ṣe lè máa mú èrò búburú kúrò lọ́kàn àti béèyàn ṣe lè jẹ́ òṣìṣẹ́ aláápọn. (Òwe 6:6; 14:30; 20:1) Ó kìlọ̀ pé ká má ṣe gbẹ́kẹ̀ lé èrò èèyàn tí kò bá ti Ọlọ́run dọ́gba torí pé ó máa ń yọrí sí ìjábá. (Òwe 14:12) Ó rọ̀ wá pé ká pa ọkàn-àyà wa, ìyẹn ẹni tá a jẹ́ ní inú, mọ́ kúrò lọ́wọ́ àwọn ohun tó lè sọ ọ́ dìbàjẹ́, ó sì rán wa létí pé “láti inú [ọkàn-àyà] ni àwọn orísun ìyè ti wá.”—Òwe 4:23.

Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn kárí ayé ti rí i pé béèyàn bá ń tẹ̀ lé irú ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀, ó máa mú kí ìgbésí ayé ẹni sunwọ̀n. Nítorí èyí, wọ́n ní ìdí tó pọ̀ láti tẹ́wọ́ gba Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Olùṣàkóso wọn.

​—A gbé e ka ìwé Òwe.

  • Kí la lè rí kọ́ bá a bá fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ ìwé Òwe?

  • Amọ̀nà wo ni ìwé Òwe fún wa nípa gbígbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run, fífọgbọ́n gbé ìgbé ayé wa àti fífọgbọ́n báni lò?

ONÍWÀÁSÙ

Ibo la ti lè rí ìtẹ́lọ́rùn, ká sì mọ ohun tí Ọlọ́run torí ẹ̀ dá wa sáyé? Sólómọ́nì wà nípò tó fi lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí. Torí pó ní ibú ọrọ̀, ọgbọ́n àti ọlá àṣẹ, ó ṣeé ṣe fún un láti wádìí kó sì mọ̀ bóyá àwọn nǹkan wọ̀nyí lè fún òun ní ojúlówó ayọ̀. Ó lépa adùn tí àwọn nǹkan tara lè fúnni, ó fẹ́ ọ̀pọ̀ obìnrin tó rẹwà, ó sì gbádùn eré ìtura gan-an. Ó dáwọ́ lé kíkọ́ àwọn ilé ńláńlá. Ó ṣèwádìí ọgbọ́n tó wà nínú àwọn ìwé táwọn tó mòye kọ. Kí ló rí? “Asán ni gbogbo rẹ̀.” Àmọ́, ó sọ òkodoro ọ̀rọ̀ kan. Ó ní: “Òpin ọ̀ràn náà, lẹ́yìn gbígbọ́ gbogbo rẹ̀, ni pé: Bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́, kí o sì pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́. Nítorí èyí ni gbogbo iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe ti ènìyàn.”—Oníwàásù 12:8, 13.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́