ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • bm apá 14 ojú ìwé 17
  • Ọlọ́run Gbẹnu Àwọn Wòlíì Rẹ̀ Sọ̀rọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọlọ́run Gbẹnu Àwọn Wòlíì Rẹ̀ Sọ̀rọ̀
  • Kí Ló Wà Nínú Bíbélì?
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Wòlíì Tí Wọ́n Jíṣẹ́ Tó Lè Ṣe Wá Láǹfààní
    Máa Fi Ọjọ́ Jèhófà Sọ́kàn
  • Wòlíì Kan Tó Wà Nígbèkùn Rí Ohun Tó Ń Bọ̀ Wá Ṣẹlẹ̀ Lọ́jọ́ Iwájú Nínú Ìran
    Kí Ló Wà Nínú Bíbélì?
  • Mèsáyà Dé
    Kí Ló Wà Nínú Bíbélì?
  • Ṣé Àwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Nípa Mèsáyà Fẹ̀rí Hàn Pé Jésù Ni Mèsáyà Náà?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
Àwọn Míì
Kí Ló Wà Nínú Bíbélì?
bm apá 14 ojú ìwé 17
Wòlíì Ọlọ́run kan ń jíṣẹ́ Ọlọ́run

Apá 14

Ọlọ́run Gbẹnu Àwọn Wòlíì Rẹ̀ Sọ̀rọ̀

Jèhófà yan àwọn wòlíì láti kéde ìdájọ́ fáwọn èèyàn, kí wọ́n sì tún sọ fún wọn nípa ìjọsìn mímọ́ àti Mèsáyà tó ń bọ̀ wá

NÍGBÀ táwọn ọba Ísírẹ́lì àti Júdà ń ṣàkóso, àwùjọ àwọn èèyàn kan bẹ̀rẹ̀ sí í gbẹnu sọ fún Ọlọ́run, ìyẹn ni àwọn wòlíì. Wọ́n jẹ́ àwọn èèyàn tó ní ìgbàgbọ́ àti ìgboyà àrà ọ̀tọ̀, tí wọ́n sì ń polongo àwọn nǹkan tí Ọlọ́run bá sọ. Mẹ́rin rèé lára àwọn kókó pàtàkì tí ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì Ọlọ́run dá lé.

1. Ìparun Jerúsálẹ́mù. Ọjọ́ pẹ́ táwọn wòlíì Ọlọ́run, pàápàá Aísáyà àti Jeremáyà, ti ń kìlọ̀ pé Ọlọ́run máa pa Jerúsálẹ́mù run, ó sì máa pa á tì. Láìfọ̀rọ̀ bọpo bọyọ̀, wọ́n sọ ìdí tí Ọlọ́run fi máa tú ìbínú rẹ̀ sórí ìlú náà. Àwọn ará Jerúsálẹ́mù sọ pé àwọn ń sin Jèhófà, àmọ́ irọ́ gbáà nìyẹn torí pé wọ́n ń lọ́wọ́ nínú onírúurú ẹ̀sìn èké, ìwà ìbàjẹ́ àti ìwà ipá.—2 Àwọn Ọba 21:10-15; Aísáyà 3:1-8, 16-26; Jeremáyà 2:1–3:13.

2. Ìmúpadàbọ̀sípò ìjọsìn mímọ́. Lẹ́yìn àádọ́rin [70] ọdún ní ìgbèkùn, Ọlọ́run máa dá àwọn èèyàn rẹ̀ nídè kúrò ní Bábílónì. Wọ́n máa pa dà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn tó ti dahoro, wọ́n á sì tún tẹ́ńpìlì Jèhófà kọ́ ní Jerúsálẹ́mù. (Jeremáyà 46:27; Ámósì 9:13-15) Ní nǹkan bí igba [200] ọdún ṣáájú, Aísáyà sọ àsọtẹ́lẹ̀ orúkọ ẹni tí olùdáǹdè náà máa jẹ́, ìyẹn ni Kírúsì, tó máa ṣẹ́gun Bábílónì tó sì máa yọ̀ǹda káwọn èèyàn Ọlọ́run mú ìjọsìn mímọ́ pa dà bọ̀ sípò. Aísáyà tiẹ̀ sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ọgbọ́n ogun tó ṣàrà ọ̀tọ̀ tí Kírúsì máa lò.—Aísáyà 44:24–45:3.

Àwọn Júù tó wà ní ìgbèkùn ní Bábílónì pa dà sí Jerúsálẹ́mù

3. Dídé Mèsáyà àtàwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ sí i. Ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ni wọ́n máa bí Mèsáyà sí. (Míkà 5:2) Ó máa jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ó máa gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọ Jerúsálẹ́mù. (Sekaráyà 9:9) Bó tilẹ̀ jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ àti onínúure, kò ní gbajúmọ̀, ọ̀pọ̀ ò sì ní gba tiẹ̀. (Aísáyà 42:1-3; 53:1, 3) Ìpa ìkà ni wọ́n máa pa á. Ṣé ibi tí ìgbésí ayé ẹ̀ máa parí sí náà nìyẹn? Rárá o, torí pé ẹbọ tó máa fi ara rẹ̀ rú máa mú kó ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀ láti rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀. (Aísáyà 53:4, 5, 9-12) Ìyẹn ò sì lè ṣeé ṣe àyàfi bó bá jíǹde

4. Bí Mèsáyà ṣe máa ṣàkóso ayé. Kò ṣeé ṣe rárá fáwọn èèyàn aláìpé láti ṣàkóso ara wọn kí àlàáfíà sì jọba, àmọ́ Mèsáyà Ọba la ó máa pè ní Ọmọ Aládé Àlàáfíà. (Aísáyà 9:6, 7; Jeremáyà 10:23) Nígbà tó bá ń ṣàkóso, gbogbo èèyàn á máa gbé ní àlàáfíà, àwọn ẹranko ò sì ní máa pa wọ́n lára. (Aísáyà 11:3-7) Àìsàn ò ní sí mọ́. (Aísáyà 33:24) A óò gbé ikú pàápàá mì títí láé. (Aísáyà 25:8) Nígbà ìṣàkóso Mèsáyà, a óò jí àwọn òkú dìde kí wọ́n lè máa wà láàyè nìṣó lórí ilẹ̀ ayé.—Dáníẹ́lì 12:13.

​—A gbé e ka ìwé Aísáyà, Jeremáyà, Dáníẹ́lì, Ámósì, Míkà àti Sekaráyà.

  • Irú iṣẹ́ wo làwọn wòlíì Ọlọ́run jẹ́?

  • Báwo làwọn wòlíì ṣe sọ àsọtẹ́lẹ̀ ìparun Jerúsálẹ́mù àti ìmúpadàbọ̀sípò ìjọsìn mímọ́?

  • Kí làwọn wòlíì Jèhófà sọ nípa Mèsáyà àtàwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ sí i?

  • Báwo làwọn wòlíì ṣe sọ pé nǹkan á rí nígbà tí Mèsáyà bá ń ṣàkóso ayé?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́