ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • rk apá 2 ojú ìwé 4-5
  • Kí Ni Ìgbàgbọ́ Òdodo?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ni Ìgbàgbọ́ Òdodo?
  • Ìgbàgbọ́ Òdodo Ló Máa Mú Kó O Ní Ayọ̀
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Báwo Lo Ṣe Lè Ní Ìgbàgbọ́ Òdodo?
  • Máa Lo Ìgbàgbọ́ Nínú Àwọn Ìlérí Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
  • Ìgbàgbọ́—Ànímọ́ Tó Ń Sọni Di Alágbára
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
  • “Fún Wa Ní Ìgbàgbọ́ Sí I”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Àwọn Tó Ní Ìgbàgbọ́ Òdodo Lóde Òní
    Ìgbàgbọ́ Òdodo Ló Máa Mú Kó O Ní Ayọ̀
Àwọn Míì
Ìgbàgbọ́ Òdodo Ló Máa Mú Kó O Ní Ayọ̀
rk apá 2 ojú ìwé 4-5

APA 2

Kí Ni Ìgbàgbọ́ Òdodo?

Ọkùnrin kan n wo owó

Owó gidi lo lè fi ra nǹkan, bákan náà ìgbàgbọ́ òdodo ló lè ṣeni láǹfààní

KÉÈYÀN ní ìgbàgbọ́ òdodo ju pé kó ṣáà ti gbà pé Ọlọ́run wà. Àìmọye èèyàn ló gbà pé Ọlọ́run wà, àmọ́ tí wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ ń hu ìwà láabi. Ṣe ni irú ìgbàgbọ́ tí àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ sọ pé àwọn ní dà bí ayédèrú owó. Ayédèrú owó máa ń jọ owó gidi àmọ́ bébà lásán, tí kò lè ra nǹkan kan ni. Kí wá ni ìgbàgbọ́ gidi, tó jẹ́ ìgbàgbọ́ òdodo?

Ìgbàgbọ́ òdodo dá lórí kéèyàn ní ìmọ̀ tó kún rẹ́rẹ́ nípa Ìwé Mímọ́. Ìwé Mímọ́ tí Ọlọ́run mí sí yìí sọ òtítọ́ nípa Ọlọ́run fún wa, ó sì ń jẹ́ ká mọ Ọlọ́run. Ó sọ àwọn òfin Ọlọ́run fún wa, ó jẹ́ ká mọ àwọn ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn láti ṣe, ó sì kọ́ wa ní àwọn ẹ̀kọ́ nípa Ọlọ́run. Lára àwọn ẹ̀kọ́ náà rèé:

  • Ọ̀kan ṣoṣo ni Ọlọ́run. Kò sí ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun tó bá a dọ́gba.

  • Jésù (Isa) kì í ṣe Ọlọ́run Olódùmarè. Wòlíì (Anabi) Ọlọ́run ni.

  • Ọlọ́run kò fẹ́ ká bọ òrìṣà èyíkéyìí rárá.

  • Ọjọ́ ìdájọ́ ń bẹ níwájú fún gbogbo ẹ̀dá.

  • Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn máa jíǹde sínú Párádísè.

Ìgbàgbọ́ òdodo ń mú ká máa ṣe iṣẹ́ rere. Irú àwọn iṣẹ́ rere bẹ́ẹ̀ ń gbé Ọlọ́run ga, ó sì máa ń ṣe àwa àti àwọn ẹlòmíì láǹfààní. Ara iṣẹ́ rere ọ̀hún ni pé

  • ká máa jọ́sìn Ọlọ́run.

  • ká máa hu àwọn ìwà tí Ọlọ́run ń fẹ́, ní pàtàkì ká ní ìfẹ́.

  • ká má ṣe jẹ́ elétekéte, ká má sì gba ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ láyè.

  • ká má ṣe kọ Ọlọ́run sílẹ̀ nígbà ìṣòro.

  • ká máa fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ àwọn ẹlòmíì.

Ìdílé kan gbé oúnjẹ wá fún ìyá àgbàlagbà kan

Ìgbàgbọ́ òdodo máa ń mú kí á ṣe iṣẹ́ rere

Báwo Lo Ṣe Lè Ní Ìgbàgbọ́ Òdodo?

Ọkùnrin kan ń dára yá kó lè lágbára sí i

Bí ìgbà tí iṣan ń nípọn sí i ni ìgbàgbọ́ rẹ yóò máa lágbára sí i bí o bá ń ṣe iṣẹ́ rere

Bẹ Ọlọ́run pé kó ràn ọ́ lọ́wọ́. Mósè (Musa) tó jẹ́ wòlíì Ọlọ́run, gbàdúrà sí Ọlọ́run pé: “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí n mọ àwọn ọ̀nà rẹ, kí n lè mọ̀ ọ́, kí n lè rí ojú rere lójú rẹ.”a Ọlọ́run gbọ́ àdúrà rẹ̀, ó sì ràn án lọ́wọ́. Ìgbàgbọ́ tí Mósè ní nínú Ọlọ́run ṣàrà ọ̀tọ̀, ìyẹn sì jẹ́ àpẹẹrẹ fún wa. Ọlọ́run máa ran ìwọ náà lọ́wọ́ kó o lè ní ìgbàgbọ́ òdodo.

Máa kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ déédéé. Lára Ìwé Mímọ́ tí Ọlọ́run mí sí ni Tórà (Taorata), Sáàmù (Sabura) àtàwọn ìwé Ìhìn Rere (Injila). Àwọn ìwé tí Ọlọ́run mí sí wà nínú Bíbélì Mímọ́, tó jẹ́ ìwé tó wà ní èdè tó pọ̀ jù lọ kárí ayé, tí àwọn èèyàn tó pọ̀ jù lọ kárí ayé sì ní lọ́wọ́. Ǹjẹ́ o ní Ìwé Mímọ́ yìí lọ́wọ́?

Máa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́. A lè fi ìgbàgbọ́ wé iṣan ara. Bó o bá ṣe ń lo iṣan ara tó, ni yóò ṣe máa nípọn sí i. Bákan náà, bó o bá ń ṣe àwọn ohun tó fi hàn pé o ní ìgbàgbọ́, ìgbàgbọ́ rẹ yóò máa lágbára sí i. Ìwọ fúnra rẹ yóò rí i pé ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run ń ṣeni láǹfààní. Ká sòótọ́, ìtọ́sọ́nà rere tó wà nínú Ìwé Mímọ́ ti mú kí ayé àìmọye èèyàn túbọ̀ dára. Túbọ̀ ka ìwé yìí síwájú, wàá rí àpẹẹrẹ àwọn èèyàn tí Ìwé Mímọ́ ti ṣe láǹfààní.

a Ẹ́kísódù 33:13.

Kí Ni Ìdáhùn Ìbéèrè Yìí?

  • Orí kí ni ìgbàgbọ́ òdodo dá lé?

  • Àwọn iṣẹ́ rere wo ni ìgbàgbọ́ òdodo máa ń mú ká ṣe?

  • Báwo ni o ṣe lè ní ìgbàgbọ́ òdodo?

Ọlọ́run Kò Jẹ́ Kí Wọ́n Pa Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ Run

Ó dájú pé Ọlọ́run jẹ́ kí Ìwé Mímọ́ gidi tí kò ní àdàlù ṣì wà títí di ìgbà tiwa lóde òní. Ọlọ́run Olódùmarè lágbára láti dáàbò bo ìwé tó jẹ́ ìwé òun fúnra rẹ̀. Ìwé Mímọ́ tó jẹ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ pé: “Koríko tútù ti gbẹ dànù, ìtànná ti rọ; ṣùgbọ́n ní ti ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wa, yóò wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—Aísáyà 40:8.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́