ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • rk apá 6 ojú ìwé 15-17
  • Torí Kí Ni Ọlọ́run Ṣe Dá Ilẹ̀ Ayé?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Torí Kí Ni Ọlọ́run Ṣe Dá Ilẹ̀ Ayé?
  • Ìgbàgbọ́ Òdodo Ló Máa Mú Kó O Ní Ayọ̀
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Ni Ète Ọlọrun fún Ilẹ̀ Ayé?
    Kí Ni Ọlọ́run Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?
  • Ibo Ni Párádísè Tí Bíbélì Sọ Máa Wà?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Ìdí Tí Ọ̀rọ̀ Nípa Ọgbà Édẹ́nì Fi Kàn Ẹ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Ṣé Ayé Máa Di Párádísè Lóòótọ́?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017
Àwọn Míì
Ìgbàgbọ́ Òdodo Ló Máa Mú Kó O Ní Ayọ̀
rk apá 6 ojú ìwé 15-17

APA 6

Torí Kí Ni Ọlọ́run Ṣe Dá Ilẹ̀ Ayé?

ỌLỌ́RUN dá ilẹ̀ ayé, ó fi ṣe ibùgbé tó dára gan-an fún àwa èèyàn. Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Ti Jèhófà ni ọ̀run, ṣùgbọ́n ilẹ̀ ayé ni ó fi fún àwọn ọmọ ènìyàn.”—Sáàmù 115:16.

Kí Ọlọ́run tó dá ọkùnrin àkọ́kọ́ tó ń jẹ́ Ádámù (Adama), ó ti kọ́kọ́ ya ibi kékeré kan sọ́tọ̀ nínú ayé, ibẹ̀ ń jẹ́ Édẹ́nì. Ó ṣe ọgbà ìdẹ̀ra kan tó lẹ́wà síbẹ̀. Ìwé Mímọ́ sọ pé Édẹ́nì yìí ni odò tó ń jẹ́ Yúfírétì àti èyí tó ń jẹ́ Tígírísì (ìyẹn Hídẹ́kẹ́lì) ti ṣàn jáde.a Àwọn èèyàn gbà pé àgbègbè ibi tí ọgbà Édẹ́nì yìí wà láyé ìgbà yẹn ni a ń pè ní ìlà-oòrùn orílẹ̀-èdè Tọ́kì lóde òní. Èyí fi hàn dájú pé ọgbà ìdẹ̀ra tó ń jẹ́ Édẹ́nì yìí ti wà rí lórí ilẹ̀ ayé yìí.

Ọlọ́run dá Ádámù, ó sì fi í sínú ọgbà Édẹ́nì “láti máa ro ó àti láti máa bójú tó o.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:15) Nígbà tó yá, Ọlọ́run dá ìyàwó fún Ádámù, orúkọ rẹ̀ ni Éfà (Hawawu). Ọlọ́run wá pa àṣẹ fún Ádámù àti Éfà pé: “Ẹ máa so èso, kí ẹ sì di púpọ̀, kí ẹ sì kún ilẹ̀ ayé, kí ẹ sì ṣèkáwọ́ rẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Ó ṣe kedere pé, Ọlọ́run “kò wulẹ̀ dá [ayé] lásán, [ṣe ni] ó ṣẹ̀dá rẹ̀ àní kí a lè máa gbé inú rẹ̀.”—Aísáyà 45:18.

Àmọ́, Ádámù àti Éfà ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run, wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ rú òfin Ọlọ́run. Nítorí náà, Ọlọ́run lé wọn jáde kúrò nínú ọgbà Édẹ́nì. Bó ṣe di pé èèyàn kò gbé inú Párádísè mọ́ nìyẹn. Ṣùgbọ́n, àkóbá tí ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù ṣe pọ̀ ju ìyẹn lọ. Ìwé Mímọ́ sọ fún wa pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ ti tipasẹ̀ ènìyàn kan wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀.”—Róòmù 5:12.

Ṣé Jèhófà wá pa ohun tó sọ pé òun fẹ́ ṣe nípa ilẹ̀ ayé tì ni, ìyẹn bó ṣe fẹ́ kí ilẹ̀ ayé jẹ́ Párádísè tí àwọn èèyàn aláyọ̀ yóò máa gbé? Rárá o! Ọlọ́run sọ pé: “Ọ̀rọ̀ mi tí ó ti ẹnu mi jáde . . . kì yóò padà sọ́dọ̀ mi láìní ìyọrísí, ṣùgbọ́n ó dájú pé yóò ṣe èyí tí mo ní inú dídùn sí, yóò sì ní àṣeyọrí sí rere tí ó dájú nínú èyí tí mo tìtorí rẹ̀ rán an.” (Aísáyà 55:11) Ó dájú pé Ọlọ́run yóò mú kí Párádísè tún pa dà wà lórí ilẹ̀ ayé!

Báwo ni ìgbé ayé wa ṣe máa rí nínú Párádísè? Wo àwọn ohun tí Ọlọ́run ṣèlérí nínú Ìwé Mímọ́, èyí tó wà ní ojú ìwé méjì tó tẹ̀ lé èyí.

a Ìwé Mímọ́ sọ nínú Jẹ́nẹ́sísì 2:10-14 pé: “Odò kan wà tí ń ṣàn jáde láti Édẹ́nì láti bomi rin ọgbà náà, ibẹ̀ ni ó sì ti bẹ̀rẹ̀ sí pínyà, ó sì di ohun tí a lè pè ní ẹ̀ka mẹ́rin. Orúkọ èyí èkíní ni Píṣónì . . . Orúkọ odò kejì sì ni Gíhónì . . . Orúkọ odò kẹta sì ni Hídẹ́kẹ́lì [tàbí Tígírísì]; òun ni èyí tí ó lọ sí ìlà-oòrùn Ásíríà. Odò kẹrin sì ni Yúfírétì.” Ní òde òní kò sí èèyàn tó mọ odó tó ń jẹ́ Píṣónì àti èyí tó ń jẹ́ Gíhónì, kò sì sí ẹni tó mọ ojú ibi tí odò méjèèjì yìí wà.

Kí Ni Ìdáhùn Ìbéèrè Yìí?

  • Kí ni ìdí tí Ọlọ́run fi dá ilẹ̀ ayé àti àwa èèyàn?

  • Báwo la ṣe mọ̀ pé ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn máa di ṣíṣe?

Àwọn èèyàn wà ní Párádísè

Párádísè Tí Yóò Wà Lórí Ilẹ̀ Ayé

Ọlọ́run yóò jí àwọn òkú dìde: “Gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn rẹ̀, wọn yóò sì jáde wá.”—Jòhánù 5:28, 29.

Kò ní sí ọjọ́ ogbó àti àìsàn àti ikú mọ́: “Kò sì sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’” (Aísáyà 33:24) Ọlọ́run “yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́.”—Ìṣípayá 21:4.

Oúnjẹ tó dára máa pọ̀ rẹpẹtẹ: “Ilẹ̀ ayé yóò máa mú èso rẹ̀ wá; Ọlọ́run, tí í ṣe Ọlọ́run wa, yóò bù kún wa.”—Sáàmù 67:6.

Ilé tó dára àti iṣẹ́ tó tẹ́ni lọ́rùn yóò wà: “Wọn yóò kọ́ ilé, wọn yóò sì máa gbé inú wọn . . . Iṣẹ́ ọwọ́ ara wọn ni àwọn àyànfẹ́ mi yóò sì lò dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.” —Aísáyà 65:21, 22.

Kò ní sí ogun àti ìwà ọ̀daràn àti ìwà jàgídíjàgan mọ́: Jèhófà yóò “mú kí ogun kásẹ̀ nílẹ̀ títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé.” (Sáàmù 46:9) Ní ti “àwọn ẹni burúkú, a óò ké wọn kúrò lórí ilẹ̀ ayé gan-an.”—Òwe 2:22.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́