ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ll apá 8 ojú ìwé 18-19
  • Kí Ni Ikú Jésù Mú Kó Ṣeé Ṣe fún Ọ?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ni Ikú Jésù Mú Kó Ṣeé Ṣe fún Ọ?
  • Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Apa 8
    Tẹ́tí sí Ọlọ́run
  • Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?
    Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?
  • Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Nípa Ìjọba Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
Àwọn Míì
Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé
ll apá 8 ojú ìwé 18-19

APÁ 8

Kí Ni Ikú Jésù Mú Kó Ṣeé Ṣe fún Ọ?

Jésù kú torí ká lè ní ìyè. Jòhánù 3:16

Àwọn obìnrin ń yọjú wo ibojì Jésù tó ṣófo

Ọjọ́ mẹ́ta lẹ́yìn tí Jésù kú, àwọn obìnrin kan lọ síbi ibojì rẹ̀, wọ́n sì rí i pé ibẹ̀ ṣófo. Jèhófà ti jí Jésù dìde.

Jésù yọ sí àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, ó wá lọ sọ́run

Lẹ́yìn náà, Jésù fara han àwọn àpọ́sítélì rẹ̀.

Bẹ́ẹ̀ ni o, Jèhófà jí Jésù dìde, Jésù sì ti di ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára tí kò lè kú mọ́. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù rí i bó ṣe ń lọ sí ọ̀run.

  • Kí ni “èrè” ẹ̀ṣẹ̀?​—Róòmù 6:23.

  • Jésù mú kí ìyè àìnípẹ̀kun ṣeé ṣe.​—Róòmù 5:21.

Ọlọ́run jí Jésù dìde, ó sì sọ ọ́ di Ọba Ìjọba Ọlọ́run. Dáníẹ́lì 7:13, 14

Jésù ń ṣàkóso àwọn èèyàn tó wà nínú Párádísè láyé látorí ìtẹ́ rẹ̀ nínú Ìjọba náà

Jésù fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ kó lè fi san ìràpadà fún aráyé. (Mátíù 20:28) Ìràpadà yẹn ni Ọlọ́run lò láti mú kó ṣeé ṣe fún wa láti wà láàyè títí láé.

Jèhófà fi Jésù jẹ Ọba tó máa ṣàkóso ayé. Àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) olóòótọ́ èèyàn tí Ọlọ́run jí dìde láti ayé sí ọ̀run ló máa ṣàkóso pẹ̀lú rẹ̀. Jésù àti àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) yìí ló máa para pọ̀ di Ìjọba Ọlọ́run, wọ́n á sì fi òdodo ṣàkóso láti ọ̀run.​—Ìfihàn 14:​1-3.

Ìjọba Ọlọ́run máa sọ ayé di Párádísè. Kò ní sí ogun, ìwà ọ̀daràn, ipò òṣì àti ebi mọ́. Inú àwọn èèyàn á máa dùn gan-an.​—Sáàmù 145:16.

  • Àwọn ìbùkún wo ni Ìjọba Ọlọ́run máa mú wá?​—Sáàmù 72.

  • Ó yẹ ká máa gbàdúrà pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé.​—Mátíù 6:10.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́