APÁ 12
Báwo Ni Ìdílé Rẹ Ṣe Lè Ní Ayọ̀?
Ìfẹ́ ló máa jẹ́ kí ìdílé ní ayọ̀. Éfésù 5:33
Ìlànà Ọlọ́run ni pé ọkùnrin kan àti obìnrin kan ni kí ó fẹ́ ara wọn.
Ọkọ tó nífẹ̀ẹ́ máa ń fi ọwọ́ jẹ̀lẹ́ńkẹ́ mú aya rẹ̀, ó sì máa ń mọ bí nǹkan ṣe ń rí lára rẹ̀.
Ó yẹ kí ìyàwó máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ọkọ rẹ̀.
Ó yẹ kí àwọn ọmọ máa gbọ́ràn sí àwọn òbí wọn lẹ́nu.
Ẹ jẹ́ onínúure àti olóòótọ́, ẹ má ṣe ya ọ̀dájú, ẹ má sì jẹ́ aláìṣòótọ́. Kólósè 3:5, 8-10
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé kí ọkọ nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ bí ara òun fúnra rẹ̀ àti pé kí aya máa bọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀.
Kò dáa rárá kí èèyàn ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹni tí kì í ṣe aya tàbí ọkọ ẹni. Bákan náà ni kò dáa kí èèyàn fẹ́ ju ìyàwó kan lọ.
Ọ̀rọ̀ Jèhófà ń jẹ́ kí ìdílé mọ bí wọ́n ṣe lè jẹ́ aláyọ̀.