Ẹ̀KỌ́ 6
Ìrètí Wo Ló Wà fún Àwọn Tó Ti Kú?
1. Ìròyìn ayọ̀ wo ló wà nípa àwọn tó ti kú?
Nígbà tí Jésù fi máa dé sí Bẹ́tánì nítòsí Jerúsálẹ́mù, ó ti pé ọjọ́ mẹ́rin tí Lásárù ọ̀rẹ́ rẹ̀ ti kú. Jésù tẹ̀ lé Màríà àti Màtá tí wọ́n jẹ́ ẹ̀gbọ́n ẹni tó kú náà lọ sí ibi tí wọ́n sin ín sí. Ká tó ṣẹ́jú pẹ́, èrò ti pé jọ. Wo bí inú Màtá àti Màríà ṣe máa dùn tó nígbà tí Jésù jí Lásárù dìde!—Ka Jòhánù 11:21-24, 38-44.
Màtá ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé ìròyìn ayọ̀ kan wà nípa àwọn tó ti kú. Ó mọ̀ pé Jèhófà máa jí àwọn òkú dìde kí wọ́n lè pa dà máa gbé lórí ilẹ̀ ayé.—Ka Jóòbù 14:14, 15.
2. Kí ló ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn tó ti kú?
Ọlọ́run sọ fún Ádámù pé: “Erùpẹ̀ ni ọ́, ìwọ yóò sì pa dà sí erùpẹ̀.”—JẸ́NẸ́SÍSÌ 3:19.
Erùpẹ̀ ni Ọlọ́run fi dá àwa èèyàn. (Jẹ́nẹ́sísì 2:7; 3:19) A kì í ṣe ẹ̀dá ẹ̀mí tó gbé àwọ̀ èèyàn wọ̀. Ẹ̀dá ẹlẹ́ran ara ni wá, torí náà kò sí ohun kankan lára wa tó máa ń wà láàyè lẹ́yìn tá a bá kú. Tá a bá kú, ọpọlọ wa parí iṣẹ́ nìyẹn, a ò tún lè ronú mọ́. Ìdí nìyẹn tí Lásárù ò fi sọ pé òun rí ohunkóhun nígbà tí òun kú, torí pé ẹni tó ti kú kò mọ ohunkóhun mọ́.—Ka Sáàmù 146:4; Oníwàásù 9:5, 6, 10.
Ṣé Ọlọ́run máa ń dá àwọn èèyàn lóró nínú iná lẹ́yìn tí wọ́n bá kú? Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn òkú kò mọ ohunkóhun, torí náà, ó ṣe kedere pé ẹ̀kọ́ èké ni ẹ̀kọ́ iná ọ̀run àpáàdì, ńṣe ni irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ ń ba Ọlọ́run lórúkọ jẹ́. Ohun ìríra gbáà ni fífi iná dáni lóró jẹ́ lójú Ọlọ́run.—Ka Jeremáyà 7:31.
Wo Fídíò náà Kí Ló Ń Ṣẹlẹ̀ sí Àwọn Tó Ti Kú?
3. Ṣé àwọn òkú lè bá wa sọ̀rọ̀?
Àwọn òkú ò lè sọ̀rọ̀, wọn ò sì lè gbọ́ràn. (Sáàmù 115:17) Àmọ́ àwọn áńgẹ́lì kan burú, wọ́n sì lè bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ bí ẹni pé ẹni tó ti kú ló ń sọ̀rọ̀. (2 Pétérù 2:4) Jèhófà ò fẹ́ ká máa bá òkú sọ̀rọ̀.—Ka Diutarónómì 18:10, 11.
4. Àwọn wo ni Ọlọ́run máa jí dìde?
Àìmọye èèyàn tó ti kú tí wọ́n wà nínú ibojì ni Ọlọ́run máa jí pa dà sí ayé. Kódà, Ọlọ́run máa jí àwọn kan tí kò mọ Ọlọ́run tí wọ́n sì ti hùwà búburú kí wọ́n tó kú.—Ka Lúùkù 23:43; Ìṣe 24:15.
Àwọn tí Ọlọ́run bá jí dìde máa láǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa Ọlọ́run kí wọ́n sì ṣègbọràn sí Jésù láti fi hàn pé wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀. (Ìfihàn 20:11-13) Àwọn tó bá ṣe rere lẹ́yìn tí Ọlọ́run jí wọn dìde máa wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé.—Ka Jòhánù 5:28, 29.
5. Kí ni àjíǹde jẹ́ ká mọ̀ nípa Jèhófà?
Bí Ọlọ́run ṣe rán Ọmọ rẹ̀ pé kó wá kú nítorí wa ló jẹ́ ká nírètí pé àwọn òkú máa jíǹde. Torí náà, àjíǹde kọ́ wa pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa àti pé ó fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí hàn sí wa. Tí àwọn òkú bá jíǹde, ta ló ń wù ẹ́ gan-an pé kó o rí?—Ka Jòhánù 3:16; Róòmù 6:23.