ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w11 6/1 ojú ìwé 16-17
  • Ǹjẹ́ Ìrètí Wà fún Àwọn Tó Ti Kú?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ Ìrètí Wà fún Àwọn Tó Ti Kú?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìrètí Wo Ló Wà fún Àwọn Tó Ti Kú?
    Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run!
  • Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Àwọn Olólùfẹ́ Wa Tí Wọ́n Ti Kú?
    Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun
  • Ojúlówó Ìrètí Fáwọn Èèyàn Rẹ Tó Ti Kú
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Ohun Kan Ṣoṣo Tó Máa Fòpin sí Ikú!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
w11 6/1 ojú ìwé 16-17

Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

Ǹjẹ́ Ìrètí Wà fún Àwọn Tó Ti Kú?

Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a béèrè àwọn ìbéèrè tó o ti lè máa ṣe kàyéfì nípa wọn, a sì tún sọ ibi tó o ti lè rí ìdáhùn wọn kà nínú Bíbélì rẹ. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti bá ẹ sọ̀rọ̀ lórí ohun tí àwọn ìdáhùn náà jẹ́.

1. Ìrètí wo ló wà fún àwọn tó ti kú?

Nígbà tí Jésù fi máa dé Bẹ́tánì nítòsí Jerúsálẹ́mù, ó ti di ọjọ́ mẹ́rin tí Lásárù ọ̀rẹ́ rẹ̀ ti kú. Jésù àtàwọn ẹ̀gbọ́n Lásárù, ìyẹn Màtá àti Màríà lọ sí ibi tí wọ́n sin òkú náà sí. Kò sí pẹ́ tí èrò rẹpẹtẹ fi pé jọ. Ǹjẹ́ o lè fojú inú wo bí ayọ̀ Màtá àti Màríà ti pọ̀ tó nígbà tí Jésù jí Lásárù dìde?—Ka Jòhánù 11:20-24, 38-44.

Màtá ní ìgbàgbọ́ pé, àwọn òkú máa jíǹde. Ó ti pẹ́ táwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà ti mọ̀ pé lọ́jọ́ iwájú, Ọlọ́run máa jí àwọn òkú dìde.—Ka Jóòbù 14:14, 15.

2. Kí ló ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn tó ti kú?

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ipá ìwàláàyè tàbí “ẹ̀mí,” ló ń mú kí èèyàn àti ẹranko máa wà láàyè, síbẹ̀ a kò ní ẹ̀mí tó máa ń wà láàyè lẹ́yìn téèyàn bá ti kú. (Oníwàásù 3:19; Jẹ́nẹ́sísì 7:21, 22) Ẹ̀dá tí a lè fojú rí ni wá, erùpẹ̀ sì ni Ọlọ́run fi dá wa. (Jẹ́nẹ́sísì 2:7; 3:19) Nígbà tí a bá kú, ọpọlọ wa á kú, a kò sì ní lè ronú mọ́. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé, nígbà tí Lásárù jíǹde, kò ṣàlàyé pé ohun kankan ṣẹlẹ̀ sí òun nígbà tóun ti kú, nítorí pé àwọn òkú kò mọ nǹkan kan.—Ka Sáàmù 146:4; Oníwàásù 9:5, 10.

Ó ṣe kedere pé àwọn òkú kò lè jìyà. Nítorí náà, irọ́ ni ohun tí àwọn kan fi ń kọ́ni pé Ọlọ́run ń fìyà jẹ àwọn èèyàn lẹ́yìn tí wọ́n bá ti kú. Ńṣe ni ẹ̀kọ́ yìí ń ba Ọlọ́run lórúkọ jẹ́ torí pé Ọlọ́run kórìíra fífi iná dá àwọn èèyàn lóró.—Ka Jeremáyà 7:31.

3. Ǹjẹ́ a lè bá àwọn òkú sọ̀rọ̀?

Àwọn òkú kò lè sọ̀rọ̀. (Sáàmù 115:17) Àmọ́ tí àwọn ańgẹ́lì burúkú bá bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀, wọ́n lè díbọ́n bíi pé ẹni tó ti kú ló ń sọ̀rọ̀. (2 Pétérù 2:4) Jèhófà sọ pé, a kò gbọ́dọ̀ bá òkú sọ̀rọ̀.—Ka Diutarónómì 18:10, 11.

4. Àwọn wo ló máa jíǹde?

Nínú ayé tuntun tó ń bọ̀, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn tó wà nínú sàréè ni wọ́n máa jíǹde. Àní àwọn kan pàápàá tí wọ́n ṣe ohun búburú nítorí pé wọn kò mọ Jèhófà máa jíǹde.—Ka Lúùkù 23:43; Ìṣe 24:15.

Àwọn tó jíǹde máa láǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa Ọlọ́run, wọ́n á sì láǹfààní láti lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù nípa ṣíṣe ìgbọràn sí i. (Ìṣípayá 20:11-13) Àwọn tó jíǹde tí wọ́n sì ṣe ohun rere máa láǹfààní láti gbádùn ìwàláàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé. Àmọ́ ṣá o, àwọn kan tí wọ́n jíǹde kò ní jáwọ́ nínú ìwà búburú. Ìyẹn á sì mú kí àjíǹde wọn yọrí sí “àjíǹde ìdájọ́.”—Ka Jòhánù 5:28, 29.

5. Kí ni àjíǹde kọ́ wa nípa Jèhófà?

Àjíǹde ṣeé ṣe nítorí pé Ọlọ́run rán Ọmọ rẹ̀ láti kú nítorí wa. Nítorí náà, inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti ìfẹ́ léyìí jẹ́ látọ̀dọ̀ Jèhófà.—Ka Jòhánù 3:16; Róòmù 6:23.

Fún àlàyé síwájú sí i, ka orí 6 àti 7 ìwé yìí, Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Ọlọ́run dá Ádámù látinú erùpẹ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́