Ohun Kan Ṣoṣo Tó Máa Fòpin sí Ikú!
ỌKÙNRIN kan tó ń jẹ́ Lásárù àtàwọn àbúrò rẹ̀ obìnrin, Màtá àti Màríà, ń gbé ní ìlú Bẹ́tánì tó wà ní nǹkan bíi kìlómítà mẹ́ta sí Jerúsálẹ́mù. Lọ́jọ́ kan tí Jésù ọ̀rẹ́ wọn rìnrìn àjò, àìsàn líle kan ki Lásárù mọ́lẹ̀. Ọkàn àwọn àbúrò Lásárù ò balẹ̀ nítorí àìsàn tó ń ṣe é. Ni wọ́n bá ránṣẹ́ sí Jésù. Lọ́jọ́ kẹta tí ìròyìn dé etígbọ̀ọ́ Jésù ni Jésù gbéra láti lọ rí Lásárù. Bí òun àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ṣe ń lọ lójú ọ̀nà, ó sọ fún wọn pé òun fẹ́ lọ jí Lásárù lójú oorun. Àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ kọ́kọ́ rò pé oorun ló sùn lóòótọ́, àmọ́ Jésù là á mọ́lẹ̀ fún wọn pé, “Lásárù ti kú.”—Jòhánù 11:1-14.
Nígbà tí Jésù débi tí wọ́n sin Lásárù sí, ó ní kí wọ́n gbé òkúta tí wọ́n fi bo ojú hòrò tí wọ́n sin ín sí kúrò. Ó wá gbàdúrà sókè ketekete, ó sì pàṣẹ pé: “Lásárù, jáde wá!” Ó sì jáde wá lóòótọ́. Bí Lásárù tó ti kú fún odindi ọjọ́ mẹ́rin ṣe jíǹde nìyẹn.—Jòhánù 11:38-44.
Ìtàn ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Lásárù yìí fi hàn pé àjíǹde ni ohun tó máa fòpin sí ikú. Àmọ́, ṣé lóòótọ́ ni iṣẹ́ ìyanu tí wọ́n fi jí Lásárù dìde ṣẹlẹ̀? Bí Bíbélì ṣe sọ ìtàn náà fi hàn pé òótọ́ ni. Tó o bá ka ohun tó wà nínú Jòhánù 11:1-44, wàá rí kúlẹ̀kúlẹ̀ ìtàn náà níbẹ̀. Ǹjẹ́ o lè sọ pé àjíǹde náà kò wáyé? Tó o bá sọ bẹ́ẹ̀, ìyẹn lè mú kó o máa wò ó pé bóyá ni gbogbo iṣẹ́ ìyanu tí Bíbélì mẹ́nu kàn ṣẹlẹ̀, títí kan àjíǹde Jésù Kristi fúnra rẹ̀. Bíbélì sì sọ pé “bí a kò bá tíì gbé Kristi dìde, ìgbàgbọ́ yín jẹ́ aláìwúlò.” (1 Kọ́ríńtì 15:17) Àjíǹde jẹ́ ẹ̀kọ́ pàtàkì kan tí Ìwé Mímọ́ fi kọ́ni. (Hébérù 6:1, 2) Àmọ́, kí ni ọ̀rọ̀ náà “àjíǹde” túmọ̀ sí?
Kí Ni “Àjíǹde” Túmọ̀ Sí?
Ó lé ní ìgbà ogójì tí ọ̀rọ̀ náà “àjíǹde” fara hàn nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì. Òun ni wọ́n fi túmọ̀ ọ̀rọ̀ Gíríìkì kan tí ìtumọ̀ olówuuru rẹ̀ jẹ́ “dídìde dúró lẹ́ẹ̀kan sí i.” Ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò fún un ní èdè Hébérù túmọ̀ sí “mímú òkú sọjí.” Àmọ́, kí ni Ọlọ́run máa jí dìde? Kì í ṣe ara ẹni tó kú ló máa jí dìde torí pé ara yẹn á ti jẹrà á sì ti padà di erùpẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹni náà gan-an ló máa jí dìde. Nítorí náà, tá a bá sọ pé a jí ẹnì kan dìde, ó túmọ̀ sí pé a dá gbogbo ìṣarasíhùwà onítọ̀hún padà sára rẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìrántí àwọn nǹkan tó ṣe nígbà ayé rẹ̀, àti gbogbo ohun tó mú kó yàtọ̀ sí ẹlòmíì.
Kì í ṣe ìṣòro rárá fún Jèhófà Ọlọ́run láti rántí gbogbo ìṣarasíhùwà ẹnì kan àtàwọn nǹkan tó ṣe nígbà ayé rẹ̀ nítorí pé pípé ni agbára ìrántí Ọlọ́run. (Aísáyà 40:26) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Jèhófà ni Orísun ìwàláàyè, kì í ṣe ìṣòro fún un láti jí ẹni tó ti kú dìde pẹ̀lú ara tuntun. (Sáàmù 36:9) Yàtọ̀ síyẹn, Bíbélì fi yé wa pé Jèhófà Ọlọ́run “nífẹ̀ẹ́” láti jí àwọn òkú dìde. (Jóòbù 14:14, 15, Bibeli Yoruba Atọ́ka) Ayọ̀ ńlá gbáà ló jẹ́ pé kì í ṣe pé Jèhófà ní agbára láti jí òkú dìde nìkan, àmọ́ ó tún fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀!
Ipa kékeré kọ́ ni Jésù Kristi alára kó nínú ọ̀rọ̀ jíjí òkú dìde. Lẹ́yìn nǹkan bí ọdún kan ó lé díẹ̀ tí Jésù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ó sọ pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí Baba ti ń gbé àwọn òkú dìde, tí ó sì ń sọ wọ́n di ààyè, bẹ́ẹ̀ náà ni Ọmọ ń sọ àwọn tí ó bá fẹ́ di ààyè.” (Jòhánù 5:21) Ǹjẹ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Lásárù ò fi hàn kedere pé Jésù Kristi ní agbára láti jí òkú dìde àti pé ó fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀?
Ọ̀rọ̀ táwọn kan wá ń sọ pé nǹkan kan wà nínú èèyàn tó ṣì máa ń wà láàyè lẹ́yìn ikú ńkọ́ o? Ẹ̀kọ́ nípa àjíǹde àtohun táwọn kan máa ń sọ pé ọkàn kì í kú ta kora pátápátá. Tí nǹkan kan bá wà nínú èèyàn tó ṣì máa ń wà láàyè lẹ́yìn tẹ́nì kan bá kú, kí wá ni àjíǹde wà fún nígbà yẹn? Màtá àbúrò Lásárù ò gbà gbọ́ pé nígbà tí ẹ̀gbọ́n òun kú, ńṣe ló lọ sí ibùgbé àwọn ẹni ẹ̀mí. Màtá gbà gbọ́ pé àjíǹde wà. Nígbà tí Jésù fi í lọ́kàn balẹ̀ pé: “Arákùnrin rẹ yóò dìde,” Màtá wí fún un pé: “Mo mọ̀ pé yóò dìde nínú àjíǹde ní ọjọ́ ìkẹyìn.” (Jòhánù 11:23, 24) Lẹ́yìn tí Jésù sì jí Lásárù dìde, Lásárù ò sọ pé òun lọ síbì kankan. Òkú ni ní gbogbo ìgbà yẹn. Bíbélì sì sọ pé: “Ní ti àwọn òkú, wọn kò mọ nǹkan kan rárá, . . . kò sí iṣẹ́ tàbí ìhùmọ̀ tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n ní Ṣìọ́ọ̀lù [ipò òkú], ibi tí ìwọ ń lọ.”—Oníwàásù 9:5, 10.
Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ, àjíǹde nìkan ṣoṣo ló lè fòpin sí ikú. Àmọ́ nínú gbogbo àìmọye èèyàn tó ti kú, àwọn wo ló máa jíǹde, ibo sì ni wọ́n máa jí dìde sí?
Àwọn Wo Ló Máa Jíǹde?
Jésù sọ pé: “Wákàtí náà ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn [Jésù], wọn yóò sì jáde wá.” (Jòhánù 5:28, 29) Gẹ́gẹ́ bí ìlérí tí Jésù ṣe yìí ti fi hàn, àwọn tí wọ́n wà ní ibojì ìrántí, ìyẹn àwọn tí wọ́n wà nínú ìrántí Jèhófà ló máa jí dìde. Ìbéèrè tó wá jẹ yọ nígbà náà ni pé, Nínú gbogbo àwọn tó ti kú, àwọn wo gan-an ni wọ́n wà nínú ìrántí Ọlọ́run tó máa jí dìde?
Ìwé Hébérù orí kọkànlá mẹ́nu kan àwọn ọkùnrin àtobìnrin tí wọ́n fi ìṣòtítọ́ sin Ọlọ́run. Àwọn wọ̀nyí àtàwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n kú ní àkókò tiwa yìí wà lára àwọn tó máa jíǹde. Àwọn tí kò tẹ̀ lé ìlànà òdodo Ọlọ́run ńkọ́, bóyá torí pé wọn ò ní ìmọ̀ kankan nípa rẹ̀? Ṣé Ọlọ́run máa rántí àwọn náà? Bẹ́ẹ̀ ni o, púpọ̀ lára wọn ni Ọlọ́run máa rántí, nítorí Bíbélì ṣèlérí pé: “Àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.”—Ìṣe 24:15.
Àmọ́, kì í ṣe gbogbo àwọn tí wọ́n ti kú ni yóò jíǹde o. Bíbélì sọ pé: “Bí a bá mọ̀ọ́mọ̀ sọ ẹ̀ṣẹ̀ dídá dàṣà lẹ́yìn rírí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́ gbà, kò tún sí ẹbọ kankan tí ó ṣẹ́ kù fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́, bí kò ṣe ìfojúsọ́nà fún ìdájọ́ akúnfẹ́rù.” (Hébérù 10:26, 27) Àwọn kan wà tó ti dá ẹ̀ṣẹ̀ tí kò ní ìdáríjì. Gẹ̀hẹ́nà, ìyẹn ibi tó ṣàpẹẹrẹ ìparun pátápátá, làwọn yẹn wà kì í ṣe Hédíìsì (ipò òkú). (Mátíù 23:33) Ṣùgbọ́n a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra ká má lọ máa sọ pé ẹni tibí ló máa jíǹde tọ̀hún ò ní jíǹde. Ọlọ́run ni onídàájọ́. Ó mọ ẹni tó wà ní Hédíìsì àtẹni tó wà ní Gẹ̀hẹ́nà. Ohun tó kàn wá kò ju pé ká gbé ìgbésí ayé wa lọ́nà tí Ọlọ́run fẹ́.
Àwọn Wo Ló Máa Jí Dìde sí Ọ̀run?
Nínú gbogbo àjíǹde tó ṣáájú ti Jésù Kristi, tiẹ̀ ló pabanbarì jù. Ìdí ni pé wọ́n ‘fi ikú pa á nínú ẹran ara, ṣùgbọ́n a sọ ọ́ di ààyè nínú ẹ̀mí.’ (1 Pétérù 3:18) Kò sí ẹ̀dá èèyàn kankan tá a tíì jí dìde lọ́nà yẹn ṣáájú rẹ̀. Jésù alára sọ pé: “Kò sí ènìyàn kankan tí ó ti gòkè re ọ̀run bí kò ṣe ẹni tí ó sọ kalẹ̀ láti ọ̀run, Ọmọ ènìyàn.” (Jòhánù 3:13) Jésù, Ọmọ ènìyàn, lẹni àkọ́kọ́ tí Ọlọ́run jí dìde gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí. (Ìṣe 26:23) Lẹ́yìn tirẹ̀, àwọn míì sì tún wà tí Ọlọ́run máa jí dìde lọ́nà yẹn. Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Olúkúlùkù ní ẹgbẹ́ tirẹ̀: Kristi àkọ́so, lẹ́yìn náà àwọn tí ó jẹ́ ti Kristi nígbà wíwàníhìn-ín rẹ̀.”—1 Kọ́ríńtì 15:23.
Ọlọ́run yóò jí ìwọ̀nba èèyàn kéréje kan, ìyẹn “àwọn tí ó jẹ́ ti Kristi,” dìde sí ọ̀run nítorí ìdí pàtàkì kan. (Róòmù 6:5) Wọn yóò lọ máa bá Kristi ṣèjọba gẹ́gẹ́ bí “ọba lé ilẹ̀ ayé lórí.” (Ìṣípayá 5:9, 10) Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n á tún sìn gẹ́gẹ́ bí àlùfáà ní ti pé wọ́n á dara pọ̀ pẹ̀lú Kristi láti mú gbogbo àtúbọ̀tán ẹ̀ṣẹ̀ tí ìran èèyàn jogún látọ̀dọ̀ Ádámù, ọkùnrin àkọ́kọ́, kúrò. (Róòmù 5:12) Gbogbo àwọn ọba àti àlùfáà tó máa bá Kristi ṣèjọba yìí jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì. (Ìṣípayá 14:1, 3) Irú ara wo ni wọ́n máa ní nígbà tí wọ́n bá jíǹde? Bíbélì sọ pé “ara ti ẹ̀mí” ni. Òun ló máa jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wọn láti lọ máa gbé lọ́run.—1 Kọ́ríńtì 15:35, 38, 42-45.
Ìgbà wo làwọn wọ̀nyí bẹ̀rẹ̀ sí jí dìde sí ọ̀run? Kọ́ríńtì kìíní orí kẹẹ̀ẹ́dógún ẹsẹ kẹtàlélógún sọ pé “nígbà wíwàníhìn-ín [Kristi]” ni. Àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ láyé láti ọdún 1914 fi hàn kedere pé ọdún yẹn gan-an ni ìgbà wíwàníhìn-ín Kristi àti “ìparí ètò àwọn nǹkan” bẹ̀rẹ̀. (Mátíù 24:3-7) Torí náà, a lè sọ pé àwọn Kristẹni olóòótọ́ ti bẹ̀rẹ̀ sí jí dìde sí ọ̀run, bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò lè fojú rí wọn. Èyí túmọ̀ sí pé àwọn àpọ́sítélì àtàwọn Kristẹni ìjímìjí ti jí dìde sí ọ̀run báyìí. Àmọ́, àwọn Kristẹni tó ṣì wà láyé lónìí tí Ọlọ́run fún ní ìrètí tó dájú pé wọn yóò lọ bá Kristi jọba lọ́run ńkọ́? Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ tí wọ́n bá kú la óò jí wọn dìde, àní “ní ìpajúpẹ́.” (1 Kọ́ríńtì 15:52) Níwọ̀n bí àjíǹde àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì ti ṣáájú tàwọn tó máa jíǹde sórí ilẹ̀ ayé, Bíbélì pe àjíǹde àwọn kéréje yẹn ní “àjíǹde àkọ́kọ́” àti “àjíǹde èkíní.”—Fílípì 3:11; Ìṣípayá 20:6.
Àwọn Wo Ló Máa Jíǹde Sórí Ilẹ̀ Ayé?
Ìwé Mímọ́ fi yéni pé èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn tó ti kú la óò jí dìde sórí ilẹ̀ ayé. (Sáàmù 37:29; Mátíù 6:10) Nígbà tí àpọ́sítélì Jòhánù ń ṣàpèjúwe ìran àgbàyanu tó rí nípa àwọn tá a jí dìde, ó kọ̀wé pé: “Òkun sì jọ̀wọ́ àwọn òkú tí ń bẹ nínú rẹ̀ lọ́wọ́, ikú àti Hédíìsì sì jọ̀wọ́ àwọn òkú tí ń bẹ nínú wọn lọ́wọ́, a sì ṣèdájọ́ wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ní ìbámu pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ wọn. A sì fi ikú àti Hédíìsì sọ̀kò sínú adágún iná. Èyí túmọ̀ sí ikú kejì, adágún iná náà.” (Ìṣípayá 20:11-14) Ọlọ́run máa rántí àwọn òkú tí wọ́n wà ní Hédíìsì tàbí Ṣìọ́ọ̀lù, ìyẹn ipò òkú. Gbogbo wọn pátá láìku ẹyọ kan ni Ọlọ́run máa jí dìde. (Sáàmù 16:10; Ìṣe 2:31) Lẹ́yìn tí wọ́n bá sì ti jíǹde, a óò ṣèdájọ́ olúkúlùkù wọn ní ìbámu pẹ̀lú iṣẹ́ ọwọ́ wọn. Kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ sí ikú àti Hédíìsì? A ó sọ wọ́n sínú “adágún iná.” Èyí túmọ̀ sí pé ikú tá a ti jogún lọ́dọ̀ Ádámù kò ní sí mọ́.
Ẹ wo bí ayọ̀ àwọn téèyàn wọn ti kú ti máa pọ̀ tó tí wọ́n bá gbọ́ nípa ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé òun máa jí àwọn òkú dìde! Inú opó Náínì yẹn ti ní láti dùn gan-an nígbà tí Jésù jí ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo tó kú dìde! (Lúùkù 7:11-17) Nígbà tí Bíbélì sì tún ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn òbí ọmọ ọdún méjìlá kan tí Jésù jí dìde, ó ní: “Ní kíá, wọn kò mọ ohun tí wọn ì bá ṣe, nítorí tí ayọ̀ náà pọ̀ jọjọ.” (Máàkù 5:21-24, 35-42; Lúùkù 8:40-42, 49-56) Ó dájú pé inú àwa náà yóò dùn gan-an láti padà rí àwọn èèyàn wa tí wọ́n ti kú nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí.
Ipa wo ni mímọ òkodoro òtítọ́ nípa àjíǹde lè ní lórí wa nísinsìnyí? Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia sọ pé: “Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń bẹ̀rù ikú, wọn ò sì fẹ́ máa ronú nípa rẹ̀ rárá.” Kí nìdí? Ìdí ni pé ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ló gbà pé ikú jẹ́ àdììtú, pé ó jẹ́ ohun téèyàn ò lóye àtohun téèyàn gbọ́dọ̀ máa bẹ̀rù. Tá a bá mọ ipò táwọn òkú wà lóòótọ́, tá a sì nígbàgbọ́ pé wọ́n máa jíǹde, a ò ní máa bẹ̀rù “ọ̀tá ìkẹyìn [náà], ikú” bí ọ̀ràn bá tiẹ̀ dójú ẹ̀ pàápàá. (1 Kọ́ríńtì 15:26) A ò sì ní bara jẹ́ ju bó ṣe yẹ lọ bí ọ̀rẹ́ wa tímọ́tímọ́ tàbí ìbátan wa bá kú.
Ìgbà wo ni Ọlọ́run yóò bẹ̀rẹ̀ sí jí àwọn èèyàn dìde sórí ilẹ̀ ayé? Ìwà ipá, gbọ́nmi-si omi-ò-to, ìpànìyàn àti ìbàyíkájẹ́ kúnnú ayé lónìí. Bí Ọlọ́run bá wá bẹ̀rẹ̀ sí jí àwọn tó ti kú dìde sí ayé báyìí, ó dájú pé ayọ̀ wọn kò ní tọ́jọ́. Àmọ́, Ẹlẹ́dàá ti ṣèlérí pé òun máa tó pa ayé ìsinsìnyí tí Sátánì ń darí run. (Òwe 2:21, 22; Dáníẹ́lì 2:44; 1 Jòhánù 5:19) Láìpẹ́ sí ìsinsìnyí, ayé yóò rí bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ kó rí gẹ́lẹ́ níbẹ̀rẹ̀. Nígbà náà, nínú ayé tuntun alálàáfíà tí Ọlọ́run fẹ́ mú wá, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn tó ti kú yóò tún padà wà láàyè.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Orí ilẹ̀ ayé ni èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn tó ti kú yóò jíǹde sí