Ẹ̀KỌ́ 13
Ìròyìn Ayọ̀ Wo Ló Wà Nípa Ìsìn?
1. Ṣé gbogbo ìsìn ló dára?
Àwọn èèyàn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ wà nínú gbogbo ìsìn. Ìròyìn ayọ̀ ló jẹ́ pé Ọlọ́run ń rí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ wọn sì jẹ ẹ́ lógún. Àmọ́, ó bani nínú jẹ́ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwà burúkú ni àwọn èèyàn ti hù lórúkọ ìsìn. (2 Kọ́ríńtì 4:3, 4; 11:13-15) Àwọn ìròyìn tó ń jáde fi hàn pé, àwọn ẹ̀sìn kan ń lọ́wọ́ nínú bí àwọn èèyàn ṣe ń fẹ̀mí ṣòfò, tí wọ́n ń pa ẹ̀yà run, tí wọ́n ń jagun, tí wọ́n sì ń hùwà àìdáa sí àwọn ọmọdé. Ẹ wo bí àwọn nǹkan yìí á ṣe máa kó ẹ̀dùn ọkàn bá àwọn olóòótọ́ tó nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run!—Ka Mátíù 24:3-5, 11, 12.
Ìsìn tòótọ́ ń fògo fún Ọlọ́run àmọ́ ẹ̀sìn èké kò mú inú Ọlọ́run dùn. Àwọn ohun tí kò sí nínú Bíbélì ni wọ́n ń kọ́ni, títí kan àwọn ẹ̀kọ́ tí kì í ṣe òótọ́ nípa Ọlọ́run àti ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn òkú. Àmọ́, Jèhófà fẹ́ kí àwọn èèyàn mọ òtítọ́ nípa òun.—Ka Ìsíkíẹ́lì 18:4; 1 Tímótì 2:3-5.
2. Ìròyìn ayọ̀ wo ló wà nípa ìsìn?
Ohun kan ni pé àwọn ẹ̀sìn èké tí wọ́n sọ pé àwọn nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àmọ́ tó jẹ́ pé ayé Sátánì ni wọ́n fẹ́ràn kò lè tan Ọlọ́run. (Jémíìsì 4:4) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pe gbogbo ẹ̀sìn èké ní “Bábílónì Ńlá.” Bábílónì ni orúkọ ìlú àtijọ́ tí ẹ̀sìn èké ti bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn Ìkún Omi ọjọ́ Nóà. Láìpẹ́, Ọlọ́run máa mú ìparun òjijì bá àwọn ẹ̀sìn tó ń tan àwọn èèyàn jẹ, tí wọ́n sì ń ni àwọn èèyàn lára.—Ka Ìfihàn 17:1, 2, 5, 16, 17; 18:8.
Ìròyìn ayọ̀ náà kò tíì tán. Jèhófà ò gbàgbé àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ tí wọ́n wà nínú àwọn ẹ̀sìn èké káàkiri ayé. Ọlọ́run ti ń kó wọn jọ sí ojú kan ní ti pé ó ń kọ́ wọn ní òtítọ́.—Ka Míkà 4:2, 5.
3. Kí ló yẹ kí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ ṣe?
Ìsìn tòótọ́ ń mú kí àwọn èèyàn wà níṣọ̀kan
Ọ̀rọ̀ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ àti ohun tó dára jẹ Jèhófà lógún. Ó rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n kúrò nínú ẹ̀sìn èké. Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run máa ń fẹ́ ṣàtúnṣe kí wọ́n lè mú inú Ọlọ́run dùn.—Ka Ìfihàn 18:4.
Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, nígbà tí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ gbọ́ ìròyìn ayọ̀ látẹnu àwọn àpọ́sítélì, inú wọn dùn gan-an. Wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ nípa ọ̀nà ìgbésí ayé tuntun látọ̀dọ̀ Jèhófà, ìgbésí ayé tó ń múnú ẹni dùn, tó nítumọ̀ tó sì ń mú kéèyàn nírètí. Àpẹẹrẹ rere ni wọ́n jẹ́ fún wa lónìí, torí pé wọ́n fi hàn pé àwọn mọyì ìròyìn ayọ̀ náà bí wọ́n ṣe fi Jèhófà ṣe ẹni àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé wọn.—Ka 1 Tẹsalóníkà 1:8, 9; 2:13.
Jèhófà ń tẹ́wọ́ gba àwọn tó bá jáde kúrò nínú ẹ̀sìn èké kí wọ́n lè dara pọ̀ mọ́ àwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀, tí wọ́n dà bí ìdílé rẹ̀. Tó o bá wá sọ́dọ̀ Jèhófà, wàá di ọ̀rẹ́ rẹ̀, wàá di ara ìdílé tí ìfẹ́ wà láàárín wọn, ìyẹn àwọn tẹ́ ẹ jọ ń sin Jèhófà, wàá sì ní ìyè àìnípẹ̀kun.—Ka Máàkù 10:29, 30; 2 Kọ́ríńtì 6:17, 18.
4. Báwo ni Ọlọ́run ṣe máa mú kí gbogbo ayé láyọ̀?
Ìròyìn ayọ̀ ló jẹ́ pé Ọlọ́run máa pa ẹ̀sìn èké run. Kárí ayé ni àwọn èèyàn ti máa bọ́ lọ́wọ́ ìnira. Ẹ̀sìn èké kò ní ṣi àwọn èèyàn lọ́nà mọ́, kò sì ní pín aráyé níyà. Gbogbo èèyàn tó wà láyé á máa sin Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà.—Ka Ìfihàn 18:20, 21; 21:3, 4.