ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • yc ẹ̀kọ́ 5 ojú ìwé 12-13
  • Sámúẹ́lì Ń Bá A Lọ Láti Máa Ṣe Ohun tí Ó Dára

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Sámúẹ́lì Ń Bá A Lọ Láti Máa Ṣe Ohun tí Ó Dára
  • Kọ́ Ọmọ Rẹ
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Sámúẹ́lì Tẹra Mọ́ Ṣíṣe Ohun Tí Ó Tọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ọmọkùnrin Kékeré Kan Sin Ọlọ́run
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • Ó “Ń Bá A Lọ ní Dídàgbà Lọ́dọ̀ Jèhófà”
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
  • Ó “Ń Bá A Lọ Ní Dídàgbà Lọ́dọ̀ Jèhófà”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
Àwọn Míì
Kọ́ Ọmọ Rẹ
yc ẹ̀kọ́ 5 ojú ìwé 12-13

Ẹ̀kọ́ 5

Sámúẹ́lì Ń Báa Lọ Láti Máa Ṣe Ohun Tí Ó Dára

Inú àgọ́ ìjọsìn tí àwọn èèyàn ti máa ń wá jọ́sìn Jèhófà ni Sámúẹ́lì wà láti kékeré. Ó ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀, ó sì ń gbé níbẹ̀. Ǹjẹ́ o mọ bí Sámúẹ́lì ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í gbé inú àgọ́ ìjọsìn? Ó dáa, jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa Hánà tó jẹ́ ìyá Sámúẹ́lì.

Ó ti pẹ́ gan-an tí Hánà tí ń wá ọmọ, àmọ́ kò bímọ. Ló bá gbàdúrà sí Jèhófà, ó sì bẹ̀ ẹ́ pé kó ran òun lọ́wọ́. Ó tún ṣèlérí pé tí òun bá bí ọkùnrin, òun máa mú un wá sí àgọ́ ìjọsìn kó máa ṣiṣẹ́ níbẹ̀, kó sì máa gbé ibẹ̀. Jèhófà dáhùn àdúrà Hánà, ó bí ọmọkùnrin. Ó sì sọ orúkọ ọmọ náà ní Sámúẹ́lì. Hánà mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, nígbà tí Sámúẹ́lì pé ọmọ ọdún mẹ́ta tàbí mẹ́rin, ó mú un lọ sí àgọ́ ìjọsìn kó lè máa sin Ọlọ́run níbẹ̀.

Élì ni àlùfáà àgbà ní àgọ́ ìjọsìn. Àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ méjèèjì náà ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀. Rántí pé, inú ilé tí àwọn èèyàn ti ń jọ́sìn Ọlọ́run ni àgọ́ ìjọsìn, ohun tó dáa ló sì yẹ káwọn èèyàn máa ṣe níbẹ̀. Àmọ́ nǹkan burúkú ni àwọn ọmọ Élì ń ṣe níbẹ̀. Gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe ni Sámúẹ́lì ń rí. Ǹjẹ́ Sámúẹ́lì ṣe àwọn nǹkan burúkú tí àwọn ọmọkùnrin Élì ń ṣe?— Rárá o, ó ń báa lọ láti má ṣe ohun tí ó tọ́, bí àwọn òbí rẹ̀ ṣe sọ pé kó máa ṣe.

Kí lo rò pé ó yẹ kí Élì ṣe fún àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ méjèèjì?— Ó yẹ kó bá wọn wí, kó sì lé wọn kúrò nínú ilé Ọlọ́run. Àmọ́, Élì ò ṣe bẹ́ẹ̀, ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi bínú sí òun àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ méjèèjì. Jèhófà sì fìyà jẹ wọ́n.

Sámúẹ́lì tó jẹ́ ọmọdé ń bá Élì tó jẹ́ Àlùfáà Àgbà sọ̀rọ̀

Sámúẹ́lì jẹ́ iṣẹ́ tí Jèhófà rán an fún Élì

Lóru ọjọ́ kan nígbà tí Sámúẹ́lì ń sùn, ó gbọ́ tí ẹnì kan pe orúkọ rẹ̀: ‘Sámúẹ́lì!’ Ló bá sáré lọ bá Élì, àmọ́ Élì sọ fún un pé: ‘Mi ò pè ẹ́.’ Èyí ṣẹlẹ̀ lẹ́ẹ̀mejì. Nígbà tó di ẹlẹ́ẹ̀kẹta, Élì sọ fún Sámúẹ́lì pé tó bá tún ti gbọ́ orúkọ rẹ̀, kó sọ pé: ‘Sọ̀rọ̀ Jèhófà, mo ń fetí sílẹ̀.’ Sámúẹ́lì sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Élì ti sọ fún un. Jèhófà wá sọ fún Sámúẹ́lì pé: ‘Sọ fún Élì pé mo máa fìyà jẹ ìdílé rẹ̀ nítorí gbogbo nǹkan burúkú tí wọ́n ti ṣe.’ Ǹjẹ́ o rò pé ó rọrùn fún Sámúẹ́lì láti jẹ́ iṣẹ́ yìí fún Élì?— Rárá, kò rọrùn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀rù ba Sámúẹ́lì, ó ṣe ohun tí Jèhófà sọ pé kó ṣe. Ohun tí Jèhófà sọ sì ṣẹlẹ̀. Níkẹyìn wọ́n pa àwọn ọmọkùnrin Élì méjèèjì, Élì náà sì kú.

Àpẹẹrẹ tó dáa ni Sámúẹ́lì jẹ́ fún wa. Ó ṣe ohun tó dára lójú Jèhófà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó rí nǹkan burúkú tí àwọn míì ń ṣe. Ìwọ ńkọ́? Ṣé wàá ṣe bíi ti Sámúẹ́lì, tí wàá sì máa báa nìṣó láti máa ṣe ohun tí ó dára? Tí o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá máa mú inú Jèhófà àti inú àwọn òbí rẹ dùn.

KÀ Á NÍNÚ BÍBÉLÌ RẸ

  • 1 Sámúẹ́lì 2:22-26; 3:1-21

ÌBÉÈRÈ:

  • Ìlérí wo ni ìyá Sámúẹ́lì ṣe?

  • Kí ni Sámúẹ́lì rí tí àwọn ọmọkùnrin Élì ń ṣẹ nínú àgọ́ ìjọsìn?

  • Kí ni Jèhófà sọ pé kí Sámúẹ́lì ṣe?

  • Kí nìdí tí Sámúẹ́lì fi jẹ́ àpẹẹrẹ tó dáa fún wa lónìí?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́