ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w08 8/1 ojú ìwé 24-25
  • Sámúẹ́lì Tẹra Mọ́ Ṣíṣe Ohun Tí Ó Tọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Sámúẹ́lì Tẹra Mọ́ Ṣíṣe Ohun Tí Ó Tọ́
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Sámúẹ́lì Ń Bá A Lọ Láti Máa Ṣe Ohun tí Ó Dára
    Kọ́ Ọmọ Rẹ
  • Ọmọkùnrin Kékeré Kan Sin Ọlọ́run
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • Ó “Ń Bá A Lọ ní Dídàgbà Lọ́dọ̀ Jèhófà”
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
  • Ó “Ń Bá A Lọ Ní Dídàgbà Lọ́dọ̀ Jèhófà”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
w08 8/1 ojú ìwé 24-25

Kọ́ Ọmọ Rẹ

Sámúẹ́lì Tẹra Mọ́ Ṣíṣe Ohun Tí Ó Tọ́

ǸJẸ́ o ti rí i táwọn èèyàn ń ṣe ohun tó burú?—a Sámúẹ́lì ti rí i. Ibi tí Sámúẹ́lì ń gbé téèyàn ò lè rò rárá pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ti lè ṣẹlẹ̀ ló ti rí i. Àgọ́ ìjọsìn Ọlọ́run tá a tún ń pè ní ibi ìjọsìn, nílùú Ṣílò ni ibi tá à ń sọ yìí. Ẹ jẹ́ ká wo bí àgọ́ ìjọsìn náà ṣe di ibi tí Sámúẹ́lì ń gbé, ní ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ọdún sẹ́yìn.

Kí wọ́n tó bí Sámúẹ́lì, Hánà ìyá rẹ̀ ń wá ọmọ lójú méjèèjì. Nígbà kan tí Hánà lọ sí àgọ́ ìjọsìn, ó gbàdúrà sí Ọlọ́run nípa ọ̀rọ̀ náà. Ó ń gbàdúrà kíkankíkan tí ẹnú rẹ̀ fi ń gbọ̀n pẹ̀pẹ̀. Èyí mú kí Élì tó jẹ́ àlùfáà àgbà rò pé Hánà ti mutí yó. Àmọ́, nígbà tó wá rí i pé ìbànújẹ́ ọkàn ló bá Hánà, Élì gbàdúrà fún un pé: “Kí Ọlọ́run Ísírẹ́lì sì yọ̀ǹda ìtọrọ tí o ṣe lọ́dọ̀ rẹ̀.”—1 Sámúẹ́lì 1:17.

Nígbà tó yá, Hánà bí Sámúẹ́lì, inú rẹ̀ sì dùn débi tó fi sọ fún ọkọ rẹ̀ Ẹlikénà pé: ‘Gbàrà tí a bá ti já ọmọdékùnrin náà lẹ́nu ọmú, èmi yóò mú un wá sí àgọ́ ìjọsìn, yóò sì máa sìn Ọlọ́run níbẹ̀.’ Ohun tí Hánà sì ṣe gan-an nìyẹn! Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọmọ ọdún mẹ́rin tàbí márùn-ún ni Sámúẹ́lì nígbà yẹn.

Élì ti darúgbó, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ méjì Hófínì àti Fíníhásì kò sì sin Jèhófà lọ́nà títọ́. Wọ́n tiẹ̀ tún máa ń bá àwọn obìnrin tó ń wá sí àgọ́ ìjọsìn lò pọ̀! Kí lo rò pé ó yẹ kí bàbá wọn ṣe?— Bẹ́ẹ̀ ni, ó yẹ kó ti bá wọn wí, kó má sì fàyè gbà wọ́n láti ṣe àwọn nǹkan burúkú yẹn.

Bí Sámúẹ́lì ṣe ń dàgbà ní àgọ́ ìjọsìn, ó ṣeé ṣe kó mọ ìwà burúkú táwọn ọmọ Élì ń hù níbẹ̀. Ǹjẹ́ Sámúẹ́lì tẹ̀ lé àpẹẹrẹ búburú wọn?— Rárá o. Ó tẹra mọ́ ṣíṣe ohun tó tọ́, bí àwọn òbí rẹ̀ ṣe kọ́ ọ. Ìyẹn tún jẹ́ ara ìdí tí Jèhófà fi bínú sí Élì. Àní Jèhófà rán wòlíì sí Élì láti sọ fún un nípa ìyà tó máa fi jẹ ìdílé Élì, ní pàtàkì àwọn ọmọkùnrin rẹ̀.—1 Sámúẹ́lì 2:22-36.

Sámúẹ́lì ń bá a lọ láti máa sin Ọlọ́run nínú àgọ́ ìjọsìn pẹ̀lú Élì. Lóru ọjọ́ kan nígbà tí Sámúẹ́lì ń sùn, ó gbọ́ tí ẹnì kan pe orúkọ rẹ̀. Nítorí náà, Sámúẹ́lì sáré lọ bá Élì, àmọ́ Élì sọ fún un pé òun kò pè é. Ẹni náà tún pè é. Wàyí o, nígbà tí ó gbọ́ ohùn náà lẹ́ẹ̀kẹta, Élì ní kí Sámúẹ́lì sọ pé: “Sọ̀rọ̀, Jèhófà, nítorí tí ìránṣẹ́ rẹ ń fetí sílẹ̀.” Nígbà tí Sámúẹ́lì sọ bẹ́ẹ̀, Jèhófà bá a sọ̀rọ̀. Ǹjẹ́ o mọ ohun tí Jèhófà sọ fún Sámúẹ́lì?—

Ọlọ́run sọ fún Sámúẹ́lì nípa ìyà tó ti sọ pé òun á fi jẹ ìdílé Élì. Láàárọ̀ ọjọ́ kejì ẹ̀rù ba Sámúẹ́lì láti sọ fún Élì nípa ohun tí Jèhófà wí. Ṣùgbọ́n Élì bẹ Sámúẹ́lì pé: “Jọ̀wọ́, má fi í pa mọ́ fún mi.” Níkẹyìn, Sámúẹ́lì sọ fún Élì nípa gbogbo ohun tí Jèhófà sọ pé Òun máa ṣe, gẹ́gẹ́ bí wòlíì Jèhófà ti sọ fún Élì tẹ́lẹ̀. Élì fèsì pé: “Kí [Jèhófà] ṣe ohun tí ó dára ní ojú rẹ̀.” Níkẹyìn wọ́n pa Hófínì àti Fíníhásì, Élì pẹ̀lú sì kú.—1 Sámúẹ́lì 3:1-18.

Láwọn ìgbà yẹn, “Sámúẹ́lì sì ń bá a lọ ní dídàgbà, Jèhófà fúnra rẹ̀ sì wà pẹ̀lú rẹ̀.” Nígbà yẹn, ó ṣeé ṣe kí Sámúẹ́lì má tíì pé ọmọ ogún ọdún, àsìkò yẹn sì ṣe pàtàkì nínú ìgbésí ayé ọ̀dọ́. Ǹjẹ́ o rò pé ó rọrùn fún Sámúẹ́lì láti máa ṣe ohun tó tọ́ nìṣó àní nígbà táwọn ẹlòmíràn kò ṣe é?— Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn fún Sámúẹ́lì, síbẹ̀ ó sin Jèhófà tòótọ́-tòótọ́ jálẹ̀ gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀.—1 Sámúẹ́lì 3:19-21.

Ìwọ ńkọ́? Ṣé wàá dà bí Sámúẹ́lì, bó o ti ń dàgbà? Ṣé wàá máa ṣe ohun tó tọ́ nìṣó? Ṣé wàá máa bá a nìṣó láti ṣègbọràn sí ẹ̀kọ́ Bíbélì àti sí ohun táwọn òbí rẹ fi kọ́ ọ? Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ yóò máa mú inú Jèhófà àtàwọn òbí rẹ dùn.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Tó o bá ń bá ọmọdé kàwé yìí, àmì yìí (—) tó wà lẹ́yìn àwọn ìbéèrè kan ń sọ fún ọ pé kó o dánú dúró kó o sì jẹ́ kí ọmọ náà dáhùn ìbéèrè náà.

Ìbéèrè:

○ Báwo ni Sámúẹ́lì ṣe dẹni tó ń sìn ní àgọ́ ìjọsìn Jèhófà?

○ Àwọn ìṣòro wo ló dojú kọ́ Sámúẹ́lì níbẹ̀?

○ Àpẹẹrẹ wo ni Sámúẹ́lì fi lélẹ̀ fáwọn ọ̀dọ́?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́