ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w08 8/1 ojú ìwé 18-23
  • Ṣé Ó Yẹ Kí Orúkọ Náà Jèhófà Wà Nínú Májẹ̀mú Tuntun?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Ó Yẹ Kí Orúkọ Náà Jèhófà Wà Nínú Májẹ̀mú Tuntun?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìṣòro Táwọn Atúmọ̀ Bíbélì Dojú Kọ
  • Báwo Làwọn Atúmọ̀ Bíbélì Ṣe Yanjú Ìṣòro Yìí?
  • Ẹ̀rí Méjì Tó Mú Kó Dáni Lójú
  • “Ké Pe Orúkọ Jèhófà”
  • A5 Orúkọ Ọlọ́run Nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • Orukọ Ọlọrun ati “Majẹmu Titun” Naa
    Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae
  • Ohun Tó Mú Kó Ṣòro Fáwọn Èèyàn Láti Mọ Orúkọ Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Róòmù 10:13—“Pe Orúkọ Oluwa”
    Àlàyé Àwọn Ẹsẹ Bíbélì
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
w08 8/1 ojú ìwé 18-23

Ṣé Ó Yẹ Kí Orúkọ Náà Jèhófà Wà Nínú Májẹ̀mú Tuntun?

ǸJẸ́ ó tiẹ̀ ṣe pàtàkì kí orúkọ Ọlọ́run wà nínú Bíbélì? Ó ṣe kedere pé Ọlọ́run fẹ́ ẹ bẹ́ẹ̀. Lẹ́tà mẹ́rin tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run lédè Hébérù fara hàn ní nǹkan bí ìgbà ẹgbẹ̀rún méje nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tí wọ́n kọ́kọ́ kọ, èyí tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń pè ní Májẹ̀mú Láéláé.a

Àwọn ọ̀mọ̀wé tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa Bíbélì gbà pé orúkọ tí Ọlọ́run ń jẹ́ gan-an wà nínú Májẹ̀mú Láéláé, ìyẹn Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Àmọ́ ṣá, ọ̀pọ̀ gbà pé kò sí nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì tí wọ́n kọ́kọ́ fọwọ́ kọ, èyí tí wọ́n ń pè ní Májẹ̀mú Tuntun.

Kí wá làwọn òǹkọ̀wé Bíbélì tó kọ àwọn ìwé inú Májẹ̀mú Tuntun ṣe láwọn ibi tí wọ́n ti fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Májẹ̀mú Láéláé, tí lẹ́tà mẹ́rin tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run lédè Hébérù sì wà nínú ibi tí wọ́n ti fa ọ̀rọ̀ yọ? Nínú ọ̀ràn báyìí, ọ̀pọ̀ atúmọ̀ Bíbélì máa ń fi ọ̀rọ̀ náà “Olúwa” rọ́pò orúkọ tí Ọlọ́run ń jẹ́ gan-an. Àmọ́ àwọn atúmọ̀ Bíbélì tó túmọ̀ Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ò bá wọn ṣe ohun tí ọ̀pọ̀ atúmọ̀ Bíbélì ń ṣe yìí. Wọ́n lo orúkọ náà, Jèhófà ní ìgbà òjìlénígba ó dín mẹ́ta [237] nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì tàbí Májẹ̀mú Tuntun.

Ìṣòro wo làwọn atúmọ̀ Bíbélì dojú kọ lórí ọ̀ràn bóyá kí wọ́n lo orúkọ Ọlọ́run nínú Májẹ̀mú Tuntun tàbí kí wọ́n má lò ó? Ǹjẹ́ ẹ̀rí tó ṣe gúnmọ́ wà tó fi yẹ kí wọ́n lo orúkọ Ọlọ́run nínú Májẹ̀mú Tuntun? Àǹfààní wo ni rírí tá a rí orúkọ Ọlọ́run nínú Bíbélì lè ṣe fún ọ?

Ìṣòro Táwọn Atúmọ̀ Bíbélì Dojú Kọ

Àwọn ìwé Májẹ̀mú Tuntun aláfọwọ́kọ tá à ń rí lónìí kì í ṣe èyí táwọn tó fọwọ́ kọ ọ́ níbẹ̀rẹ̀ kọ. Ọwọ́ lílò dun ìwé táwọn bíi Mátíù, Jòhánù, Pọ́ọ̀lù àtàwọn míì fọwọ́ ara wọn kọ, ìyẹn sì jẹ́ kí wọ́n tètè gbó. Àmọ́ kí wọ́n tó gbó, àwọn èèyàn ṣe ẹ̀dà ìwé wọ̀nyí, nígbà táwọn yẹn náà sì ń gbó lọ, àwọn míì tún ṣe àwọn ẹ̀dà míì sí i. Kò dín ní ọgọ́rùn-ún ọdún méjì lẹ́yìn tí àwọn tó kọ́kọ́ kọ Májẹ̀mú Tuntun parí ẹ̀ táwọn èèyàn ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe àdàkọ ọ̀pọ̀ lára ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ẹ̀dà aláfọwọ́kọ rẹ̀ tó wà lónìí. Ó dà bíi pé àwọn tí wọ́n ń ṣe ẹ̀dà àwọn ìwé aláfọwọ́kọ yìí nígbà yẹn fi àwọn ọ̀rọ̀ náà Kuʹri·os tàbí Kyʹri·os, tó túmọ̀ sí “Olúwa” lédè Gíríìkì, rọ́pò lẹ́tà mẹ́rin tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run. Ó sì lè jẹ́ pé ṣe làwọn náà dà á kọ látọ̀dọ̀ àwọn tó ti ṣe bẹ́ẹ̀ ṣáájú wọn.b

Bí atúmọ̀ Bíbélì kan bá ti mọ èyí, ó gbọ́dọ̀ wá wò ó bóyá ẹ̀rí tó lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ wà pé lẹ́tà mẹ́rin tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run wà nínú àwọn ìwé aláfọwọ́kọ lédè Gíríìkì tí wọ́n kọ́kọ́ kọ àbí kò sí nínú wọn. Ǹjẹ́ a rí ẹ̀rí èyí níbì kankan? Jẹ́ ká wo àwọn ẹ̀rí tó tẹ̀ lé e yìí:

◼ Jésù lo orúkọ Ọlọ́run nígbà tó ń fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Májẹ̀mú Láéláé àti nígbà tó ń kà á. (Diutarónómì 6:13, 16; 8:3; Sáàmù 110:1; Aísáyà 61:1, 2; Mátíù 4:4, 7, 10; 22:44; Lúùkù 4:16-21) Nígbà ayé Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, lẹ́tà mẹ́rin tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run wà nínú àwọn Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù èyí tí wọ́n sábàá máa ń pè ní Májẹ̀mú Láéláé, bẹ́ẹ̀ náà ló sì ṣe wà níbẹ̀ títí dòní. Àmọ́, fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún, àwọn ọ̀mọ̀wé rò pé lẹ́tà mẹ́rin tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run yìí kò sí nínú ìwé aláfọwọ́kọ ti Májẹ̀mú Láéláé tí wọ́n túmọ̀ sí èdè Gíríìkì, ìyẹn Greek Septuagint, bẹ́ẹ̀ sì ni kò sí nínú ìwé aláfọwọ́kọ ti Májẹ̀mú Tuntun. Àmọ́, ní nǹkan bí ogójì ọdún sí ọgọ́ta ọdún sẹ́yìn, àwọn ọ̀mọ̀wé ṣàwárí ohun àrà kan. Wọ́n rí àwọn ògbólógbòó àjákù ìwé aláfọwọ́kọ ti Májẹ̀mú Láéláé tí wọ́n túmọ̀ sí èdè Gíríìkì. Wọ́n ti kọ àwọn ìwé yìí látìgbà ayé Jésù. Orúkọ Ọlọ́run tí wọ́n fi àwọn lẹ́tà Hébérù kọ sì wà lára àwọn ìwé àjákù náà.

◼ Jésù lo orúkọ Ọlọ́run, ó sì jẹ́ káwọn èèyàn mọ orúkọ náà. (Jòhánù 17:6, 11, 12, 26) Jésù sọ láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n pé: “Mo wá ní orúkọ Baba mi.” Ó tún tẹnu mọ́ ọn pé “orúkọ Baba [òun]” ni òun fi ń ṣe àwọn iṣẹ́ tóun ń ṣe. Kódà, ìtumọ̀ orúkọ Jésù alára ni “Jèhófà Ni Ìgbàlà.”—Jòhánù 5:43; 10:25.

◼ Ìkékúrú orúkọ Ọlọ́run wà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì. Orúkọ Ọlọ́run wà lára gbólóhùn náà “Halelúyà,” gbólóhùn yìí sì wà nínú Ìṣípayá 19:1, 3, 4, 6. Gbólóhùn yìí ní tààràtà túmọ̀ sí “Ẹ yin Jáà!” Ìkékúrú orúkọ Jèhófà ni Jáà.

◼ Àwọn ìwé táwọn Júù kan kọ láyé àtijọ́ fi hàn pé àwọn Kristẹni tó jẹ́ Júù lo orúkọ Ọlọ́run nínú ìwé wọn. Ìwé àkópọ̀ òfin àtẹnudẹ́nu tó ń jẹ́ The Tosefta, tí wọ́n parí kíkọ rẹ̀ ní nǹkan bí ọdún 300 Sànmánì Kristẹni, sọ nípa ìwé àwọn Kristẹni kan tí wọ́n dáná sun lọ́jọ́ Sábáàtì, ó ní: “Ìwé àwọn Ajíhìnrere àti àwọn ìwé minim [tí wọ́n rò pé ó jẹ́ àwọn Kristẹni tó jẹ́ Júù] ni wọn ò yọ nínú iná. Ńṣe ni wọ́n jẹ́ kí iná jó wọn mọ́ ibi tí wọ́n wà, . . . àwọn ìwé náà àti Orúkọ Ọlọ́run tó wà nínú wọn.” Ìwé The Tosefta yìí tún tọ́ka sí ọ̀rọ̀ Rábì Yosé ará Gálílì kan, tó gbé láyé lẹ́yìn ọdún 100 Sànmánì Kristẹni, ó ní Rábì yẹn sọ pé láwọn ọjọ́ míì láàárín ọ̀sẹ̀, “ẹnì kan á gé ibi tí Orúkọ Ọlọ́run wà nínú [ìwé àwọn Kristẹni] kúrò, ẹni náà á sì fi í pamọ́, ìyókù ìwé náà á sì jóná.” Nítorí náà, ẹ̀rí tó dájú wà pé àwọn Júù tó gbé ayé láàárín ọdún 100 sí 200 Sànmánì Kristẹni gbà gbọ́ pé àwọn Kristẹni lo orúkọ Jèhófà nínú àwọn ìwé wọn.

Báwo Làwọn Atúmọ̀ Bíbélì Ṣe Yanjú Ìṣòro Yìí?

Ṣé àwọn tó túmọ̀ Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun nìkan ni atúmọ̀ Bíbélì tó dá orúkọ Ọlọ́run padà sáyè ẹ̀ nígbà tí wọ́n ń túmọ̀ Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì ni? Rárá o. Látàrí àwọn ẹ̀rí tá a ti sọ lókè yìí, ọ̀pọ̀ atúmọ̀ Bíbélì ló gbà pé ó yẹ káwọn dá orúkọ Ọlọ́run padà sáyè ẹ̀ nígbà tí wọ́n ń túmọ̀ Májẹ̀mú Tuntun.

Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ Bíbélì tó wà láwọn èdè tí wọ́n ń sọ nílẹ̀ Áfíríkà, Amẹ́ríkà, Éṣíà àti erékùṣù Pàsífíìkì ló lo orúkọ Ọlọ́run ní ọ̀pọ̀ ìgbà nínú Májẹ̀mú Tuntun. (Wo àtẹ tó wà lójú ìwé 21.) Ẹnu àìpẹ́ yìí ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í gbé díẹ̀ lára àwọn Bíbélì yìí jáde. Lára wọn ni Bíbélì Rotuman (tí wọ́n gbé jáde lọ́dún 1999), ó lo orúkọ náà Jihova nígbà mọ́kànléláàádọ́ta [51] ní ẹsẹ méjìdínláàádọ́ta [48] nínú Májẹ̀mú Tuntun. Òmíràn ni Bíbélì Batak-Toba (tí wọ́n gbé jáde lọ́dún 1989) láti orílẹ̀-èdè Indonesia, ó lo orúkọ náà Jahowa nígbà àádọ́fà [110] nínú Májẹ̀mú Tuntun. Orúkọ Ọlọ́run tún ti fara hàn nínú àwọn ìtúmọ̀ Bíbélì ní èdè Faransé, Jámánì àti Sípéènì. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀gbẹ́ni Pablo Besson túmọ̀ Májẹ̀mú Tuntun sí èdè Sípéènì ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn. Nínú Bíbélì tó túmọ̀, ó lo Jèhófà nínú Júúdà ẹsẹ ìkẹrìnlá, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́rùn-ún àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé tó fi hàn pé ó ṣeé ṣe kí wọ́n máa lo orúkọ Ọlọ́run.

Nísàlẹ̀ yìí, a to àpẹẹrẹ àwọn Bíbélì díẹ̀ lédè Gẹ̀ẹ́sì tí wọ́n lo orúkọ Ọlọ́run nínú Májẹ̀mú Tuntun:

A Literal Translation of the New Testament . . . From the Text of the Vatican Manuscript, látọwọ́ Herman Heinfetter (1863)

The Emphatic Diaglott, látọwọ́ Benjamin Wilson (1864)

The Epistles of Paul in Modern English, látọwọ́ George Barker Stevens (1898)

St. Paul’s Epistle to the Romans, látọwọ́ W. G. Rutherford (1900)

The Christian’s Bible—New Testament, látọwọ́ George N. LeFevre (1928)

The New Testament Letters, látọwọ́ J.W.C. Wand, Bíṣọ́ọ̀bù ìlú London (1946)

Láìpẹ́ yìí, Bíbélì èdè Gẹ̀ẹ́sì kan tó ń jẹ́ New Living Translation tó gbajúmọ̀ dáadáa, ẹ̀dà tọdún 2004 sọ ọ̀rọ̀ yìí nínú ọ̀rọ̀ ìṣáájú, lábẹ́ àkòrí tó sọ pé “Bá A Ṣe Túmọ̀ Àwọn Orúkọ Ọlọ́run,” ó ní: “Jálẹ̀ nínú Bíbélì yìí, bákan náà la ṣe túmọ̀ lẹ́tà mẹ́rin yìí (YHWH) tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run. A túmọ̀ rẹ̀ sí ‘OLÚWA.’ A kọ ọ́ pẹ̀lú lẹ́tà ńlá tí ìrísí rẹ̀ kéré. Bí ọ̀pọ̀ Bíbélì èdè Gẹ̀ẹ́sì sì ṣe kọ ọ́ nìyẹn. Èyí á lè jẹ́ ká fìyàtọ̀ sí orúkọ náà ʹadonai, tá a túmọ̀ sí ‘Olúwa.’” Nígbà tó sì ń sọ̀rọ̀ lórí Májẹ̀mú Tuntun, ó ní: “Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà kurios la túmọ̀ sí ‘Olúwa’ látòkèdélẹ̀, àyàfi ìgbà tó bá jẹ́ pé Májẹ̀mú Tuntun fa ọ̀rọ̀ yọ ní tààràtà látinú Májẹ̀mú Láéláé, tó sì jẹ́ pé lẹ́tà ńlá tá a kọ ní ìrísí kékeré ni wọ́n fi kọ ọ́. Nírú ipò bẹ́ẹ̀ a túmọ̀ rẹ̀ sí ‘OLÚWA.’” (Àwa la fi lẹ́tà tó dagun kọ ọ́.) Àwọn tó túmọ̀ Bíbélì yìí tipa báyìí gbà pé ó yẹ káwọn lo lẹ́tà mẹ́rin yìí, YHWH, tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run láwọn ibi tí Májẹ̀mú Tuntun ti fa ọ̀rọ̀ yọ wọ̀nyẹn.

Ó dùn mọ́ni pé ìwé atúmọ̀ Bíbélì kan tí wọ́n pè ní The Anchor Bible Dictionary sọ lábẹ́ àkòrí náà, “Lẹ́tà Mẹ́rin Tó Dúró fún Orúkọ Ọlọ́run Nínú Májẹ̀mú Tuntun,” ó ní: “Ẹ̀rí wà tó fi hàn pé lẹ́tà mẹ́rin tó dúró fún Orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Yáwè, fara hàn nínú díẹ̀ tàbí nínú gbogbo ọ̀rọ̀ tí Májẹ̀mú Tuntun fà yọ látinú Májẹ̀mú Láéláé nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ kọ Májẹ̀mú Tuntun sílẹ̀.” Ọ̀mọ̀wé George Howard sì sọ pé: “Níwọ̀n bí wọ́n ti lo lẹ́tà mẹ́rin tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run nínú àwọn ẹ̀dà Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tí wọ́n túmọ̀ sí èdè Gíríìkì, tó sì jẹ́ pé àwọn ẹ̀dà yìí ló para pọ̀ di Ìwé Mímọ́ tí wọ́n ń lò láwọn ṣọ́ọ̀ṣì ayé àtijọ́, ó bọ́gbọ́n mu láti gbà pé àwọn tó kọ Májẹ̀mú Tuntun lo lẹ́tà mẹ́rin tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run nínú Bíbélì nígbà tí wọ́n ń fa ọ̀rọ̀ inú Májẹ̀mú Láéláé yọ.”

Ẹ̀rí Méjì Tó Mú Kó Dáni Lójú

Ó wá hàn gbangba báyìí pé kì í ṣe Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ni Bíbélì àkọ́kọ́ tó máa lo orúkọ Ọlọ́run nínú Májẹ̀mú Tuntun. Ńṣe ni àwọn ìgbìmọ̀ atúmọ̀ Bíbélì tó túmọ̀ Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun dà bí adájọ́ kan tí wọ́n ní kó wá dá ẹjọ́ kan, tí kò sì sí ẹlẹ́rìí kankan tí ọ̀ràn náà ṣojú ẹ̀ mọ́ láyé. Wọ́n fìṣọ́ra ṣàyẹ̀wò gbogbo ẹ̀rí tí wọ́n rí. Látàrí àwọn ẹ̀rí tí wọ́n rí, wọ́n pinnu láti lo orúkọ Jèhófà nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì. Jẹ́ ká wo ẹ̀rí méjì tó dájú tó mú kí wọ́n ṣe ohun tí wọ́n ṣe yìí.

(1) Àwọn atúmọ̀ Bíbélì yìí gbà pé níwọ̀n bí Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ti ní ìmísí Ọlọ́run, tó sì jẹ́ àfikún sí Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, ó dà bíi pé bí orúkọ Jèhófà ṣe dédé dàwátì nínú rẹ̀ fi hàn pé nǹkan míì ti wọ̀ ọ́.

Kí nìdí tí èrò yìí fi bọ́gbọ́n mu? Ní nǹkan bí ọdún 49 Sànmánì Kristẹni, Jákọ́bù ọmọ ẹ̀yìn Jésù sọ fáwọn alàgbà tó wà ní Jerúsálẹ́mù pé: “Símíónì ti ṣèròyìn ní kínníkínní bí Ọlọ́run ti yí àfiyèsí rẹ̀ sí àwọn orílẹ̀-èdè fún ìgbà àkọ́kọ́ láti mú àwọn ènìyàn kan fún orúkọ rẹ̀ jáde láti inú wọn.” (Ìṣe 15:14) Ǹjẹ́ ẹ rò pé ó bọ́gbọ́n mu láti gbà pé Jákọ́bù sọ irú ọ̀rọ̀ yìí ká ní kò sẹ́nì kankan ní ọ̀rúndún kìíní tó mọ orúkọ Ọlọ́run tàbí tó ń lò ó?

(2) Nígbà tí wọ́n rí àwọn ẹ̀dà Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tí wọ́n túmọ̀ sí èdè Gíríìkì tó lo orúkọ Ọlọ́run dípò kó lo Kyʹri·os (Olúwa), ó hàn gbangba sáwọn atúmọ̀ Bíbélì yìí pé orúkọ Ọlọ́run wà nínú àwọn ẹ̀dà Ìwé Mímọ́ ti àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ tó wà nígbà ayé Jésù, yálà èyí tó wà ní èdè Gíríìkì ni o tàbí èdè Hébérù.

Ó dà bí ẹni pé lẹ́yìn ìgbà ayé Jésù ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ àṣà tí kò bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run yẹn, pé kí wọ́n máa yọ orúkọ Ọlọ́run kúrò nínú àwọn Bíbélì lédè Gíríìkì tí wọ́n fọwọ́ kọ. Àbí, kí lèrò tìẹ? Ṣé o rò pé Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ á lọ́wọ́ nínú irú àṣà bẹ́ẹ̀?—Mátíù 15:6-9.

“Ké Pe Orúkọ Jèhófà”

Kódà, Ìwé Mímọ́ alára pèsè ẹ̀rí tó dájú pé àwọn Kristẹni ìgbàanì lo orúkọ Jèhófà dáadáa nínú àwọn ìwé tí wọ́n kọ, pàápàá jù lọ nígbà tí wọ́n bá fa àwọn àyọkà kan yọ látinú Májẹ̀mú Láéláé, tí orúkọ náà sì wà níbẹ̀. Nítorí náà, ó ṣe kedere pé Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ní ìdí tó lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ láti dá orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà padà sáyè rẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì.

Àǹfààní wo làwọn ohun tá a ti jíròrò yìí lè ṣe fún ọ? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù láti fi rán àwọn Kristẹni tó wà ní Róòmù létí pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń ké pe orúkọ Jèhófà ni a ó gbà là.” Ó wá béèrè pé: “Báwo ni wọn yóò ṣe ké pe ẹni tí wọn kò ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀? Báwo, ẹ̀wẹ̀, ni wọn yóò ṣe ní ìgbàgbọ́ nínú ẹni tí wọn kò gbọ́ nípa rẹ̀?” (Róòmù 10:13, 14; Jóẹ́lì 2:32) Àwọn Bíbélì tó bá lo orúkọ Ọlọ́run níbi tó ti yẹ yóò jẹ́ kó o lè sún mọ́ Ọlọ́run. (Jákọ́bù 4:8) Lóòótọ́, iyì ńlá ló jẹ́ fún wa pé a láǹfààní láti mọ orúkọ tí Ọlọ́run ń jẹ́ gan-an, ìyẹn Jèhófà, tá a sì tún lè ké pè é.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Lẹ́tà mẹ́rin tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run lédè Hébérù rèé: YHWH. Wọ́n sábà máa ń túmọ̀ rẹ̀ sí Jèhófà tàbí Yáwè lédè Yorùbá.

b Tó o bá ń fẹ́ aláyè síwájú sí i nípa ìdí tí wọ́n fi fi ọ̀rọ̀ náà “Olúwa” rọ́pò orúkọ Ọlọ́run, wo ìwé náà Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae, ojú ìwé 23 sí 27. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 21]

A Rí Orúkọ Ọlọ́run Nínú Májẹ̀mú Tuntun Nínú Àwọn Bíbélì Tó Wà Láwọn Èdè Mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún Yìí

CHIHOWA: Choctaw

IÁHVE: Portuguese

IEHOUA: Mer

IEHOVA: Gilbertese; Hawaiian; Hiri Motu; Kerewo; Kiwai; Marquesas; Panaieti (Misima); Rarotongan; Tahitian; Toaripi

IEHOVAN: Saibai

IEOVA: Kuanua; Wedau

IHOVA: Aneityum

IHVH: Faransé

IOVA: Malekula (Kuliviu); Malekula (Pangkumu) Malekula (Uripiv)

JAHOWA: Batak-Toba

JAHUÈ: Chacobo

JAKWE: (Ki)Sukuma

JAHVE: Hungarian

JEHOBA: Kipsigis; Mentawai

JEHOFA: Tswana

JEHOVA: Croatian; German; Kélé (Gabon); Manus Island; Nandi; Nauruan; Nukuoro

JEHOVÁ: Spanish

JEHÔVA: Fang; Tsimihety

JEHOVAH: Dutch; Ẹ́fíìkì; Gẹ̀ẹ́sì; Kalenjin; Malagasy; Narrinyeri; Ojibwa

JEOVA: Kusaie (Kosraean)

JIHOVA: Naga (Angami); Naga (Konyak); Naga (Lotha); Naga (Mao); Naga (Ntenyi); Naga (Sangtam); Rotuman

JIOUA: Mortlock

JIOVA: Fijian

JIWHEYẸWHE: Gu (Alada)

SIHOVA: Tongan

UYEHOVA: Súlú

YAHOWA: Thai

YAHVE: Ila

YAVE: Kongo

YAWE: Bobangi; Bolia; Dholuo; Lingala; Mongo (Lolo); (Lo)Ngandu; (Lo)Ntumba; (Ke)Sengele

YEHÓA: Awabakal

YEHOFA: Southern Sotho

YEHOVA: Chokwe; Chuana (Tlapi); (Ki)Kalanga; Logo; Luba; Lugbara; (Chi)Luimbi; (Chi)Lunda (Ndembu); (Chi)Luvale; Santo (Hog Harbor); Tífí; Umbundu; (Isi)Xhosa

YEHOVAH: Bube; Mohawk; Nguna (Efate); Nguna (Tongoa)

YEHOWA: Ga; Laotian; (Ki)Songe; Tshiluba

YEKOVA: Zande

YEOBA: Kuba (Inkongo)

YEOHOWA: Korean

YHWH: Hébérù

YOWO: Lomwe

ZAHOVA: Chin (Haka-Lai)

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

ATÚMỌ̀ BÍBÉLÌ KAN TÓ BỌ̀WỌ̀ FÚN ORÚKỌ ỌLỌ́RUN

Ní oṣù November ọdún 1857, míṣọ́nnárì kan tó ń jẹ́ Hiram Bingham II àti ìyàwó rẹ̀ dé sí Erékùṣù Gilbert (tó ti di Kiribati báyìí), ọmọ ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ni nígbà yẹn. Ení-tere, èjì-tere làwọn ọmọ Ilé Ẹ̀kọ́ Ọjọ́ Ìsinmi Ilẹ̀ Amẹ́ríkà dáwó ọkọ̀ ojú omi àwọn míṣọ́nnárì tó gbé wọn. Àwọn tó ṣonígbọ̀wọ́ ìrìn àjò náà sọ ọkọ̀ yẹn ní Ìràwọ̀ Òwúrọ̀ láti fi hàn pé wọ́n nígbàgbọ́ nínú ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rún Ọdún tí Kristi ń bọ̀ wá ṣe.

Ọ̀gbẹ́ni Barrie Macdonald sọ nínú ìwé rẹ̀ tó pè ní Cinderellas of the Empire pé: “Ara Bingham ò fi bẹ́ẹ̀ le. Gbogbo ìgbà ni inú máa ń run ún, ọ̀nà ọ̀fun tó sì ń dùn ún kì í jẹ́ kó lè sọ̀rọ̀ dáadáa nígbà tó bá ń bá ọ̀pọ̀ èèyàn sọ̀rọ̀. Ojú tún ń dùn ún, èyí kò sì jẹ́ kó lè kàwé ju wákàtí méjì sí mẹ́ta lọ lójúmọ́.”

Àmọ́ láìka èyí sí, Bingham pinnu pé òun máa kọ́ èdè Gilbertese. Èyí kì í ṣe iṣẹ́ kékeré rárá. Ó bẹ̀rẹ̀ nípa nínawọ́ sáwọn nǹkan, á sì ní káwọn tó ń sọ èdè Gilbertese sọ orúkọ tí wọ́n ń pè é fóun. Nígbà tó ti kọ ọ̀rọ̀ tó pọ̀ tó ẹgbẹ̀rún méjì sílẹ̀ tán, ó ń fún ọ̀kan lára àwọn tó ti wàásù fún ní owó dọ́là kan fún ọgọ́rùn-ún ọ̀rọ̀ tuntun tó bá lè fi kún èyí tó ti kọ sílẹ̀.

Sùúrù Bingham sèso rere. Ìdí ni pé nígbà tó fi máa kúrò ní Erékùṣù Gilbert lọ́dún 1865 nítorí àìlera rẹ̀ tó túbọ̀ ń burú sí i, ó ti sọ èdè Gilbertese di èyí tí wọ́n lè máa kọ sílẹ̀. Kì í ṣèyẹn nìkan, ó tún ti túmọ̀ ìwé Mátíù àti Jòhánù sí èdè Gilbertese. Nígbà tó padà lọ sí erékùṣù yẹn ní ọdún 1873, ó mú odindi Májẹ̀mú Tuntun lédè Gilbertese dání. Ó ń bá iṣẹ́ ìtúmọ̀ rẹ̀ lọ fún ọdún mẹ́tàdínlógún, nígbà tó sì máa fi di ọdún 1890, ó parí títúmọ̀ odindi Bíbélì lédè Gilbertese.

Títí dòní làwọn tó ń gbé ní Erékùṣù Kiribati ṣì ń lo Bíbélì tí Bingham túmọ̀. Àwọn tó ń kà á kíyè sí i pé ó lo orúkọ Jèhófà (Iehova lédè Gilbertese) ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìgbà nínú Májẹ̀mú Láéláé, ó sì lò ó tó ìgbà àádọ́ta nínú Májẹ̀mú Tuntun. Lóòótọ́, atúmọ̀ Bíbélì tó bọ̀wọ̀ fún orúkọ Ọlọ́run ni Hiram Bingham!

[Àwọn àwòrán]

Hiram Bingham II

Bíbélì lédè Gilbertese tí Bingham túmọ̀

[Credit Line]

A rí fọ́tò ti òkè nínú ìwé tí Alfred M. Bingham kọ, tó pe orúkọ rẹ̀ ní, “The Tiffany Fortune”

[Àtẹ Ìsọfúnnni/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18, 19]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

200

DIUTARÓNÓMÌ 6:4

ÒRÉPÈTÉ NASH

Ní ọ̀rúndún kejì tàbí ìkíní ṣáájú Sànmánì Kristẹni

[Àwòrán]

Ìwé ayé ìgbàanì tó wà lédè Hébérù tí orúkọ Ọlọ́run fara hàn nínú rẹ̀ lẹ́ẹ̀méjì

100

ÀJÁKÙ DIUTARÓNÓMÌ 18:15, 16

P. FOUAD INV. 266

Ní ọ̀rúndún kìíní ṣáájú Sànmánì Kristẹni

[Àwòrán]

Ìwé Májẹ̀mú Láéláé tí wọ́n túmọ̀ sí èdè Gíríìkì, tí orúkọ Ọlọ́run tí wọ́n fi lẹ́tà èdè Hébérù kọ fara hàn nínú rẹ̀

[Credit Line]

Société Royale de Papyrologie du Caire

↑

Ṣ.S.K.

S.K.

↓

100

300

400

DIUTARÓNÓMÌ 18:15

CODEX ALEXANDRINUS

Ọ̀rúndún karùn-ún Sànmánì Kristẹni

[Àwòrán]

Wọ́n ti yọ orúkọ Ọlọ́run kúrò nínú Bíbélì yìí, wọ́n sì ti fi K̇Ċ àti KY tó jẹ́ ìkékúrú ọ̀rọ̀ Gíríìkì tó ń jẹ́ Kýrios (ìyẹn “Olúwa”) rọ́pò rẹ̀

[Credit Line]

Látinú The Codex Alexandrinus in Reduced Photographic Facsimile, 1909, àwọn British Library ló fún wa láṣẹ láti lò ó

500

1900

1950

ÌṢE 3:22, FA Ọ̀RỌ̀ YỌ LÁTINÚ DIUTARÓNÓMÌ 18:15

ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ọ̀rúndún ogún Sànmánì Kristẹni

[Àwòrán]

Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun dá orúkọ Ọlọ́run padà sáyè ẹ̀

2000

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Bí orúkọ Ọlọ́run ṣe fara hàn ní Róòmù 10:13 nínú oríṣiríṣi Bíbélì

Bíbélì Hutter lédè Hébérù, Gíríìkì, Látìn àti Jámánì

Bíbélì Rotuman

bíbélì Batak-Toba

Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun (Gẹ̀ẹ́sì)

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́