ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • yc ẹ̀kọ́ 10 ojú ìwé 22-23
  • Jésù Máa Ń Ṣègbọràn ní Gbogbo Ìgbà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jésù Máa Ń Ṣègbọràn ní Gbogbo Ìgbà
  • Kọ́ Ọmọ Rẹ
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jésù Kẹ́kọ̀ọ́ Láti Jẹ́ Onígbọràn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Àwọn Ohun Tá A Lè Kọ́ Lára Màríà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Ó Dé ‘Ìparí Èrò Nínú Ọkàn Rẹ̀’
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
  • “Èyí Ni Ọmọ Mi”
    Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà
Àwọn Míì
Kọ́ Ọmọ Rẹ
yc ẹ̀kọ́ 10 ojú ìwé 22-23
Jósẹ́fù àti Màríà rí Jésù nínú tẹ́ńpìlì

Ẹ̀kọ́ 10

Jésù Máa Ń Ṣègbọràn Ní Gbogbo Ìgbà

Ṣé gbogbo ìgbà ló máa ń rọrùn fún ẹ láti gbọ́rọ̀ sí àwọn òbí rẹ lẹ́nu?— Ó máa ń ṣòro nígbà míì. Ǹjẹ́ o mọ̀ pé Jésù gbọ́rọ̀ sí Jèhófà àti àwọn òbí rẹ̀ lẹ́nu?— Àpẹẹrẹ rẹ̀ lè jẹ́ kí ìwọ náà máa gbọ́rọ̀ sí àwọn òbí rẹ lẹ́nu, kódà nígbà tí kò bá tiẹ̀ rọrùn fún ẹ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa bí Jésù ṣe ṣègbọràn.

Kí Jésù tó wá sí ayé, ó ti wà lọ́run tẹ́lẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà, Bàbá rẹ̀. Àmọ́ Jésù tún ní àwọn òbí lórí ilẹ̀ ayé. Jósẹ́fù àti Màríà ni orúkọ wọn. Ṣé o mọ bí wọ́n ṣe di òbí Jésù?—

Ọlọ́run mú ìwàláàyè Jésù ní ọ̀run, ó sì fi sínú Màríà kí ó lè bí Jésù, kí Jésù lè máa gbé láyé. Iṣẹ́ ìyanu gbáà lèyí! Ìwàláàyè Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í dàgbà ní inú Màríà gẹ́gẹ́ bí ọmọ ṣe máa ń dàgbà ní inú ìyá rẹ̀. Ní nǹkan bí oṣù mẹ́sàn-án lẹ́yìn náà, Màríà bí Jésù. Bí Màríà àti Jósẹ́fù ọkọ rẹ̀ ṣe di òbí Jésù lórí ilẹ̀ ayé nìyẹn.

Nígbà tí Jésù wà ní ọmọ ọdún méjìlá, ó ṣe ohun kan tó fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, Baba rẹ̀ gan-an. Èyí ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jésù àti ìdílé rẹ̀ rin ìrìn àjò lọ sí ibi tó jìn. Jerúsálẹ́mù ni ibi tí wọ́n ti lọ ṣe àjọyọ̀ Ìrékọjá. Nígbà tí wọ́n ń pa dà lọ sílé, Jósẹ́fù àti Màríà kò rí Jésù, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í wá a. Ǹjẹ́ o mọ ibi tí Jésù wà?—

Kí nìdí tí Jésù fi lọ sí tẹ́ńpìlì?

Jósẹ́fù àti Màríà sáré pa dà lọ sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n ń wá Jésù káàkiri. Wọ́n dààmú torí pé wọn kò rí i. Àmọ́ lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta, wọ́n rí i nínú tẹ́ńpìlì. Ǹjẹ́ o mọ ìdí tí Jésù fi lọ sínú tẹ́ńpìlì?— Ìdí ni pé ibẹ̀ ló ti lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, Bàbá rẹ̀. Ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó sì fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí ó ṣe lè mú inú rẹ̀ dùn. Kódà nígbà tó dàgbà, gbogbo ìgbà ni ó máa ń ṣègbọràn sí Jèhófà. Nígbà tí kò bá tiẹ̀ rọrùn fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀ tàbí tí wọ́n bá fẹ́ fi ìyà jẹ ẹ́, ó máa ń ṣègbọràn sí Jèhófà. Ǹjẹ́ Jésù gbọ́rọ̀ sí Jósẹ́fù àti Màríà lẹ́nu?— Bẹ́ẹ̀ ni, Bíbélì sọ pé, ó ṣe bẹ́ẹ̀.

Kí lo rí kọ́ lára Jésù?— Ìwọ náà gbọ́dọ̀ máa gbọ́rọ̀ sí àwọn òbí rẹ lẹ́nu, kódà nígbà tí kò bá rọrùn fún ẹ láti ṣe ohun tí wọ́n sọ. Ṣé wàá ṣe bẹ́ẹ̀?—

KÀ Á NÍNÚ BÍBÉLÌ RẸ

  • Lúùkù 1:30-35; 2:45-52

  • Éfésù 6:1

  • Hébérù 5:8

ÌBÉÈRÈ:

  • Báwo ni Jósẹ́fù àti Màríà ṣe di òbí Jésù lórí ilẹ̀ ayé?

  • Nígbà tí àwọn òbí Jésù ń wá a káàkiri ní Jerúsálẹ́mù, ibo ni wọ́n ti rí i?

  • Kí lo rí kọ́ lára Jésù?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́