ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • hf apá 7 1-4
  • Bí O Ṣe Lè Máa Kọ́ Ọmọ Rẹ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bí O Ṣe Lè Máa Kọ́ Ọmọ Rẹ
  • Ìdílé Rẹ Lè Jẹ́ Aláyọ̀
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • 1 MÚ KÓ RỌRÙN FÚN ÀWỌN ỌMỌ RẸ LÁTI BÁ Ọ SỌ̀RỌ̀
  • 2 GBÌYÀNJÚ LÁTI MỌ OHUN TÓ WÀ LỌ́KÀN WỌN
  • 3 Ẹ MÁA FỌWỌ́ SOWỌ́ PỌ̀
  • 4 Ẹ ṢÈTÒ BÍ Ẹ ṢE MÁA KỌ́ WỌN
  • Kọ́ Ọmọ Rẹ Láti Ìgbà Ọmọdé Jòjòló
    Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
  • Ẹ̀yin Òbí—ẹ Máa Kọ́ Àwọn Ọmọ Yín Tìfẹ́tìfẹ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ǹjẹ́ Bíbélì Lè Ràn ọ́ Lọ́wọ́ Láti Tọ́ Àwọn Ọmọ Rẹ?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Gbígbé Ìdílé Tó Dúró Sán-ún Nípa Tẹ̀mí Ró
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
Àwọn Míì
Ìdílé Rẹ Lè Jẹ́ Aláyọ̀
hf apá 7 1-4
Bàbá àti ọmọ jọ ń tún kẹ̀kẹ́ ṣe

APÁ KEJE

Bí O Ṣe Lè Máa Kọ́ Ọmọ Rẹ

Kí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí mo ń pa láṣẹ fún ọ lónìí sì wà ní ọkàn-àyà rẹ, kí ìwọ sì fi ìtẹnumọ́ gbìn wọ́n sínú ọmọ rẹ.”​—Diutarónómì 6:​6, 7

Nígbà tí Jèhófà dá ìdílé sílẹ̀, ó fi àwọn ọmọ sábẹ́ àbójútó àwọn òbí wọn. (Kólósè 3:20) Ojúṣe ẹ̀yin òbí ni láti kọ́ àwọn ọmọ yín kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, kí wọ́n sì di àgbà tó dáńgájíá. (2 Tímótì 1:5; 3:​15) Ẹ tún gbọ́dọ̀ rí i pé ẹ mọ ohun tó wà ní ọkàn àwọn ọmọ yín. Ẹ má sì gbàgbé pé àpẹẹrẹ tí ẹ bá fi lélẹ̀ ṣe pàtàkì gan-an. Ọ̀nà tó dára jù tí ẹ lè gbà fi Ọ̀rọ̀ Jèhófà kọ́ ọmọ yín ni pé kí ẹ kọ́kọ́ fi sí ọkàn ẹ̀yin fúnra yín.​—Sáàmù 40:8.

1 MÚ KÓ RỌRÙN FÚN ÀWỌN ỌMỌ RẸ LÁTI BÁ Ọ SỌ̀RỌ̀

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: ‘Kí ènìyàn yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ.’ (Jákọ́bù 1:​19) Mú kó máa wu àwọn ọmọ rẹ láti bá ọ sọ̀rọ̀ fàlàlà. O ní láti jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé o máa tẹ́tí gbọ́ wọn tí wọ́n bá fẹ́ bá ẹ sọ̀rọ̀. Máa ṣe àwọn ohun tí á fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ kí wọ́n lè máa sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn. (Jákọ́bù 3:​18) Tí wọ́n bá ti rò ó pé ọ̀rọ̀ rẹ ti máa le jù tàbí pé ṣe lo máa kanra mọ́ wọn, wọ́n lè má sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn wọn fún ẹ. Máa ní sùúrù fún àwọn ọmọ rẹ, kí o sì máa fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ pé o nífẹ̀ẹ́ wọn.​—Mátíù 3:​17; 1 Kọ́ríńtì 8:1.

OHUN TÍ O LÈ ṢE:

  • Máa wá àyè láti tẹ́tí gbọ́ àwọn ọmọ rẹ nígbà tí wọ́n bá fẹ́ bá ẹ sọ̀rọ̀

  • Máa bá àwọn ọmọ rẹ sọ̀rọ̀ déédéé, kó má wulẹ̀ jẹ́ ìgbà tí ìṣòro bá wà nìkan

2 GBÌYÀNJÚ LÁTI MỌ OHUN TÓ WÀ LỌ́KÀN WỌN

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: “Ẹni tí ń fi ìjìnlẹ̀ òye hàn nínú ọ̀ràn yóò rí ire.” (Òwe 16:20) Nígbà míì, o máa ní láti wò kọjá ọ̀rọ̀ ẹnu àwọn ọmọ rẹ kí o tó lè lóye ohun tí wọ́n ní lọ́kàn. Àbùmọ́ sábà máa ń wà nínú ọ̀rọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tàbí kí wọ́n sọ ohun tí wọn kò ní lọ́kàn láti ṣe. “Tí ẹnì kan bá ń fèsì [ọ̀rọ̀] kí ó tó gbọ́ ọ, èyíinì jẹ́ ìwà òmùgọ̀ níhà ọ̀dọ̀ rẹ̀ àti ìtẹ́lógo.” (Òwe 18:13) Má ṣe tètè máa bínú.​—Òwe 19:11.

Ìyá kan ń fìkanra bá ọmọ ẹ̀ wí torí ohun tó sọ

OHUN TÍ O LÈ ṢE:

  • Pinnu pé o kò ní já lu ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ rẹ àti pé o kò ní fara ya láìka ohun tí wọ́n bá sọ sí

  • Máa rántí bọ́rọ̀ ṣe máa ń rí lára tìẹ náà àtàwọn ohun tí o kà sí pàtàkì nígbà tí o wà lọ́jọ́ orí tí wọ́n wà

3 Ẹ MÁA FỌWỌ́ SOWỌ́ PỌ̀

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: “Fetí sílẹ̀, ọmọ mi, sí ìbáwí baba rẹ, má sì ṣá òfin ìyá rẹ tì.” (Òwe 1:8) Bàbá àti ìyá ni Jèhófà fún ní àṣẹ lórí àwọn ọmọ. Ẹ gbọ́dọ̀ kọ́ àwọn ọmọ yín láti máa bọ̀wọ̀ fún yín kí wọ́n sì máa gbọ́ràn sí yín lẹ́nu. (Éfésù 6:​1-3) Àwọn ọmọ máa ń mọ̀ tí ‘èrò àwọn òbí wọn kò bá ṣọ̀kan.’ (1 Kọ́ríńtì 1:​10) Tí èrò yín kò bá ṣọ̀kan, ẹ rí i dájú pé ẹ kò bá ara yín fa ọ̀rọ̀ níṣojú àwọn ọmọ yín, torí pé èyí lè mú kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í rí yín fín.

Bàbá kan ń bá ọmọ ẹ̀ wí ní kọ̀rọ̀, ìyá ẹ̀ àti ẹ̀gbọ́n ẹ̀ sì wà ní yàrá kejì

OHUN TÍ O LÈ ṢE:

  • Ẹ jọ sọ̀rọ̀, kí ẹ sì fẹnu kò lórí bí ẹ ó ṣe máa bá àwọn ọmọ yín wí

  • Tí èrò ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ kò bá ṣọ̀kan lórí bí ẹ ṣe máa tọ́ àwọn ọmọ yín, gbìyànjú láti mọ ohun tí ọkọ tàbí aya rẹ ní lọ́kàn

4 Ẹ ṢÈTÒ BÍ Ẹ ṢE MÁA KỌ́ WỌN

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: “Tọ́ ọmọdékùnrin ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà tí yóò tọ̀.” (Òwe 22:6) Àwọn ọmọ yín kò ní ṣàdédé mọ àwọn ohun tó yẹ lámọ̀dunjú. Ẹ ní láti ṣètò bí ẹ ó ṣe máa kọ́ wọn, èyí sì kan bí ẹ ó ṣe máa bá wọn wí. (Sáàmù 127:4; Òwe 29:17) Ìbáwí kò mọ sórí fífi ìyà jẹni, ó tún wé mọ́ jíjẹ́ kí àwọn ọmọ lóye ìdí tó fi yẹ kí wọ́n pa òfin mọ́. (Òwe 28:7) Ẹ tún ní láti kọ́ wọn bí wọ́n ṣe lè nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Jèhófà kí wọ́n sì lóye àwọn ìlànà rẹ̀. (Sáàmù 1:2) Èyí máa jẹ́ kí wọ́n lè ní ẹ̀rí ọkàn rere.​—Hébérù 5:​14.

OHUN TÍ O LÈ ṢE:

  • Rí i dájú pé àwọn ọmọ rẹ mọ Ọlọ́run sí Ẹni gidi tí wọ́n lè fọkàn tán

  • Jẹ́ kí wọ́n mọ àwọn oníwàkiwà tó lè ṣàkóbá fún wọn, kí wọ́n sì máa yẹra fún wọn. Irú bí àwọn ­oníwàkiwà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì àti lórí àwọn ìkànnì àjọlò. Kọ́ wọn bí wọn ò ṣe ní kó sọ́wọ́ àwọn tó ń fipá báni lò pọ̀

Àwọn òbí kan ń kọ́ ọmọ wọn láti máa sin Jèhófà, láti kékeré títí ó fi ṣèrìbọmi

“Tọ́ ọmọdékùnrin ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà tí yóò tọ̀”

JÈHÓFÀ YÓÒ BÙ KÚN ÌSAPÁ RẸ

Ojúṣe pàtàkì tí ẹ̀yin òbí ní ni pé kí ẹ kọ́ àwọn mọ yín lẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Jèhófà ṣe ń ronú. (Éfésù 6:4) Jèhófà mọ̀ pé èyí kì í ṣe iṣẹ́ kékeré, àmọ́ ẹ jẹ́ kó dá yín lójú pé tí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ ó lè fi ìyìn fún Ọlọ́run, ẹ ó sì ní ayọ̀ tó pọ̀ jaburata.​—Òwe 23:24.

BI ARA RẸ PÉ . . .

  • Kí ni mo lè ṣe tí ọkàn ọmọ mi á fi lè balẹ̀ láti bá mi sọ ohunkóhun tó bá wà lọ́kàn rẹ̀?

  • Kí ni mo lè rí kọ́ látinú ọ̀nà tí àwọn òbí mìíràn gbà ń tọ́ àwọn ọmọ wọn?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́