ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • snnw orin 142
  • À Ń Wàásù fún Gbogbo Onírúurú Èèyàn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • À Ń Wàásù fún Gbogbo Onírúurú Èèyàn
  • Kọrin sí Jèhófà—Àwọn Orin Tuntun
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Máa Wàásù fún Onírúurú Èèyàn
    “Fi Ayọ̀ Kọrin” sí Jèhófà
  • Kọ́ Wọn Kí Wọ́n Lè Dúró Gbọn-in
    Kọrin sí Jèhófà—Àwọn Orin Tuntun
  • Jèhófà Ni Orúkọ Rẹ
    Kọrin sí Jèhófà—Àwọn Orin Tuntun
  • Tẹjú Mọ́ Èrè Náà
    “Fi Ayọ̀ Kọrin” sí Jèhófà
Àwọn Míì
Kọrin sí Jèhófà—Àwọn Orin Tuntun
snnw orin 142

Orin 142

À Ń Wàásù fún Gbogbo Onírúurú Èèyàn

Bíi Ti Orí Ìwé

(1 Tímótì 2:4)

  1. A fẹ́ máa fara wé Ọlọ́run wa,

    Ká jẹ́ ẹni tí kì í ṣojúsàájú.

    Ó fẹ́ kí gbogbo èèyàn rí’gbàlà;

    Gbogbo onírúurú èèyàn ló ń pè.

    (ÈGBÈ)

    Ibi yòówù kí wọ́n wà;

    Ọkàn ló ṣe pàtàkì.

    À ń wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún wọn.

    Torí pé a nífẹ̀ẹ́ wọn,

    À ń wàásù níbi gbogbo:

    “Káwọn èèyàn lè dọ̀rẹ́ Ọlọ́run.”

  2. Ibi yòówù kí a ti pàdé wọn

    Tàbí irú ẹni tí wọ́n lè jẹ́.

    Ẹni tí wọ́n jẹ́ nínú ni Jáà rí—

    Ìyẹn ló sì ṣe pàtàkì jù sí i.

    (ÈGBÈ)

    Ibi yòówù kí wọ́n wà;

    Ọkàn ló ṣe pàtàkì.

    À ń wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún wọn.

    Torí pé a nífẹ̀ẹ́ wọn,

    À ń wàásù níbi gbogbo:

    “Káwọn èèyàn lè dọ̀rẹ́ Ọlọ́run.”

  3. Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn tó pinnu

    Láti má ṣe jẹ́ apá kan ayé.

    A mọ èyí, a sì fẹ́ káyé mọ̀,

    Torí náà à ń wàásù fáwọn èèyàn.

    (ÈGBÈ)

    Ibi yòówù kí wọ́n wà;

    Ọkàn ló ṣe pàtàkì.

    À ń wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún wọn.

    Torí pé a nífẹ̀ẹ́ wọn,

    À ń wàásù níbi gbogbo:

    “Káwọn èèyàn lè dọ̀rẹ́ Ọlọ́run.”

(Tún wo Jòh. 12:32; Ìṣe 10:34; 1 Tím. 4:10; Títù 2:11.)

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́