ORIN 144
Tẹjú Mọ́ Èrè Náà
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Afọ́jú yóò tún pa dà ríran,
Adití yóò sì pa dà gbọ́ràn,
Ọmọdé yóò máa fayọ̀ kọrin,
Àlàáfíà yóò kárí ayé,
Àwọn tó ti kú yóò tún jíǹde,
Sínú ayé tí kò sẹ́ṣẹ̀ mọ́.
(ÈGBÈ)
Wàá rí bí Jèhófà yóò ṣe ṣe é,
Tó o bá tẹjú mọ́ èrè náà.
2. Àwọn ẹranko yóò máa gbé pọ̀.
Wọn kò ní máa para wọn jẹ mọ́.
Ọmọdé ni yóò máa darí wọn.
Wọn yóò máa tẹ̀ lé àṣẹ rẹ̀.
Kò ní sẹ́kún àti ọ̀fọ̀ mọ́.
Ìbẹ̀rù, ìrora kò sí mọ́.
(ÈGBÈ)
Wàá rí bí Jèhófà yóò ṣe ṣe é,
Tó o bá tẹjú mọ́ èrè náà.
(Tún wo Àìsá. 11:6-9; 35:5-7; Jòh. 11:24.)