Orin 24
Tẹjú Mọ́ Èrè Náà!
Bíi Ti Orí Ìwé
1.’Gbà táfọ́jú bá tún ńríran
Tí adití sì tún ńgbọ́ràn,
Tódòdó sì ńtàn láginjù
Tílẹ̀ gbígbẹ ńṣàn fún omi,
Tí arọ ńfò bí àgbọ̀nrín,
Tí ìpínyà sì ti dópin,
Àkókò náà yóò ṣojú rẹ,
Bóo bá tẹjú mọ́ èrè náà.
2. ’Gbà tódi bá ńpa dà sọ̀rọ̀,
Tárúgbó pa dà di ọ̀dọ́,
Tí ilẹ̀ ńmú ìbísí wá
Tí gbogbo nǹkan rere ńpọ̀ síi,
Tórin àwọn ọmọ gbilẹ̀,
Táyọ̀, àlááfíà gbòde kan,
Wàá ráwọn òkú tó ńjíǹde,
Bóo bá tẹjú mọ́ èrè náà.
3.’Gbà tíkookò ńbágùntàn jẹ̀,
Tí màlúù òun béárì jọ ńjẹ̀,
Tí ọmọdé yóò máa dà wọ́n,
Tí wọn yóò sì máa ṣègbọràn.
Tómijé máa di nǹkan tàná,
Tẹ́rù òun ìrora yóò lọ,
Ọlọ́run yóò ṣeé, wàá sì ríi,
Bóo bá tẹjú mọ́ èrè náà.
(Tún wo Aísá. 11:6-9; 35:5-7; Jòh. 11:24.)