Orin 143
Ìmọ́lẹ̀ Nínú Ayé Tó Ṣókùnkùn
Bíi Ti Orí Ìwé
Láyé burúkú tá a wà yìí,
Ìmọ́lẹ̀ wà tá à ń rí.
Bíi pé ojúmọ́ ń mọ́ bọ̀
Tó máa mọ́ kedere.
(ÈGBÈ)
Iṣẹ́ ìwàásù wa,
Mọ́lẹ̀ nínú òkùnkùn.
Ó ń mú ìrètí wá—
Ó ń mọ́lẹ̀, ó ń tàn yòò,
Ó ń mú ká lè rí ọ̀la—
Òkùnkùn lọ.
Ó yẹ ká jí àwọn tó ń sùn
Torí àkókò ń lọ.
À ń gbé wọn ró, wọ́n ń nírètí.
À ń fi wọ́n sádùúrà.
(ÈGBÈ)
Iṣẹ́ ìwàásù wa,
Mọ́lẹ̀ nínú òkùnkùn.
Ó ń mú ìrètí wá—
Ó ń mọ́lẹ̀, ó ń tàn yòò,
Ó ń mú ká lè rí ọ̀la—
Òkùnkùn lọ.
(Tún wo Jòh. 3:19; 8:12; Róòmù 13:11, 12; 1 Pét. 2:9.)