Orin153
Báwo Ló Ṣe Rí Lára Rẹ?
Báwo ló ṣe ńrí ná
tóo bá ńwàásù, tóò ńkọ́ni,
Tóo mọ̀ póo ti sapá gan-an
kí olóòótọ́ lè gbọ́?
Sa gbogbo ipá rẹ;
Ọlọ́run máa fèrè síi.
Ó mọ àwọn èèyàn
tó fẹ́ mọ òun lóòótọ́.
((ÈGBÈ)
Inú wa ńdùn, ọkàn wa yọ̀
àń yìnín lọ́kàn, lérò, lọ́rọ̀.
Ká máa rú ẹbọ ìyìn síi
lójúmọ́ ayé wa.
Báwo ló ṣe ńrí ná
tóo bá sọ ọ̀rọ̀ rere
Fún ọlọ́kàn rere
tó ńfẹ́’yè àìnípẹ̀kun?
Àwọn kan kò fẹ́ gbọ́,
wọ́n ṣi àwọn míì lọ́nà.
Àwa ńjẹ́ orúkọ mọ́ ọn
à ńbá’ṣẹ́ ‘wàásù lọ.
(Ègbè)
Inú wa ńdùn, ọkàn wa yọ̀
àń yìnín lọ́kàn, lérò, lọ́rọ̀.
Ká máa rú ẹbọ ìyìn síi
lójúmọ́ ayé wa.
Báwo ló ṣe ńrí ná,
pé ò ńrọ́wọ́ Ọlọ́run,
Ó sì jẹ́ kí o máa ṣiṣẹ́
tí ó gbé fún wa?
À ńwàásù, à ńkọ́ni,
À ńsọ ọ̀rọ̀ tó tura,
À ńwá ẹni yíyẹ kàn;
iṣẹ́ yìí ńparí lọ.
(Ègbè)
Inú wa ńdùn, ọkàn wa yọ̀
àń yìnín lọ́kàn, lérò, lọ́rọ̀.
Ká máa rú ẹbọ ìyìn síi
lójúmọ́ ayé wa.
(Tún wo Ìṣe 13:48; 1 Tẹs. 2:4; 1 Tím. 1:11.)