ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • sjj orin 76
  • Báwo Ló Ṣe Máa Ń Rí Lára Rẹ?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Ló Ṣe Máa Ń Rí Lára Rẹ?
  • “Fi Ayọ̀ Kọrin” sí Jèhófà
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Báwo Ló Ṣe Rí Lára Rẹ?
    Kọrin sí Jèhófà—Àwọn Orin Tuntun
  • Jèhófà Fìfẹ́ Rọ̀ Ọ́ Pé: “Ọmọ Mi, Jẹ́ Ọlọ́gbọ́n”
    “Fi Ayọ̀ Kọrin” sí Jèhófà
  • Máa Ṣe “Àwọn Ohun Tó Ṣe Pàtàkì Jù”
    “Fi Ayọ̀ Kọrin” sí Jèhófà
  • A Ti Ya Ara Wa sí Mímọ́ fún Ọlọ́run!
    “Fi Ayọ̀ Kọrin” sí Jèhófà
Àwọn Míì
“Fi Ayọ̀ Kọrin” sí Jèhófà
sjj orin 76

ORIN 76

Báwo Ló Ṣe Máa Ń Rí Lára Rẹ?

Bíi Ti Orí Ìwé

(Hébérù 13:15)

  1. 1. Báwo ló ṣe máa ń rí

    tó o bá ń ṣiṣẹ́ ìwàásù,

    tó ò ń gbìyànjú láti dé

    ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn?

    Àwa gbẹ́kẹ̀ lé Jáà,

    yóò bù kún iṣẹ́ tá a ṣe,

    Torí Ó mọ àwọn tó

    jẹ́ ọlọ́kàn tútù.

    (ÈGBÈ)

    Inú wa dùn, ayọ̀ wa kún

    pé a ti ṣohun tá a lè ṣe.

    Kí Jèhófà tẹ́wọ́ gba ‘ṣẹ́

    tá à ń ṣe lójoojúmọ́.

  2. 2. Báwo ló ṣe máa ń rí

    tó o bá báwọn kan sọ̀rọ̀

    tí wọ́n tẹ́tí gbọ́rọ̀ rẹ,

    tó sì wọ̀ wọ́n lọ́kàn?

    Àwọn mí ì kọ̀ jálẹ̀,

    Wọn kò fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ wa.

    Síbẹ̀, à ń láyọ̀ pé à ń

    wàásù orúkọ Jáà.

    (ÈGBÈ)

    Inú wa dùn, ayọ̀ wa kún

    pé a ti ṣohun tá a lè ṣe.

    Kí Jèhófà tẹ́wọ́ gba ‘ṣẹ́

    tá à ń ṣe lójoojúmọ́.

  3. 3. Báwo ló ṣe máa ń rí

    tó o bá ń ṣiṣẹ́ Jèhófà,

    tó fi sí ìkáwọ́ wa,

    tó sì ń tì wá lẹ́yìn?

    À ń wá àwọn èèyàn

    tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ òtítọ́.

    À ń sọ̀rọ̀ tútù lẹ́nu

    bá a ṣe ń wàásù fún wọn.

    (ÈGBÈ)

    Inú wa dùn, ayọ̀ wa kún

    pé a ti ṣohun tá a lè ṣe.

    Kí Jèhófà tẹ́wọ́ gba ‘ṣẹ́

    tá à ń ṣe lójoojúmọ́.

(Tún wo Ìṣe 13:48; 1 Tẹs. 2:4; 1 Tím. 1:11.)

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́