ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • jy orí 9 ojú ìwé 26-ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 1
  • Ó Ń Dàgbà ní Násárẹ́tì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ó Ń Dàgbà ní Násárẹ́tì
  • Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ibẹrẹpẹpẹ Igbesi-aye Idile Jesu
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
  • Ó Dáàbò Bo Ìdílé Rẹ̀, Ó Pèsè fún Wọn, Ó sì Ní Ìfaradà
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
  • Ó Dáàbò Bo Ìdílé Rẹ̀, Ó Pèsè fún Wọn, Ó sì Lo Ìfaradà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Ó Gba Ìtọ́sọ́nà Àtọ̀runwá
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
Àwọn Míì
Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
jy orí 9 ojú ìwé 26-ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 1
Jósẹ́fù ń kọ́ Jésù ní iṣẹ́ káfíńtà

ORÍ 9

Ó Ń Dàgbà ní Násárẹ́tì

MÁTÍÙ 13:55, 56 MÁÀKÙ 6:3

  • JÓSẸ́FÙ ÀTI MÀRÍÀ BÍ ÀWỌN ỌMỌ MÍÌ

  • JÉSÙ KỌ́ IṢẸ́ ỌWỌ́

Jésù ń dàgbà ní Násárẹ́tì, ìyẹn ìlú kékeré kan tí ò fi bẹ́ẹ̀ gbajúmọ̀. Agbègbè Gálílì ni ìlú yìí wà, ó sì wà ní apá ìwọ̀ oòrùn Òkun Gálílì.

Nígbà tí Jésù wà ní nǹkan bí ọmọ ọdún méjì, Jósẹ́fù àti Màríà kúrò ní Íjíbítì, wọ́n sì kó wá sí Násárẹ́tì. Ó jọ pé òun nìkan ni wọ́n ṣì bí nígbà yẹn. Nígbà tó yá, Màríà bí àwọn ọmọkùnrin míì, orúkọ wọn ni Jémíìsì, Jósẹ́fù, Símónì àti Júdásì. Jósẹ́fù àti Màríà tún bí àwọn ọmọbìnrin. Ó kéré tán, àbúrò ọkùnrin àti obìnrin mẹ́fà ni Jésù ní.

Jésù tún ní àwọn mọ̀lẹ́bí míì. Lára wọn ni Èlísábẹ́tì àti Jòhánù ọmọ rẹ̀. Apá gúúsù nílẹ̀ Jùdíà ni Jòhánù ń gbé. Jésù tún ní àwọn mọ̀lẹ́bí míì tó ń gbé nítòsí wọn ní Gálílì. Ọ̀kan lára wọn ni Sàlómẹ̀ tó ṣeé ṣe kó jẹ́ arábìnrin Màríà. Sébédè ni ọkọ Sàlómẹ̀, wọ́n sì ní ọmọkùnrin méjì tó ń jẹ́ Jémíìsì àti Jòhánù. Torí náà, á jẹ́ pé ìbátan làwọn ọmọ yìí jẹ́ sí Jésù. A ò mọ̀ bóyá Jésù àtàwọn ọmọ yìí jọ máa ń ṣeré nígbà tí wọ́n ṣì kéré. Àmọ́ nígbà tó yá, àwọn àti Jésù di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́, kódà wọ́n di àpọ́sítélì rẹ̀.

Jósẹ́fù ṣiṣẹ́ kára gan-an kó lè tọ́jú ìyàwó àtàwọn ọmọ rẹ̀, iṣẹ́ káfíńtà ló sì ń ṣe. Jósẹ́fù mú Jésù bí ọmọ, Bíbélì tiẹ̀ pe Jésù ní “ọmọ káfíńtà.” (Mátíù 13:55) Jósẹ́fù kọ́ Jésù ní iṣẹ́ káfíńtà, ó sì mọṣẹ́ náà dáadáa. Kódà nígbà tó yá, ohun táwọn èèyàn sọ nípa Jésù ni pé: “Káfíńtà yẹn nìyí.”—Máàkù 6:3.

Jósẹ́fù àti Màríà ń kọ́ àwọn ọmọ wọn ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

Ìjọsìn Jèhófà ni ìdílé Jósẹ́fù fi sípò àkọ́kọ́. Jósẹ́fù àti Màríà máa ń ṣe ohun tí Òfin Ọlọ́run sọ, wọ́n sì máa ń kọ́ àwọn ọmọ wọn ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ‘nígbà tí wọ́n bá jókòó nínú ilé, nígbà tí wọ́n bá ń rìn lójú ọ̀nà, nígbà tí wọ́n bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí wọ́n bá dìde.’ (Diutarónómì 6:6-9) Sínágọ́gù kan wà ní Násárẹ́tì, ó sì dájú pé Jósẹ́fù máa ń kó ìdílé rẹ̀ lọ síbẹ̀ déédéé láti jọ́sìn. Nígbà tó yá, Bíbélì sọ pé Jésù lọ sí sínágọ́gù “bó ṣe máa ń ṣe ní ọjọ́ Sábáàtì.” (Lúùkù 4:16) Inú ìdílé wọn tún máa ń dùn gan-an lásìkò tí wọ́n bá rìnrìn àjò lọ sí tẹ́ńpìlì Jèhófà ní Jerúsálẹ́mù.

  • Ó kéré tán, àbúrò ọkùnrin àti obìnrin mélòó ni Jésù ní?

  • Iṣẹ́ wo ni Jésù kọ́, kí sì nìdí?

  • Ọwọ́ wo ni Jósẹ́fù fi mú ìjọsìn Ọlọ́run nínú ìdílé rẹ̀?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́