Ó Gba Ìtọ́sọ́nà Àtọ̀runwá
KÍ A sọ pé a fi ọmọ pípé kan sábẹ́ àbójútó rẹ tí a sì retí pé kí o tọ́ ọ dáradára. Wo bí ìyẹn yóò ti jẹ́ ìpèníjà kan tó! Báwo ni ẹ̀dá ènìyàn aláìpé èyíkéyìí ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? Kìkì nípa títẹ́wọ́gba ìtọ́sọ́nà àtọ̀runwá àti fífi í sílò nínú ìgbésí-ayé ojoojúmọ́.
Ohun tí Josefu, bàbá alágbàtọ́ Jesu ṣe gan-an nìyẹn. Yàtọ̀ sí kúlẹ̀kúlẹ̀ àwọn ìtàn tí ó lè ṣàìjẹ́ òtítọ́ nípa Josefu, ìwọ̀nba díẹ̀ ni ohun tí Bibeli sọ nípa ipa rírẹlẹ̀ tí ó kó ní ìbẹ̀rẹ̀ ìgbésí-ayé Jesu. A mọ̀ pé Josefu àti aya rẹ̀, Maria, tọ́ Jesu, àwọn ọmọkùnrin mẹ́rin mìíràn, àti àwọn ọmọbìnrin pẹ̀lú.—Marku 6:3.
Josefu jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ọba Dafidi ti Israeli láti ìlà ìdílé Solomoni. Ó jẹ́ ọmọkùnrin Jakọbu àti ọkọ ọmọbìnrin Heli. (Matteu 1:16; Luku 3:23) Gẹ́gẹ́ bíi káfíńtà ní ìlú-ńlá Nasareti ní Galili, Josefu jẹ́ ẹni tí kò fi bẹ́ẹ̀ rí jájẹ nípa ti ara. (Matteu 13:55; Luku 2:4, 24; fiwé Lefitiku 12:8.) Ṣùgbọ́n ó lọ́rọ̀ nípa tẹ̀mí. (Owe 10:22) Dájúdájú èyí jẹ́ nítorí pé ó gba ìtọ́sọ́nà àtọ̀runwá.
Láìsí iyèméjì, Josefu jẹ́ Júù onínútútù àti onírẹ̀lẹ̀-ọkàn tí ó ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọrun tí ó sì nífẹ̀ẹ́-ọkàn láti ṣe ohun tí ó tọ́. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ díẹ̀ nípa ìgbésí-ayé rẹ tí a kọ sínú Ìwé Mímọ́ fihàn pé nígbà gbogbo ni ó ń ṣègbọràn sí àṣẹ Jehofa. Èyí rí bẹ́ẹ̀ yálà a kọ wọ́n sínú Òfin tàbí Josefu rí wọn gbà ní tààràtà nípasẹ̀ àwọn angẹli.
Ọkùnrin Olódodo Tí Ó Ní Ìṣòro
Kí ni ẹnì kan tí ó jẹ́ oníwà-bí-Ọlọrun níláti ṣe nígbà tí ó bá dojúkọ ìṣòro lílekoko? Họ́wù, ó yẹ kí ó “kó ẹrù rẹ̀ lọ sí ara Oluwa” kí ó sì tẹ̀lé ìtọ́sọ́nà àtọ̀runwá! (Orin Dafidi 55:22) Oun tí Josefu ṣe nìyẹn. Nígbà tí ó ti wọnú àdéhùn ìgbéyàwó pẹ̀lú Maria, ‘ó rí i pé ó lóyún lati ọwọ́ ẹ̀mí mímọ́ ṣáájú kí á tó so wọ́n pọ̀ ṣọ̀kan.’ Nítorí pé Josefu ‘jẹ́ olódodo tí kò sì fẹ́ sọ ọ́ di ìran-àpéwò fún gbogbo ènìyàn, ó pètepèrò lati kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ní bòókẹ́lẹ́.’ Lẹ́yìn tí Josefu ti da ọ̀rọ̀ náà rò, áńgẹ́lì Jehofa farahàn án lójú àlá ó sì wí pé: “Josefu, ọmọkùnrin Dafidi, máṣe fòyà lati mú Maria aya rẹ sí ilé, nitori èyíinì tí oun lóyún rẹ̀ sínú jẹ́ nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́. Oun yoo bí ọmọkùnrin kan, iwọ sì gbọ́dọ̀ pe orúkọ rẹ̀ ní Jesu, nitori oun yoo gba awọn ènìyàn rẹ̀ là kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ wọn.” Nígbà tí ó tají, Josefu “ṣe gẹ́gẹ́ bí áńgẹ́lì Jehofa ti darí rẹ̀, ó sì mú aya rẹ̀ sí ilé. Ṣugbọn oun kò ní ìbádàpọ̀ kankan pẹlu rẹ̀ títí ó fi bí ọmọkùnrin kan; ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jesu.” (Matteu 1:18-25, NW) Josefu gba ìtọ́sọ́nà àtọ̀runwá.
Kesari Augustu pàṣẹ pé kí gbogbo ènìyàn fi orúkọ sílẹ̀ ní ìlú wọn. Ní ìṣègbọràn, Josefu àti Maria lọ sí Betlehemu ní Judea. Níbẹ̀ ni Maria bí Jesu sí, ó sì níláti tẹ́ ẹ sí ibùjẹ ẹran nítorí pé kò sí ilé-ibùwọ̀ mìíràn lárọ̀ọ́wọ́tó. Ní alẹ́ ọjọ́ yẹn àwọn olùṣọ́-àgùtàn tí wọ́n ti gbọ́ ìkéde áńgẹ́lì kan nípa àkànṣe ìbímọ yìí wá láti rí ọmọ-ọwọ́ náà. Ní nǹkan bí 40 ọjọ́ lẹ́yìn náà, Josefu àti Maria ṣègbọràn sí Òfin náà nípa gbígbé Jesu lọ sí tẹ́ḿpìlì ní Jerusalemu pẹ̀lú ohun ìrúbọ. Àwọn méjèèjì ṣe kàyéfì bí wọ́n ti gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Simeoni nípa àwọn ohun ribiribi tí Jesu yóò ṣe.—Luku 2:1-33; fiwé Lefitiku 12:2-4, 6-8.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè dàbí ẹni pé Luku 2:39 fihàn pé Josefu àti Maria lọ sí Nasareti tààràtà lẹ́yìn tí wọ́n ti gbé Jesu lọ sí tẹ́ḿpìlì, ẹsẹ ìwé mímọ́ yìí jẹ́ apákan àkọsílẹ̀ kúkúrú. Ó jọ pé ní àkókò kan lẹ́yìn tí wọ́n ti gbé e lọ sí tẹ́ḿpìlì, àwọn awòràwọ̀ ará Gábàsì (Afìràwọ̀mòye) bẹ Maria àti Jesu wò nínú ilé kan ní Betlehemu. Dídá tí Ọlọrun dá sí ọ̀ràn látọ̀runwá ni kò jẹ́ kí ìbẹ̀wò yìí yọrísí ikú fún Jesu. Lẹ́yìn tí àwọn afìràwọ̀mòye náà ti fi ibẹ̀ sílẹ̀, áńgẹ́lì Jehofa yọ sí Josefu lójú àlá ó sì sọ fún un pé: “Herodu ti fẹ́ máa wá ọmọ kékeré naa káàkiri lati pa á run.” Gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀, Josefu kọbiara sí ìtọ́sọ́nà àtọ̀runwá ó sì mú ìdílé rẹ̀ lọ sí Egipti.—Matteu 2:1-14, NW.
Lẹ́yìn ikú Herodu, áńgẹ́lì kan yọ sí Josefu ní Egipti lójú àlá, ó sì sọ pé: “Dìde, mú ọmọ kékeré naa ati ìyá rẹ̀ kí o sì mú ọ̀nà rẹ pọ̀n lọ sí ilẹ̀ Israeli.” Nígbà tí ó gbọ́ pé Arkelau ọmọkùnrin Herodu ni ó ń jọba ní ipò bàbá rẹ̀, ẹ̀rù ba Josefu láti padà sí Judea. Ní kíkọbiara sí ìkìlọ̀ àtọ̀runwá tí a fifún un lójú àlá, ó lọ sí agbègbè Galili ó sì ń gbé ní ìlú-ńlá Nasareti.—Matteu 2:15-23, NW.
Ọkùnrin Tẹ̀mí
Josefu rí sí i pé ìdílé òun ṣègbọràn sí òfin àtọ̀runwá àti pé a fi oúnjẹ tẹ̀mí bọ́ wọn. Lọ́dọọdún ni òun àti gbogbo ìdílé rẹ̀ pátá máa ń lọ sí Jerusalemu fún ayẹyẹ Ìrékọjá. Ní àkókò kan tí wọ́n lọ bẹ́ẹ̀, Josefu àti Maria ń padà lọ sí Nasareti wọ́n sì ti rin ìrìn-àjò ọjọ́ kan láti Jerusalemu nígbà tí wọ́n rí i pé Jesu ọmọ ọdún 12 náà kò sí pẹ̀lú wọn. Lójú ọ̀nà padà sí Jerusalemu, wọ́n fìṣọ́ra wá a kiri wọ́n sì rí i ní tẹ́ḿpìlì lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ó ń tẹ́tísílẹ̀ sí àwọn olùkọ́ níbẹ̀ ó sì ń bi wọ́n ní ìbéèrè.—Luku 2:41-50.
Ó dàbí ẹni pé Josefu jẹ́ kí aya rẹ̀ lo ìdánúṣe nínú àwọn ọ̀ràn kan. Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí wọ́n padà lọ sí Jerusalemu tí wọ́n sì bá Jesu nínú tẹ́ḿpìlì, Maria ni ó bá ọmọdékùnrin rẹ̀ sọ̀rọ̀ lórí ọ̀ràn náà. (Luku 2:48, 49) Nígbà tí ó ń dàgbàsókè gẹ́gẹ́ bí “ọmọkùnrin káfíńtà,” Jesu gba ìtọ́ni tẹ̀mí. Josefu tún kọ́ ọ ní iṣẹ́ káfíńtà, nítorí tí a pe Jesu ní “káfíńtà náà ọmọkùnrin Maria.” (Matteu 13:55; Marku 6:3, NW) Àwọn òbí oníwà-bí-Ọlọ́run lónìí gbọ́dọ̀ lo irú àǹfààní bẹ́ẹ̀ ní kíkún láti fún àwọn ọmọ wọn ní ìtọ́ni, ní pàtàkì jùlọ fífún wọn ní ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tẹ̀mí.—Efesu 6:4; 2 Timoteu 1:5; 3:14-16.
Ohun Tí Josefu Ń Fojúsọ́nà Fún
Ìwé Mímọ́ kò pèsè ìsọfúnni kankan nípa ikú Josefu. Ṣùgbọ́n ó yẹ fún àfiyèsí pé Marku 6:3 (NW) pe Jesu ní “ọmọkùnrin Maria,” dípò ti Josefu. Èyí fihàn pé Josefu ti kú nígbà náà. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, bí ó bá jẹ́ pé Josefu ṣì wàláàyè títí di 33 C.E. ni, kò dàbí ẹni pé Jesu tí a kàn mọ́gi náà yóò fa àbójútó Maria lé aposteli Johannu lọ́wọ́.—Johannu 19:26, 27.
Nítorí náà, Josefu yóò wà lára àwọn òkú tí yóò gbọ́ ohùn Ọmọkùnrin ènìyàn tí wọn yóò sì jáde wá nígbà àjíǹde. (Johannu 5:28, 29) Bí ó ti mọ̀ nípa ìpèsè Jehofa fún ìyè ayérayé, kò sí iyèméjì pé Josefu yóò fi ìdùnnú lo àǹfààní yìí fún ara rẹ̀ tí yóò sì jẹ́ onígbọràn ọmọ-abẹ́ Ọba ọ̀run ńlá náà, Jesu Kristi, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti kọbiara sí ìtọ́sọ́nà àtọ̀runwá ní èyí tí ó ju 1,900 ọdún sẹ́yìn.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Josefu fún Jesu ní ìtọ́ni tẹ̀mí ó sì tún kọ́ ọ ní iṣẹ́ káfíńtà