ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • jy orí 10 ojú ìwé 28-ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 7
  • Jósẹ́fù àti Ìdílé Rẹ̀ Rìnrìn Àjò Lọ sí Jerúsálẹ́mù

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jósẹ́fù àti Ìdílé Rẹ̀ Rìnrìn Àjò Lọ sí Jerúsálẹ́mù
  • Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Awọn Irin Ajo si Jerusalẹmu
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
  • Ìgbà Tí Jésù Wà Lọ́mọdé
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Jésù Ọ̀dọ́mọdé Nínú Tẹ́ńpìlì
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • Jésù Kẹ́kọ̀ọ́ Láti Jẹ́ Onígbọràn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
Àwọn Míì
Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
jy orí 10 ojú ìwé 28-ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 7
Jésù ọmọ ọdún méjìlá wà nínú tẹ́ńpìlì, ó ń bi àwọn olùkọ́ Júù ní ìbéèrè

ORÍ 10

Jósẹ́fù àti Ìdílé Rẹ̀ Rìnrìn Àjò Lọ sí Jerúsálẹ́mù

LÚÙKÙ 2:40-52

  • JÉSÙ ỌMỌ ỌDÚN MÉJÌLÁ Ń BI ÀWỌN OLÙKỌ́ NÍ ÌBÉÈRÈ

  • JÉSÙ PE JÈHÓFÀ NÍ “BABA MI”

Ìgbà ìrúwé ti dé báyìí, torí náà àkókò ti tó fún ìdílé Jósẹ́fù àtàwọn ọ̀rẹ́ wọn títí kan àwọn mọ̀lẹ́bí wọn láti rìnrìn àjò lọ sí Jerúsálẹ́mù bí wọ́n ṣe máa ń ṣe lọ́dọọdún. Àjọyọ̀ Ìrékọjá ni wọ́n máa ń lọ ṣe níbẹ̀ bí Òfin Mósè ṣe pa á láṣẹ. (Diutarónómì 16:16) Nǹkan bíi máìlì márùndínlọ́gọ́rin (75) ni Násárẹ́tì sí Jerúsálẹ́mù. Àsìkò àjọyọ̀ ni ìgbà yẹn máa ń jẹ́ fún wọn bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ nǹkan ni wọ́n máa ń múra sílẹ̀. Jésù ti pé ọmọ ọdún méjìlá (12) báyìí, ó sì ń wọ̀nà fún àjọyọ̀ yẹn torí pé inú ẹ̀ máa ń dùn láti lọ sí tẹ́ńpìlì Jèhófà.

Ìrékọjá kì í ṣe àjọyọ̀ ọjọ́ kan ṣoṣo fún ìdílé Jósẹ́fù. Ọjọ́ tó tẹ̀ lé Ìrékọjá ni wọ́n máa ń bẹ̀rẹ̀ Àjọyọ̀ Búrẹ́dì Aláìwú, ọjọ́ méje ni wọ́n sì fi máa ń ṣe é. (Máàkù 14:1) Wọ́n gbà pé àjọyọ̀ yìí wà lára àjọyọ̀ Ìrékọjá. Ìrìn àjò yìí máa ń gbà wọ́n ní ọ̀sẹ̀ méjì ó kéré tán. Ìdí ni pé wọ́n máa rìn láti Násárẹ́tì dé Jerúsálẹ́mù, wọ́n máa lo ọjọ́ díẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì tún máa rìn pa dà sílé. Àmọ́ lọ́dún yìí, ohun tí Jésù ṣe mú kí wọ́n lò ju àkókò yẹn lọ. Ìgbà tí wọ́n ń pa dà sílé ni wọ́n kíyè sí i pé nǹkan kan ti ṣẹlẹ̀.

ÌRÌN ÀJÒ TÓ Ń MÚNÚ WỌN DÙN

Jósẹ́fù àti ìdílé rẹ̀ ń rìnrìn àjò lọ sí Jerúsálẹ́mù

Inú àwọn èèyàn máa ń dùn gan-an tí wọ́n bá ń rìnrìn àjò lọ sí Jerúsálẹ́mù fún àjọyọ̀ lẹ́ẹ̀mẹ́ta lọ́dún. (Diutarónómì 16:15) Nígbà ìrìn àjò yẹn, Jésù máa rí oríṣiríṣi ilẹ̀, á sì kẹ́kọ̀ọ́ nípa wọn. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún máa rí àwọn olùjọ́sìn Ọlọ́run tó wá láti ibòmíì. Ó dájú pé àwọn ìrìn àjò yẹn máa ń lárinrin gan-an!

Bí wọ́n ṣe ń pa dà sílé, Jósẹ́fù àti Màríà rò pé Jésù wà láàárín àwọn mọ̀lẹ́bí àtàwọn ọ̀rẹ́ tí wọ́n jọ ń rìnrìn àjò. Nígbà tí ilẹ̀ ṣú, wọ́n dúró láti wá ibì kan sùn, àmọ́ wọn ò rí Jésù. Wọ́n wá a láàárín gbogbo àwọn tí wọ́n jọ ń rìnrìn àjò, àmọ́ wọn ò rí i. Háà! Odindi ọmọ ló sọnù yìí! Bí Jósẹ́fù àti Màríà ṣe pa dà sí Jerúsálẹ́mù nìyẹn.

Odindi ọjọ́ kan ni wọ́n fi wá a, tí wọn ò sì rí i. Wọ́n tún wá a títí lọ́jọ́ kejì, síbẹ̀ wọn ò rí i. Àwọn gbọ̀ngàn tó wà nínú tẹ́ńpìlì yẹn pọ̀ gan-an, àmọ́ nígbà tí wọ́n wá a títí wọ́n rí i lọ́jọ́ kẹta. Wọ́n rí Jésù tó jókòó láàárín àwọn olùkọ́ Júù. Ó ń tẹ́tí sí wọn, ó sì ń béèrè ìbéèrè, kódà òye tó ní yà wọ́n lẹ́nu.

Jósẹ́fù àti Màríà rí Jésù

Màríà wá bi í pé: “Ọmọ, kí ló dé tí o fi ṣe báyìí sí wa? Wò ó, èmi àti bàbá rẹ ti dààmú gan-an bá a ṣe ń wá ọ kiri.”—Lúùkù 2:48.

Ó ya Jésù lẹ́nu pé wọn ò mọ ibi tí òun wà. Ó bi wọ́n pé: “Kí ló dé tí ẹ̀ ń wá mi? Ṣé ẹ ò mọ̀ pé mo gbọ́dọ̀ wà nínú ilé Baba mi ni?”—Lúùkù 2:49.

Ní báyìí tí Jósẹ́fù àti Màríà ti rí Jésù, wọ́n jọ pa dà sí Násárẹ́tì, Jésù sì ń gbọ́ràn sí wọn lẹ́nu. Bó ṣe ń dàgbà sí i, bẹ́ẹ̀ lọgbọ́n rẹ̀ ń pọ̀ sí i. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ṣì kéré, ó ń rí ojúure Ọlọ́run àti èèyàn. Kò sí àní-àní pé láti kékeré ni Jésù ti ń fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ ní ti pé ó fọwọ́ pàtàkì mú ìjọsìn Ọlọ́run, ó sì ń bọ̀wọ̀ fáwọn òbí rẹ̀.

  • Ibo ni Jósẹ́fù àti ìdílé rẹ̀ máa ń rìnrìn àjò lọ nígbà ìrúwé, kí sì nìdí?

  • Nígbà tí Jésù wà lọ́mọ ọdún méjìlá, kí ni Jósẹ́fù àti Màríà kíyè sí bí wọ́n ṣe ń pa dà sílé láti Jerúsálẹ́mù, kí ló wá ṣẹlẹ̀?

  • Àpẹẹrẹ wo ni Jésù fi lélẹ̀ fáwọn ọ̀dọ́ lónìí?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́