ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • jy orí 13 ojú ìwé 36-ojú ìwé 37 ìpínrọ̀ 6
  • Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Bí Jésù Ṣe Kojú Àdánwò

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Bí Jésù Ṣe Kojú Àdánwò
  • Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kikẹkọọ Lati Inu Awọn Ìdẹwò Jesu
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
  • A Gbọ́dọ̀ Kọ Ìdẹwò
    Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà
  • “Ẹ Kọ Ojú Ìjà sí Èṣù” bí Jésù Ti Ṣe
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Èṣù Dán Jésù Wò
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
Àwọn Míì
Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
jy orí 13 ojú ìwé 36-ojú ìwé 37 ìpínrọ̀ 6
Jésù kọ àwọn ìdẹwò Èṣù

ORÍ 13

Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Bí Jésù Ṣe Kojú Àdánwò

MÁTÍÙ 4:1-11 MÁÀKÙ 1:12, 13 LÚÙKÙ 4:1-13

  • SÁTÁNÌ DÁN JÉSÙ WÒ

Kété lẹ́yìn tí Jòhánù ṣèrìbọmi fún Jésù, ẹ̀mí Ọlọ́run darí Jésù lọ sínú aginjù Jùdíà. Ọ̀pọ̀ nǹkan ló máa wà lọ́kàn Jésù. Ká rántí pé “ọ̀run ṣí sílẹ̀” nígbà tó ṣèrìbọmi. (Mátíù 3:16) Torí náà, á rántí àwọn ohun tó ti kọ́ àtàwọn nǹkan tó ti ṣe ní ọ̀run. Kò sí àní-àní pé ọ̀pọ̀ nǹkan ló ń ronú lé!

Ogójì (40) ọ̀sán àti ogójì òru ni Jésù lò nínú aginjù. Ní gbogbo àkókò yẹn, kò jẹ nǹkan kan. Nígbà tó yá, ebi bẹ̀rẹ̀ sí í pa á gan-an, ni Sátánì Èṣù bá wá kó lè dán an wò. Sátánì sọ pé: “Tí o bá jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, sọ fún àwọn òkúta yìí pé kí wọ́n di búrẹ́dì.” (Mátíù 4:3) Jésù mọ̀ pé kò yẹ kí òun lo agbára tóun ní láti fi tẹ́ ara òun lọ́rùn, torí náà, kò ṣe ohun tí Sátánì sọ.

Àmọ́ Èṣù ò fi mọ síbẹ̀. Ó dá ọgbọ́n míì. Ó ní kí Jésù bẹ́ sílẹ̀ látorí ògiri orí òrùlé tẹ́ńpìlì. Àmọ́ Jésù ò ṣe bẹ́ẹ̀, torí ṣekárími nìyẹn máa jẹ́. Jésù wá lo ọ̀rọ̀ inú Ìwé Mímọ́ tó jẹ́ kó ṣe kedere pé kò yẹ kéèyàn dán Ọlọ́run wò.

Èṣù tún dán Jésù wò lẹ́ẹ̀kẹta, lọ́nà kan ó fi “gbogbo ìjọba ayé àti ògo wọn” han Jésù, ó sì sọ pé: “Gbogbo nǹkan yìí ni màá fún ọ tí o bá wólẹ̀, tí o sì jọ́sìn mi lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.” Jésù tún kọ̀ jálẹ̀, ó ní: “Kúrò lọ́dọ̀ mi, Sátánì!” (Mátíù 4:8-10) Jésù ò jẹ́ kí Èṣù sún òun láti ṣe ohun tí kò tọ́, ó mọ̀ pé Jèhófà nìkan ṣoṣo ló yẹ ká jọ́sìn. Láìsí àní-àní, Jésù ti pinnu pé òun máa jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run.

Àwọn nǹkan kan wà tá a lè kọ́ látinú àwọn ìdẹwò yìí àti ohun tí Jésù ṣe. Ti pé Èṣù dán Jésù wò fi hàn pé Èṣù wà lóòótọ́, kì í wulẹ̀ ṣe èrò ibi kan lásán báwọn kan ṣe rò. Ẹni gidi ni bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò lè rí i. Àkọsílẹ̀ yìí tún jẹ́ ká rí i pé ìkáwọ́ Èṣù ni àwọn ìjọba ayé yìí wà, òun ló sì ń darí wọn. Àbí, ká sọ pé òun kọ́ ló ni wọ́n, ṣé á lè fi dẹ Jésù wò? Ó dájú pé kò ní ṣe bẹ́ẹ̀.

Ohun míì ni pé, Èṣù ní òun máa fún Jésù lóhun tó pọ̀ tó bá jọ́sìn òun lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, ó bá a débi pé ó fẹ́ fún Jésù ní gbogbo ìjọba ayé. Èṣù lè fi irú ẹ̀ dán àwa náà wò, ó lè fẹ́ ká lọ́wọ́ sí àwọn nǹkan kan tó lè mú ká lówó rẹpẹtẹ, ká lókìkí tàbí ká lẹ́nu láwùjọ. A máa fi hàn pé ọlọ́gbọ́n ni wá tá a bá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, tá a jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run láìka àdánwò yòówù ká kojú sí! Àmọ́, ẹ má gbàgbé pé Èṣù ò fi Jésù sílẹ̀ pátápátá o, ṣe ló kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ “títí di ìgbà míì tó wọ̀.” (Lúùkù 4:13) Ó lè ṣe bẹ́ẹ̀ fún àwa náà, ìdí nìyẹn tí kò fi yẹ ká túra sílẹ̀ nígbà kankan.

  • Àwọn nǹkan wo ló ṣeé ṣe kí Jésù máa ronú lé nígbà tó wà nínú aginjù fún ogójì (40) ọjọ́?

  • Báwo ni Èṣù ṣe dán Jésù wò?

  • Kí la rí kọ́ látinú àwọn àdánwò náà àti bí Jésù ṣe kojú wọn?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́