Ẹ̀KỌ́ 75
Èṣù Dán Jésù Wò
Lẹ́yìn tí Jésù ṣèrìbọmi, ẹ̀mí mímọ́ darí ẹ̀ lọ sí aginjù. Jésù ò jẹ nǹkan kan fún ogójì (40) ọjọ́, ebi wá ń pa á gan-an. Bí Èṣù ṣe wá dán an wò nìyẹn, ó sọ fún Jésù pé: ‘Tó bá jẹ́ pé Ọmọ Ọlọ́run ni ẹ́ lóòótọ́, sọ fáwọn òkúta yìí pé kí wọ́n di búrẹ́dì.’ Àmọ́, Jésù fi ohun tó wà nínú Ìwé Mímọ́ dá a lóhùn, ó sọ pé: ‘A ti kọ ọ́ pé kì í ṣe oúnjẹ nìkan ló máa jẹ́ ká wà láàyè. A gbọ́dọ̀ máa fetí sí gbogbo ohun tí Jèhófà bá sọ.’
Lẹ́yìn ìyẹn, Èṣù tún sọ fún un pé: ‘Tó o bá jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run lóòótọ́, bẹ́ sílẹ̀ láti ibi tó ga jù ní tẹ́ńpìlì yìí. Torí a ti kọ ọ́ pé Ọlọ́run á rán àwọn áńgẹ́lì ẹ̀ láti gbé ọ, kó o má bàa ṣubú.’ Jésù tún fi Ìwé Mímọ́ dá a lóhùn, ó sọ pé: ‘A ti kọ ọ́ pé, o ò gbọ́dọ̀ dán Jèhófà Ọlọ́run rẹ wò.’
Lẹ́yìn ìyẹn, Sátánì tún fi gbogbo ìjọba ayé yìí han Jésù, àti gbogbo ọrọ̀ àti ògo tó wà láyé, ó wá sọ fún un pé: ‘Màá fún ẹ ní gbogbo nǹkan yìí tó o bá jọ́sìn mi lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.’ Jésù wá sọ fún Sátánì pé: ‘Kúrò lọ́dọ̀ mi, Sátánì! Torí a ti kọ ọ́ pé, Jèhófà Ọlọ́run nìkan lo gbọ́dọ̀ jọ́sìn.’
Èṣù kúrò lọ́dọ̀ Jésù, lẹ́yìn náà àwọn áńgẹ̀lì wá sọ́dọ̀ Jésù, wọ́n sì fún un lóúnjẹ. Látìgbà yẹn ni Jésù ti ń wàásù ìhìn rere nípa Ìjọba Ọlọ́run. Iṣẹ́ tí Jèhófà ní kí Jésù wá ṣe láyé nìyẹn. Àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ ẹ̀kọ́ tí Jésù ń kọ́ wọn, torí náà gbogbo ibi tí Jésù bá ń lọ làwọn èèyàn máa ń tẹ̀ lé e lọ.
‘Tí Èṣù bá ń pa irọ́, ṣe ló ń sọ irú ẹni tí òun fúnra rẹ̀ jẹ́, torí pé òpùrọ́ ni, òun sì ni baba irọ.’—Jòhánù 8:44