ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • jy orí 15 ojú ìwé 40-ojú ìwé 41 ìpínrọ̀ 6
  • Jésù Ṣe Iṣẹ́ Ìyanu Àkọ́kọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jésù Ṣe Iṣẹ́ Ìyanu Àkọ́kọ́
  • Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Iṣẹ Iyanu Akọkọ Ti Jesu Ṣe
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
  • Iṣẹ́ Ìyanu Kejì ní Kánà
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Iṣẹ Iyanu Keji ni Kana
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
Àwọn Míì
Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
jy orí 15 ojú ìwé 40-ojú ìwé 41 ìpínrọ̀ 6
Níbi àsè ìgbéyàwó kan ní Kánà, Jésù sọ fún àwọn ìránṣẹ́ tó ń pín jíjẹ mímu pé kí wọ́n pọn omi kún inú àwọn ìṣà

ORÍ 15

Jésù Ṣe Iṣẹ́ Ìyanu Àkọ́kọ́

JÒHÁNÙ 2:1-12

  • ÌGBÉYÀWÓ TÓ WÁYÉ NÍ KÁNÀ

  • JÉSÙ SỌ OMI DI WÁÌNÌ

Ó ti pé ọjọ́ mẹ́ta báyìí tí Nàtáníẹ́lì ti di ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn tí Jésù kọ́kọ́ ní. Díẹ̀ lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tẹ̀ lé e lọ sí agbègbè Gálílì, nílùú ìbílẹ̀ wọn. Ìlú Kánà ni wọ́n ń lọ, ìyẹn ìlú ìbílẹ̀ Nàtáníẹ́lì. Àárín àwọn òkè lápá àríwá Násárẹ́tì tí Jésù dàgbà sí ni Kánà wà. Kí ni wọ́n fẹ́ lọ ṣe ní Kánà? Wọ́n pè wọ́n síbi àsè ìgbéyàwó kan níbẹ̀ ni.

Màríà ìyá Jésù náà wá síbi ìgbéyàwó yẹn. Torí pé ọ̀rẹ́ ni Màríà jẹ́ sí ìdílé àwọn tó ń ṣègbéyàwó, ó ṣeé ṣe kó wà lára àwọn tó ń bójú tó àwọn àlejò rẹpẹtẹ tó wà níbẹ̀. Ìdí nìyẹn tó fi tètè kíyè sí i pé wáìnì ti fẹ́ tán. Ló bá pe Jésù, ó sì sọ fún un pé: “Wọn ò ní wáìnì kankan.”—Jòhánù 2:3.

Ṣe ni Màríà ń dọ́gbọ́n sọ fún Jésù pé kó bá wọn wá nǹkan ṣe sí wáìnì tí ò tó yẹn. Jésù fi àkànlò èdè kan dá ìyá rẹ̀ lóhùn láti fi hàn pé òun ò fara mọ́ ohun tó sọ, ó ní: “Obìnrin yìí, báwo ni ìyẹn ṣe kan èmi àti ìwọ?” (Jòhánù 2:4) Jésù ni Ọba tí Ọlọ́run yàn, torí náà, Baba rẹ̀ ọ̀run ló yẹ kó máa darí ohun tó ń ṣe, kì í ṣe àwọn mọ̀lẹ́bí tàbí ọ̀rẹ́. Màríà hùwà ọgbọ́n, ó sì fi ọmọ rẹ̀ sílẹ̀, ó wá sọ fún àwọn ìránṣẹ́ tó ń pín jíjẹ mímu pé: “Ẹ ṣe ohunkóhun tó bá ní kí ẹ ṣe.”—Jòhánù 2:5.

Ìṣà tàbí ìkòkò omi mẹ́fà tí wọ́n fi òkúta ṣe wà níbẹ̀, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan máa gbà ju gálọ́ọ̀nù omi mẹ́wàá lọ. Jésù sọ fún àwọn ìránṣẹ́ tó ń pín jíjẹ mímu pé: “Ẹ pọn omi kún inú àwọn ìṣà náà.” Ó wá sọ pé: “Ó yá, ẹ bu díẹ̀, kí ẹ sì gbé e lọ fún alága àsè.”—Jòhánù 2:7, 8.

Alága àsè ìgbéyàwó náà gbóríyìn fún ọkọ ìyàwó torí bí wáìnì náà ṣe dáa tó

Ó wú alága náà lórí pé wáìnì yẹn dáa gan-an, àmọ́ kò mọ̀ pé ọ̀nà ìyanu ni wáìnì náà gbà jáde. Ó pe ọkọ ìyàwó, ó sì sọ pé: “Wáìnì tó dáa ni gbogbo èèyàn máa ń kọ́kọ́ gbé jáde, tí àwọn èèyàn bá sì ti yó, wọ́n á gbé gbàrọgùdù jáde. Wáìnì tó dáa lo gbé pa mọ́ títí di àkókò yìí.”—Jòhánù 2:10.

Iṣẹ́ ìyanu tí Jésù kọ́kọ́ ṣe nìyí. Nígbà tí àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ rí iṣẹ́ ìyanu yìí, ìgbàgbọ́ wọn túbọ̀ lágbára. Lẹ́yìn náà, Jésù, ìyá rẹ̀, àtàwọn àbúrò rẹ̀ rìnrìn àjò lọ sílùú Kápánáúmù tó wà ní bèbè Òkun Gálílì.

  • Ìgbà wo ni Jésù ṣe iṣẹ́ ìyanu àkọ́kọ́?

  • Kí ni Jésù sọ nígbà tí ìyá rẹ̀ sọ pé kó wá nǹkan ṣe sí wáìnì tí ò tó?

  • Iṣẹ́ ìyanu wo ni Jésù ṣe, báwo ló sì ṣe rí lára àwọn míì?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́