ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • jy orí 20 ojú ìwé 54-ojú ìwé 55 ìpínrọ̀ 8
  • Iṣẹ́ Ìyanu Kejì ní Kánà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Iṣẹ́ Ìyanu Kejì ní Kánà
  • Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Iṣẹ Iyanu Keji ni Kana
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
  • Jésù Ṣe Iṣẹ́ Ìyanu Àkọ́kọ́
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Iṣẹ Iyanu Akọkọ Ti Jesu Ṣe
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
  • Àsọtẹ́lẹ̀ Nípa Mèsáyà Tó Ní Ìmúṣẹ
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2016)
Àwọn Míì
Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
jy orí 20 ojú ìwé 54-ojú ìwé 55 ìpínrọ̀ 8
Òṣìṣẹ́ kan tó ń ṣọ̀fọ̀ ń bẹ Jésù pé kó wá wo ọmọ òun sàn

ORÍ 20

Iṣẹ́ Ìyanu Kejì ní Kánà

MÁÀKÙ 1:14, 15 LÚÙKÙ 4:14, 15 JÒHÁNÙ 4:43-54

  • JÉSÙ Ń WÀÁSÙ PÉ ‘ÌJỌBA ỌLỌ́RUN TI SÚN MỌ́LÉ’

  • Ó WO ỌMỌDÉKÙNRIN KAN SÀN LÁTI Ọ̀NÀ JÍJÌN

Lẹ́yìn tí Jésù lo nǹkan bí ọjọ́ méjì ní Samáríà, ó pa dà sí ìlú rẹ̀. Ó ti wàásù gan-an ní Jùdíà, àmọ́ kì í ṣe torí pé ó fẹ́ sinmi ló fi pa dà sílùú rẹ̀. Iṣẹ́ ìwàásù ló tún fẹ́ lọ ṣe níbẹ̀, èyí sì máa ṣàrà ọ̀tọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lo. Ó ṣeé ṣe kí Jésù ti mọ̀ pé wọn ò ní gba òun tọwọ́ tẹsẹ̀, ó ṣe tán, òun náà ló sọ pé “wòlíì kì í gbayì ní ìlú rẹ̀.” (Jòhánù 4:44) Dípò káwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ dúró tì í, ṣe ni wọ́n pa dà sí ilé wọn, tí wọ́n sì ń bá iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wọn lọ.

Kí ni ìwàásù Jésù dá lé? Ó ń kọ́ni pé: ‘Ìjọba Ọlọ́run ti sún mọ́lé. Ẹ ronú pìwà dà, kí ẹ sì ní ìgbàgbọ́ nínú ìhìn rere.’ (Máàkù 1:15) Kí làwọn èèyàn wá ṣe lẹ́yìn tí wọ́n gbọ́ ìhìn rere náà? Ọ̀pọ̀ lára àwọn ará Gálílì tẹ́wọ́ gba Jésù, wọ́n sì bọlá fún un. Kì í ṣe torí ìwàásù rẹ̀ nìkan ni wọ́n fi ṣe bẹ́ẹ̀. Ìdí míì ni pé àwọn ará Gálílì kan wà níbi Ìrékọjá tí wọ́n ṣe ní Jerúsálẹ́mù ní oṣù díẹ̀ sẹ́yìn, wọ́n sì rí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe.—Jòhánù 2:23.

Ibo gan-an ni Jésù ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù àrà ọ̀tọ̀ yìí ní Gálílì? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ní Kánà, níbi tó ti sọ omi di wáìnì níbi ìgbéyàwó kan. Ẹ̀ẹ̀kejì tí Jésù lọ síbẹ̀ nìyí, ó gbọ́ pé ọmọ kan ń ṣàìsàn, àìsàn náà sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ gbẹ̀mí rẹ̀. Ọmọ òṣìṣẹ́ Ọba Hẹ́rọ́dù Áńtípà ni, ìyẹn ọba tó pa Jòhánù Arinibọmi. Òṣìṣẹ́ ọba yìí gbọ́ pé Jésù ti kúrò ní Jùdíà wá sí Kánà. Torí náà, ó gbéra kúrò nílé ẹ̀ ní Kápánáúmù láti lọ wá Jésù ní Kánà. Ọkùnrin tó ń ṣọ̀fọ̀ náà sọ fún Jésù pé: “Olúwa, sọ̀ kalẹ̀ wá kí ọmọ mi kékeré tó kú.”—Jòhánù 4:49.

Ó ṣeé ṣe kí ohun tí Jésù sọ ya ọkùnrin náà lẹ́nu, Jésù ní: “Máa lọ; ọmọ rẹ ti yè.” (Jòhánù 4:50) Òṣìṣẹ́ ọba yìí gba Jésù gbọ́, ó sì pa dà sílé. Bó ṣe ń lọ, ó pàdè àwọn ẹrú ẹ̀ tí wọ́n ń bọ̀ wá bá a yọ̀. Wọ́n sọ fún un pé ara ọmọ ẹ̀ ti yá, pé kò kú mọ́! Ó wá bi wọ́n pé, ‘Ìgbà wo ni ara rẹ̀ yá?’ torí ó fẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà yé òun dáadáa.

Wọ́n dáhùn pé: “Wákàtí keje ni ibà náà fi í sílẹ̀ lánàá.”—Jòhánù 4:52.

Òṣìṣẹ́ náà pàdé àwọn ẹrú rẹ̀ lọ́nà, nígbà tó sì délé ó rí i pé Jésù ti wo ọmọ òun sàn

Ọkùnrin yẹn wá mọ̀ pé ìgbà tí Jésù sọ pé: “Ọmọ rẹ ti yè” gangan ni ara ọmọ òun yá. Lẹ́yìn ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn, ọkùnrin yẹn àti agbo ilé rẹ̀ di ọmọlẹ́yìn Jésù.

Iṣẹ́ ìyanu méjì ni Jésù ṣe ní Kánà. Ó sọ omi di wáìnì, ó sì mú ọmọdékùnrin kan lára dá láti nǹkan bíi máìlì mẹ́rìndínlógún (16) síbi tọ́mọ náà wà. Kì í ṣe iṣẹ́ ìyanu méjì yìí nìkan ni Jésù ṣe, àmọ́ ti ọmọ tó wò sàn yẹn ṣàrà ọ̀tọ̀ torí ó jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé ó ti pa dà sí Gálílì. Ó dájú pé wòlíì Ọlọ́run ni Jésù. Àmọ́, báwo ni ‘wòlíì yìí ṣe máa gbayì tó ní ìlú rẹ̀?’

A máa rí ìdáhùn sí ìbéèrè yẹn nígbà tí Jésù bá lọ sí ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀ ní Násárẹ́tì. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí i níbẹ̀?

  • Kí ni Jésù ń wàásù nígbà tó pa dà sí Gálílì, kí làwọn èèyàn ṣe lẹ́yìn tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀?

  • Iṣẹ́ ìyanu míì wo ni Jésù ṣe ní Kánà, kí ló sì yọrí sí?

  • Kí ló ṣàrà ọ̀tọ̀ nípa bí Jésù ṣe wo ọmọ kan sàn ní Kápánáúmù?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́