ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • jy orí 28 ojú ìwé 70-ojú ìwé 71 ìpínrọ̀ 6
  • Kí Nìdí Tí Àwọn Ọmọlẹ́yìn Jésù Kò Fi Gbààwẹ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Nìdí Tí Àwọn Ọmọlẹ́yìn Jésù Kò Fi Gbààwẹ̀?
  • Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • A Bi Í Leere Nipa Ààwẹ̀
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
  • Ṣé Ààwẹ̀ Gbígbà Ló Máa Jẹ́ Kó O Sún Mọ́ Ọlọ́run?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ààwẹ̀?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Gbígbààwẹ̀ Ha Ti Di Aláìbágbàmu Bí?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
Àwọn Míì
Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
jy orí 28 ojú ìwé 70-ojú ìwé 71 ìpínrọ̀ 6
Àwọn ọmọlẹ́yìn Jòhánù bi Jésù nípa ààwẹ̀

ORÍ 28

Kí Nìdí Tí Àwọn Ọmọlẹ́yìn Jésù Kò Fi Gbààwẹ̀?

MÁTÍÙ 9:14-17 MÁÀKÙ 2:18-22 LÚÙKÙ 5:33-39

  • ÀWỌN ỌMỌLẸ́YÌN JÒHÁNÙ TỌ JÉSÙ LỌ, WỌ́N SÌ BÉÈRÈ ÌDÍ TÍ ÀWỌN ỌMỌ Ẹ̀YÌN TIẸ̀ KÒ FI GBÀÀWẸ̀

Kò pẹ́ lẹ́yìn tí Jésù lọ sí Ìrékọjá tí wọ́n ṣe lọ́dún 30 S. K. ni wọ́n ju Jòhánù Arinibọmi sẹ́wọ̀n. Jòhánù fẹ́ kí àwọn ọmọlẹ́yìn òun máa tẹ̀ lé Jésù, àmọ́ kì í ṣe gbogbo wọn ló ṣe bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ju Jòhánù sẹ́wọ̀n.

Bí Ìrékọjá ọdún 31 S.K. ṣe ń sún mọ́lé, àwọn ọmọlẹ́yìn Jòhánù kan wá bá Jésù, wọ́n bi í pé: “Kí ló dé tí àwa àti àwọn Farisí máa ń gbààwẹ̀ àmọ́ tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ kì í gbààwẹ̀?” (Mátíù 9:14) Ìdí sì ni pé àwọn Farisí ti sọ ààwẹ̀ di apá pàtàkì nínú ìjọsìn wọn. Nígbà tó yá, Jésù sọ àpèjúwe nípa Farisí kan tó jẹ́ olódodo lójú ara rẹ̀, tó wá ń gbàdúrà pé: “Ọlọ́run, mo dúpẹ́ pé mi ò dà bíi gbogbo àwọn èèyàn yòókù . . . Ẹ̀ẹ̀mejì lọ́sẹ̀ ni mò ń gbààwẹ̀.” (Lúùkù 18:11, 12) Ó ṣeé ṣe kí àwọn ọmọlẹ́yìn Jòhánù náà ti sọ ààwẹ̀ gbígbà dàṣà tàbí kí wọ́n máa gbààwẹ̀ láti fi ṣọ̀fọ̀ Jòhánù tí wọ́n jù sẹ́wọ̀n. Àwọn kan tiẹ̀ lè máa ronú pé kí nìdí tí àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù kò fi gbààwẹ̀ torí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jòhánù.

Jésù fi àpèjúwe kan dá wọn lóhùn, ó ní: “Kò sí ohun tó máa mú kí àwọn ọ̀rẹ́ ọkọ ìyàwó ṣọ̀fọ̀ tí ọkọ ìyàwó bá ṣì wà lọ́dọ̀ wọn, àbí ó wà? Àmọ́ ọjọ́ ń bọ̀, tí a máa mú ọkọ ìyàwó kúrò lọ́dọ̀ wọn, wọ́n máa wá gbààwẹ̀.”—Mátíù 9:15.

Jòhánù fúnra rẹ̀ tiẹ̀ pe Jésù ní ọkọ ìyàwó. (Jòhánù 3:28, 29) Ìdí nìyẹn tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù kò fi gbààwẹ̀ nígbà tí Jésù wà pẹ̀lú wọn. Tí Jésù bá wá kú, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ á ṣọ̀fọ̀, wọn ò sì ní lè jẹun. Àmọ́ tó bá jíǹde, kò ní sídìí fún wọn láti máa gbààwẹ̀ tàbí ṣọ̀fọ̀ mọ́.

Lẹ́yìn ìyẹn Jésù sọ àpèjúwe méjì yìí: “Kò sí ẹni tó máa rán ègé aṣọ tí kò tíì sún kì mọ́ ara aṣọ àwọ̀lékè tó ti gbó, torí aṣọ tuntun náà máa ya kúrò lára aṣọ àwọ̀lékè náà, ó sì máa ya ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Àwọn èèyàn kì í sì í rọ wáìnì tuntun sínú àpò awọ tó ti gbó. Tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, àpò náà máa bẹ́, wáìnì á dà nù, àpò náà á sì bà jẹ́. Àmọ́ inú àpò awọ tuntun ni àwọn èèyàn máa ń rọ wáìnì tuntun sí.” (Mátíù 9:16, 17) Kí ni Jésù ní lọ́kàn?

Jésù fẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn Jòhánù mọ̀ pé kò sídìí táwọn ọmọ ẹ̀yìn òun á fi máa gbààwè bíi tàwọn Júù. Jésù ò fọwọ́ sí ìjọsìn wọn torí ó mọ̀ pé oríṣiríṣi àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ni wọ́n ti mú wọnú ẹ̀. Kò sì wá láti ṣàtúnṣe sí i, torí ó mọ̀ pé kò ní pẹ́ kógbá sílé. Jésù ò fẹ́ rán aṣọ tuntun mọ́ aṣọ tó ti gbó, kò sì fẹ́ da wáìnì tuntun sínú àpò awọ tó ti bà jẹ́.

ÀPÈJÚWE NÍPA ÀÀWẸ̀

Àpò awọ

Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ lórí kókó yìí, ó lo àpèjúwe aṣọ rírán torí ó mọ̀ pé ó máa tètè yé àwọn tó ń tẹ́tí sí òun. Ká sọ pé ẹnì kan rán aṣọ tuntun mọ́ aṣọ àlòkù tó ti gbó, kí ló máa ṣẹlẹ̀? Tí wọ́n bá fọ aṣọ náà, ó máa mú kí aṣọ àlòkù yẹn sún kì, kó sì ya.

Bákan náà, nígbà míì wọ́n máa ń rọ wáìnì sínú àpò awọ tí wọ́n fi awọ ẹran ṣe. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, awọ yẹn á gan, kò sì ní lè fẹ̀ mọ́. Irú àpò awọ bẹ́ẹ̀ lè fàya téèyàn bá rọ wáìnì tuntun sínú ẹ̀. Ìdí sì ni pé bí wáìnì tuntun yẹn ṣe ń kan, bẹ́ẹ̀ lá máa mú atẹ́gùn jáde. Awọ tó ti gan náà lè bẹ́ torí pé kò sí ibi tí atẹ́gùn lè dúró sí nínú ẹ̀ mọ́.

  • Àwọn wo ló ń gbààwẹ̀ nígbà ayé Jésù, kí sì nìdí?

  • Kí nìdí tí àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù kò fi gbààwẹ̀ nígbà tó wà pẹ̀lú wọn, àmọ́ kí ló lè mú kí wọ́n gbààwẹ̀ tó bá yá?

  • Kí ni ìtumọ̀ àpèjúwe tí Jésù ṣe nípa aṣọ tuntun àti wáìnì tuntun?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́