ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 11/15 ojú ìwé 3-4
  • Gbígbààwẹ̀ Ha Ti Di Aláìbágbàmu Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Gbígbààwẹ̀ Ha Ti Di Aláìbágbàmu Bí?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Irin Iṣẹ́ àti Ààtò Ìsìn
  • Ṣé Ààwẹ̀ Gbígbà Ló Máa Jẹ́ Kó O Sún Mọ́ Ọlọ́run?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ààwẹ̀?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ọlọ́run Ha Béèrè Gbígbààwẹ̀ Bí?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • A Bi Í Leere Nipa Ààwẹ̀
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 11/15 ojú ìwé 3-4

Gbígbààwẹ̀ Ha Ti Di Aláìbágbàmu Bí?

MRUDULABEN, obìnrin kan tí ó jẹ́ ará Íńdíà, tí ó jẹ́ ẹni ọdún 78, tí ó sì láásìkí sọ pé: “Láti ìgbà tí mo ti wà ní ọ̀dọ́langba ni mo ti máa ń gbààwẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ Monday.” Èyí ti jẹ́ apá kan ìjọsìn rẹ̀, ọ̀nà kan láti rí i dájú pé ìgbéyàwó rẹ̀ yọrí sí rere, kí àwọn ọmọ rẹ̀ máa ta kébékébé, kí ààbò sì wà fún ọkọ rẹ̀. Nísinsìnyí tí ó ti di opó, ó ń bá a nìṣó láti máa gbààwẹ̀ ní ọjọọjọ́ Monday fún ìlera tí ó dára àti fún aásìkí àwọn ọmọ rẹ̀. Bíi tirẹ̀, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn obìnrin tí wọ́n jẹ́ onísìn Híńdù sọ gbígbààwẹ̀ déédéé di apá kan ìgbésí ayé wọn.

Prakash, ọkùnrin oníṣòwò kan, tí ó wà ní àárín gbùngbùn ìgbésí ayé rẹ̀, tí ó ń gbé ní àdúgbò ẹ̀yìn odi ìlú Mumbai (Bombay), ní Íńdíà, sọ pé òún máa ń gbààwẹ̀ lọ́dọọdún ní ọjọọjọ́ Monday nínú oṣù Sawan (Shravan). Èyí jẹ́ oṣù kan tí ó ní ìjẹ́pàtàkì àrà ọ̀tọ̀ ní ti ìsìn, lórí kàlẹ́ńdà àwọn Híńdù. Prakash ṣàlàyé pé: “Mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí ìdí tí ó jẹ́ ti ìsìn, ṣùgbọ́n nísinsìnyí mo wá rí ohun mìíràn tí ń gún mi ní kẹ́ṣẹ́ láti máa bá a nìṣó nítorí ìlera. Níwọ̀n bí oṣù Sawan ti wà ní apá ìparí ìgbà òjò, ó máa ń fún ètò ìṣiṣẹ́ ara mi ní àǹfààní láti gba ara rẹ̀ lọ́wọ́ àwọn àmódi tí ó máa ń bá ìgbà òjò rìn.”

Àwọn kan rò pé gbígbààwẹ̀ ń ṣàǹfààní fún ẹnì kan nípa ti ara, ní ti èrò orí, àti nípa tẹ̀mí. Fún àpẹẹrẹ, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, Grolier International Encyclopedia, wí pé: “Ìwádìí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ tí a ṣe láìpẹ́ yìí fi hàn pé gbígbààwẹ̀ lè ṣàǹfààní fún ìlera, nígbà tí a bá sì fara balẹ̀ gbà á, ó lè yọrí sí òye àti èrò ìmọ̀lára, tí ó túbọ̀ jí pépé.” A mẹ́nu kàn án pé ọlọ́gbọ́n èrò orí tí ó jẹ́ Gíríìkì, Plato, máa ń gbààwẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́wàá tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ àti pé onímọ̀ ìṣirò náà, Pythagoras, máa ń mú kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ gbààwẹ̀ kí ó tó kọ́ wọn.

Lójú àwọn kan, gbígbààwẹ̀ túmọ̀ sí ṣíṣàìfẹnu kan oúnjẹ àti omi fún sáà kan pàtó, nígbà tí ó sì jẹ́ pé àwọn mìíràn máa ń wá nǹkan mu tí wọ́n bá ń gbààwẹ̀. Ọ̀pọ̀ ka fífo àkókò oúnjẹ kan tàbí fífà sẹ́yìn kúrò nínú jíjẹ irú oúnjẹ kan ní pàtó sí gbígbààwẹ̀. Ṣùgbọ́n gbígbààwẹ̀ fún ìgbà pípẹ́ láìsí àbójútó léwu. Akọ̀ròyìn, Parul Sheth, sọ pé, lẹ́yìn tí ará bá ti fa ìpèsè èròjà carbohydrate tí ó ní ní ìpamọ́ mu tán, yóò bẹ̀rẹ̀ sí í yí èròjà protein tí ó wà nínú iṣan padà sí èròjà glucose, lẹ́yìn náà, yóò wá bẹ̀rẹ̀ sí í fa ọ̀rá inú ara mu. Yíyí ọ̀rá padà sí èròjà glucose máa ń mú àwọn èròjà onímájèlé tí à ń pè ní omiró ketone jáde. Bí àwọn wọ̀nyí bá ti ń kóra jọ, wọn yóò wọ́ lọ sínú ọpọlọ, ní ṣíṣèpalára fún ìgbékalẹ̀ ọpọlọ. Sheth wí pé: “Ìgbà yìí ni gbígbààwẹ̀ lè léwu. Ọkàn rẹ lè pòrúurùu, ọkàn rẹ lè dàrú, ó sì tún lè burú jù bẹ́ẹ̀ lọ. . . . [Ó lè fa] dídákú àti ikú lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.”

Irin Iṣẹ́ àti Ààtò Ìsìn

A ti lo gbígbààwẹ̀ gẹ́gẹ́ bí irin iṣẹ́ lílágbára fún ète ìṣèlú tàbí ti ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà. Mohandas K. Gandhi ní Íńdíà jẹ́ ẹni tí ó gbajúmọ̀ nínú lílo irin iṣẹ́ yìí. Níwọ̀n bí ọgọ́rọ̀ọ̀rún àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn ti gbé e gẹ̀gẹ̀ gidigidi, ó lo gbígbààwẹ̀ láti lo agbára ìdarí lílágbára lórí àwùjọ onísìn Híńdù tí wọ́n jẹ́ ará Íńdíà. Nígbà tí ó ń ṣàpèjúwe àbájáde ààwẹ̀ tí òún gbà láti yanjú awuyewuye ní ilé iṣẹ́, tí ó ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn òṣìṣẹ́ ilé iṣẹ́ àti àwọn tí ó ni ilé iṣẹ́, Gandhi sọ pé: “Àbárèbábọ̀ rẹ̀ ni pé, ipò àyíká onífẹ̀ẹ́ inú rere wáyé láàárín gbogbo àwọn tí ọ̀rán kàn. Ọkàn àwọn onílé iṣẹ́ náà rọ̀ wọ̀ọ̀ . . . A kásẹ̀ ìyanṣẹ́lódì náà nílẹ̀ lẹ́yìn tí mo ti gbààwẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta péré.” Ààrẹ orílẹ̀-èdè Gúúsù Áfíríkà, Nelson Mandela, kópa nínú ìyan-oúnjẹ-lódì ọlọ́jọ́ márùn-ún ní àwọn ọdún tí ó lò gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́wọ̀n ìṣèlú.

Ṣùgbọ́n, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tí wọ́n ti sọ gbígbààwẹ̀ dàṣà tí ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí àwọn ìdí tí ó jẹ́ ti ìsìn. Gbígbààwẹ̀ jẹ́ ààtò tí ó gbajúmọ̀ nínú ìsìn Híńdù. Ìwé náà, Fast and Festivals of India, sọ pé, ní àwọn ọjọ́ kan pàtó, “a máa ń gbààwẹ̀ bíríbírí . . . kódà a kì í fẹnu kan omi rárá. Tọkùnrin tobìnrin ni ó máa ń gbààwẹ̀ ní ti gidi . . . láti lè ní ìdánilójú pé wọn yóò láyọ̀, pé wọn yóò láásìkí àti pé a óò dárí ìrékọjá òun ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n.”

Ọ̀pọ̀ àwọn onísìn Jain máa ń gbààwẹ̀. Ìwé ìròyìn náà, The Sunday Times of India Review, ròyìn pé: “Onísìn Jain kan tí ó jẹ́ muni [amòye] ní Bombay [Mumbai] mu kìkì ife omi sísè méjì lóòjọ́—fún 201 ọjọ́. Ó pàdánù ìwọ̀n 33 kg.” Àwọn kan tilẹ̀ gbààwẹ̀ débi fífi ebi para wọn kú, ní gbígbà gbọ́ dájú pé èyí yóò mú ìgbàlà wá.

Ní gbogbogbòò, fún àwọn àgbà ọkùnrin tí ń ṣe ìsìn Ìsìláàmù, gbígbààwẹ̀ pọn dandan nínú oṣù Ramadan. A kò gbọdọ̀ jẹun tàbí mu omi láti òwúrọ̀ títí di àṣálẹ́, jálẹ̀ oṣù náà. Ẹnikẹ́ni tí ara rẹ̀ kò bá yá tàbí tí ó bá rìnrìn àjò ní àkókò yìí, gbọ́dọ̀ wá àwọn ọjọ́ mìíràn láti gbààwẹ̀ náà pé. Lẹ́ǹtì, sáà 40 ọjọ́ tí ó máa ń ṣáájú Easter, jẹ́ àkókò ààwẹ̀ gbígbà fún àwọn kan nínú ìsìn Kirisẹ́ńdọ̀mù, ọ̀pọ̀ ètò ìsìn sì máa ń gbààwẹ̀ ní àwọn ọjọ́ mìíràn tí wọ́n yàn.

Dájúdájú, gbígbààwẹ̀ kò tí ì parẹ́. Níwọ̀n bí ó sì ti jẹ́ apá kan ọ̀pọ̀ jaburata ìsìn, a lè béèrè pé, Ọlọ́run ha ń béèrè gbígbààwẹ̀ bí? Àwọn àkókò ha wà nígbà tí àwọn Kristẹni lè pinnu láti gbààwẹ̀ bí? Èyí ha lè ṣàǹfààní bí? Ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀ lé e yóò jíròrò àwọn ìbéèrè wọ̀nyí.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

Ìsìn Jain ka gbígbààwẹ̀ sí ọ̀nà kan láti rí ìgbàlà ọkàn gbà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Mohandas K. Gandhi lo gbígbààwẹ̀ gẹ́gẹ́ bí irin iṣẹ́ lílágbára fún ète ìṣèlú tàbí ti ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Nínú ìsìn Ìsìláàmù, gbígbààwẹ̀ pọn dandan nínú oṣù Ramadan

[Credit Line]

Garo Nalbandian

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́