ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 11/15 ojú ìwé 5-7
  • Ọlọ́run Ha Béèrè Gbígbààwẹ̀ Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọlọ́run Ha Béèrè Gbígbààwẹ̀ Bí?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Gbígbààwẹ̀ Ha Wà fún Àwọn Kristẹni Bí?
  • Ààwẹ̀ Lẹ́ǹtì Ńkọ́?
  • Ìgbà Tí Gbígbààwẹ̀ Lè Ṣàǹfààní
  • Ṣé Ààwẹ̀ Gbígbà Ló Máa Jẹ́ Kó O Sún Mọ́ Ọlọ́run?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ààwẹ̀?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Gbígbààwẹ̀ Ha Ti Di Aláìbágbàmu Bí?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • A Bi Í Leere Nipa Ààwẹ̀
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 11/15 ojú ìwé 5-7

Ọlọ́run Ha Béèrè Gbígbààwẹ̀ Bí?

ÒFIN Ọlọ́run tí a fúnni nípasẹ̀ Mósè béèrè gbígbààwẹ̀ ní kìkì àkókò kan ṣoṣo péré—ní Ọjọ́ Ètùtù ọdọọdún. Òfin náà pàṣẹ pé ní ọjọ́ yẹn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́dọ̀ ‘pọ́n ọkàn wọn lójú,’ èyí tí a lóye pé ó túmọ̀ sí pé wọ́n gbààwẹ̀. (Léfítíkù 16:29-31; 23:27; Orin Dáfídì 35:13) Ṣùgbọ́n, ààwẹ̀ yìí kì í wulẹ̀ ṣe ètò àṣà kan lásán. Kíkíyè sí Ọjọ́ Ètùtù náà sún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti túbọ̀ mọ̀ pé wọ́n jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ àti pé, wọ́n nílò ìràpadà. Wọ́n tún ń gbààwẹ̀ ní ọjọ́ yẹn láti fi ìbànújẹ́ hàn nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn àti láti fi ìrònúpìwàdà hàn níwájú Ọlọ́run.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí ni ààwẹ̀ kan ṣoṣo tí ó pọn dandan lábẹ́ Òfin Mósè, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún gbààwẹ̀ ní àwọn àkókò míràn. (Ẹ́kísódù 34:28; Sámúẹ́lì Kìíní 7:6; Kíróníkà Kejì 20:3; Ẹ́sírà 8:21; Ẹ́sítérì 4:3, 16) Lára àwọn wọ̀nyí ni ààwẹ̀ tí a ń fínnúfíndọ̀ gbà gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà kan láti fi ìrònúpìwàdà hàn. Jèhófà rọ àwọn ènìyàn Júdà tí wọ́n ń tẹ ìlànà lójú pé: “Ẹ fi gbogbo ọkàn yín yí padà sí mi, àti pẹ̀lú ààwẹ̀, àti pẹ̀lú ẹkún, àti pẹ̀lú ọ̀fọ̀.” Èyí kò gbọdọ̀ jẹ́ ṣekárími, nítorí Ọlọ́run ń bá a nìṣó láti sọ pé: “Ẹ . . . fa àyà yín ya, kì í sì í ṣe aṣọ yín.”—Jóẹ́lì 2:12-15.

Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ọ̀pọ́ gbààwẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ètò àṣà ṣekárími. Jèhófà kórìíra irú gbígbààwẹ̀ tí kì í ṣe ti olótìítọ́ ọkàn bẹ́ẹ̀, nítorí náà, ó béèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì alágàbàgebè pé: “Ààwẹ̀ irú èyí ni mo yàn bí? ọjọ́ tí ènìyàn ń jẹ ọkàn rẹ̀ ní ìyà? láti tẹ orí rẹ̀ ba bíi koríko odò? àti láti tẹ́ aṣọ ọ̀fọ̀ àti eérú lábẹ́ rẹ̀? ìwọ óò ha pe èyí ní ààwẹ̀, àti ọjọ́ ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa?” (Aísáyà 58:5) Dípò fífi ààwẹ̀ tí wọ́n ń gbà ṣe ṣekárími, a sọ fún àwọn ènìyàn oníwà wíwọ́ wọ̀nyí láti mú àwọn iṣẹ́ tí ó yẹ fún ìrònúpìwàdà jáde.

Àwọn ààwẹ̀ kan tí àwọn Júù gbé kalẹ̀ kò ní ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run láti ìbẹ̀rẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, ní àkókò kan, àwọn ènìyàn Júdà ń gbààwẹ̀ mẹ́rin lọ́dọọdún láti fi ṣèrántí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ oníjàm̀bá tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìgbóguntì àti ìsọdahoro Jerúsálẹ́mù ní ọ̀rúndún keje ṣááju Sànmánì Tiwa. (Àwọn Ọba Kejì 25:1-4, 8, 9, 22-26; Sekaráyà 8:19) Lẹ́yìn tí a dá àwọn Júù sílẹ̀ kúrò ní ìgbèkùn ní Bábílónì, Jèhófà sọ nípasẹ̀ wòlíì rẹ̀, Sekaráyà, pé: “Nígbà tí ẹ̀yín gbààwẹ̀ . . . , àní fún àádọ́rin ọdún wọnnì, ẹ̀yín ha gbààwẹ̀ sí mi rárá, àní sí èmi?” Ọlọ́run kò tẹ́wọ́ gba ààwẹ̀ wọ̀nyí nítorí pé àwọn Júù ń gbààwẹ̀, wọ́n sì ń ṣọ̀fọ̀ nítorí ìdájọ́ tí ó ti ọwọ́ Jèhófà fúnra rẹ̀ wá. Wọ́n ń gbààwẹ̀ nítorí àjálù tí ó já lù wọ́n, kì í ṣe nítorí ìwà àìtọ́ wọn tí ó ṣokùnfà rẹ̀. Lẹ́yìn tí a mú wọn padà sí ilẹ̀ ìbílẹ̀ wọn, ó jẹ́ àkókò fún wọn láti hó ìhó ayọ̀ dípò bíbanú jẹ́ nítorí ohun tí ó ti kọjá.—Sekaráyà 7:5.

Gbígbààwẹ̀ Ha Wà fún Àwọn Kristẹni Bí?

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù Kristi kò fìgbà kan rí pàṣẹ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti gbààwẹ̀, òun àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ gbààwẹ̀ ní Ọjọ́ Ètùtù nítorí pé wọ́n wà lábẹ́ Òfin Mósè. Ní àfikún sí i, díẹ̀ lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ fínnúfíndọ̀ gbààwẹ̀ ní àwọn àkókò míràn, níwọ̀n bí Jésù kò ti pàṣẹ fún wọn láti yẹra fún àṣà náà pátápátá. (Ìṣe 13:2, 3; 14:23) Síbẹ̀, wọn kò gbọdọ̀ ‘ba ojú wọn jẹ́ nítorí àtilè fara han àwọn ènìyàn pé wọ́n ń gbààwẹ̀.’ (Mátíù 6:16) Irú fífi ìfọkànsìn ṣekárími hàn bẹ́ẹ̀ lè mú kí àwọn ènìyàn míràn kan sáárá síni, kí wọ́n sì gbóṣùbà fúnni. Síbẹ̀síbẹ̀, inú Ọlọ́run kò dùn sí irú ṣekárími bẹ́ẹ̀.—Mátíù 6:17, 18.

Jésù pẹ̀lú sọ nípa bí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ yóò ti gbààwẹ̀ nígbà ikú rẹ̀. Òun kò tipa bẹ́ẹ̀ gbé ààwẹ̀ aláàtò ìsìn kalẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ń tọ́ka sí ìhùwàpadà kan sí ìbànújẹ́ jíjinlẹ̀ tí wọn yóò nírìírí rẹ̀. Ní gbàrà tí a bá ti jí i dìde, òun yóò wà pẹ̀lú wọn lẹ́ẹ̀kan sí i, kì yóò sì sí ìdí bẹ́ẹ̀ kan fún wọn mọ́ láti gbààwẹ̀.—Lúùkù 5:34, 35.

Òfin Mósè dópin nígbà tí “a fi Kristi rúbọ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún tún un ṣe mọ́ láé láti ru ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀.” (Hébérù 9:24-28) Nígbà tí Òfin náà sì ti dópin, àṣẹ náà láti gbààwẹ̀ ní Ọjọ́ Ètùtù dópin. Nípa báyìí, a mú ààwẹ̀ pípọn dandan kan ṣoṣo tí a mẹ́nu bà nínú Bíbélì kúrò.

Ààwẹ̀ Lẹ́ǹtì Ńkọ́?

Nígbà náà, kí ni ìdí fún ààwẹ̀ tí àwọn onísìn Kirisẹ́ńdọ̀mù ń gbà lákòókò Lẹ́ǹtì? Àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì àti Pùròtẹ́sítáǹtì tẹ́wọ́ gba ààwẹ̀ Lẹ́ǹtì, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé bí wọ́n ṣe ń gbà á yàtọ̀ láti ṣọ́ọ̀ṣì kan sí èkejì. Àwọn kan máa ń jẹ oúnjẹ ẹ̀ẹ̀kan lóòjọ́ ní gbogbo sáà 40 ọjọ́ tí ó ń ṣáájú Easter. Àwọn mìíràn máa ń gbààwẹ̀ délẹ̀délẹ̀ ní ọjọ́ Ash Wednesday àti Good Friday. Fún àwọn kan, ààwẹ̀ Lẹ́ǹtì, ń béèrè títa kété sí jíjẹ ẹran, ẹja, ẹyin, àti àwọn ohun tí a fi wàrà ṣe.

Ààwẹ̀ Lẹ́ǹtì ni àwọn kan lérò pé a gbé karí ààwẹ̀ 40 ọjọ́ tí Jésù gbà lẹ́yìn batisí rẹ̀. Nígbà náà lọ́hùn-ún, òún ha ń gbé ààtò ìsìn kan kalẹ̀ tí a óò máa tẹ̀ lé lọ́dọọdún bí? Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Èyí ṣe kedere láti inú òtítọ́ náà pé Bíbélì kò ṣàkọsílẹ̀ irú àṣà èyíkéyìí bẹ́ẹ̀ láàárín àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀. A gba ààwẹ̀ Lẹ́ǹtì fún ìgbà àkọ́kọ́ ní ọ̀rúndún kẹrin lẹ́yìn tí Kristi ti wá. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ àwọn ẹ̀kọ́ Kirisẹ́ńdọ̀mù míràn, a gbà á lò láti inú àwọn orísun tí ó jẹ́ ti abọ̀rìṣà.

Bí ààwẹ̀ Lẹ́ǹtì bá jẹ́ ní àfarawé gbígbààwẹ̀ tí Jésù gbààwẹ̀ nínú aginjù lẹ́yìn batisí rẹ̀, èé ṣe tí a fi ń gbà á ní àwọn ọ̀sẹ̀ tí ó ṣáájú Easter—tí àwọn kan lérò pé ó jẹ́ àkókò àjíǹde rẹ̀? Jésù kò gbààwẹ̀ ní àwọn ọjọ́ tí ó wà ní gẹ́rẹ́ ṣáájú ikú rẹ̀. Àwọn àkọsílẹ̀ Ìhìn Rere fi hàn pé òun àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣèbẹ̀wò sí àwọn ibùgbé, wọ́n sì jẹun ní Bẹ́tánì ní kìkì ọjọ́ díẹ̀, ṣáájú kí ó tó kú. Ó sì jẹ oúnjẹ Ìrékọjá ní alẹ́ tí ó ṣáájú ikú rẹ̀.—Mátíù 26:6, 7; Lúùkù 22:15; Jòhánù 12:2.

Ohun kan wà tí a ní láti kọ́ láti inú gbígbààwẹ̀ tí Jésù gbààwẹ̀ lẹ́yìn batisí rẹ̀. Ó ń dágbá lé iṣẹ́ òjíṣẹ́ pàtàkì kan. Ó kan ìdáláre ipò ọba aláṣẹ ti Jèhófà àti ọjọ́ ọ̀la gbogbo ìran ènìyàn. Àkókò nìyí fún àṣàrò jíjinlẹ̀ àti fún fífi tàdúràtàdúrà yíjú sí Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́ àti ìtọ́sọ́nà. Ní àkókò yìí, Jésù gbààwẹ̀ lọ́nà tí ó bá a mu wẹ́kú. Èyí fi hàn pé gbígbààwẹ̀ lè ṣàǹfààní nígbà tí a bá ṣe é pẹ̀lú ìsúnniṣe títọ́, àti ní àkókò yíyẹ.—Fi wé Kólósè 2:20-23.

Ìgbà Tí Gbígbààwẹ̀ Lè Ṣàǹfààní

Jẹ́ kí a ṣàgbéyẹ̀wò àwọn àkókò kan lónìí nígbà tí olùjọ́sìn Ọlọ́run lè gbààwẹ̀. Ẹnì kan tí ó ti dẹ́ṣẹ̀ lè máà fẹ́ láti jẹun fún sáà kan. Èyí kì yóò jẹ́ láti wú àwọn ẹlòmíràn lórí tàbí láti fi ìbínú hàn nítorí tí a bá a wí. Àmọ́ ṣáá o, gbígbààwẹ̀ nínú ara rẹ̀ kì yóò mú ọ̀ràn tọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n, ẹnì kan tí ó ronú pìwà dà ní tòótọ́ yóò nímọ̀lára ìbànújẹ́ jíjinlẹ̀ nítorí mímú tí ó ti mú Jèhófà àti bóyá àwọn ọ̀rẹ́ àti ìdílé banú jẹ́. Làásìgbò àti àdúrà gbígbóná janjan fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ lè máà mú kí ọkàn ẹní fà sí oúnjẹ.

Ọba Dáfídì ti Ísírẹ́lì ní irú ìrírí kan náà. Nígbà tí ó ń retí pípàdánù ọmọkùnrin rẹ̀ tí Bátí-ṣébà bí fún un, ó pa gbogbo ìsapá rẹ̀ pọ̀ sórí gbígbàdúrà sí Jèhófà láti rí àánú gbà lórí ọmọ náà. Bí ó ti ń lo èrò ìmọ̀lára rẹ̀ àti okun rẹ̀ nínú àdúrà, ó gbààwẹ̀. Bákan náà, jíjẹ oúnjẹ lè ṣàìbá a mu wẹ́kú lábẹ́ àwọn ipò másùn máwo pàtó kan lónìí.—Sámúẹ́lì Kejì 12:15-17.

Àwọn àkókò tún lè wà nígbà tí ẹnì kan tí ó jẹ́ oníwà-bí-Ọlọ́run lè fẹ́ láti pọkàn pọ̀ sórí àwọn ọ̀ràn tẹ̀mí jíjinlẹ̀ kan. Ìwádìí nínú Bíbélì àti àwọn ìtẹ̀jáde Kristẹni lè pọn dandan. A lè nílò sáà kan fún ṣíṣe àṣàrò. Nígbà irú sáà ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ń fi ara fún pátápátá bẹ́ẹ̀, ẹnì kan lè yàn láti má ṣe fi jíjẹ oúnjẹ pín ọkàn rẹ̀ níyà.—Fi wé Jeremáyà 36:8-10.

A ní àwọn àpẹẹrẹ inú Ìwé Mímọ́ ní ti àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n gbààwẹ̀ nígbà tí wọ́n ní láti ṣe àwọn ìpinnu wíwúwo. Ní ọjọ́ Nehemáyà, a fẹ́ ṣe ìbúra kan fún Jèhófà, àwọn Júù yóò sì gba ègún bí wọ́n bá hùwà lòdì sí ìbúra náà. Wọ́n ní láti ṣèlérí láti kọ àwọn àjèjì aya wọn sílẹ̀, kí wọ́n sì ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wọn ká. Ṣáájú ṣíṣe ìbúra yìí àti nígbà tí wọ́n ń jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ wọn, gbogbo ìjọ náà gbààwẹ̀. (Nehemáyà 9:1, 38; 10:29, 30) Nígbà tí a bá dojú kọ àwọn ìpinnu wíwúwo, Kristẹni kan lè ṣàìjẹun fún sáà kúkúrú kan.

Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, gbígbààwẹ̀ máa ń bá ìpinnu ṣíṣe nípasẹ̀ ẹgbẹ́ àwọn alàgbà nínú ìjọ Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ rìn. Lónìí, àwọn alàgbà ìjọ tí wọ́n dojú kọ àwọn ìpinnu líle koko, bóyá ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ọ̀ràn ìdájọ́, lè ṣàìjẹun nígbà tí wọ́n bá ń gbé ọ̀ràn náà yẹ̀ wò.

Yíyàn láti gbààwẹ̀ nínú àwọn àyíká ipò kan jẹ́ ìpinnu ẹnì kọ̀ọ̀kan. Ẹnì kan kò gbọdọ̀ dá ẹnì kejì lẹ́jọ́ lórí ọ̀ràn yìí. A kò gbọdọ̀ fẹ́ láti “fara hàn . . . bí olódodo sí àwọn ènìyàn”; bẹ́ẹ̀ sì ni a kò gbọdọ̀ sọ oúnjẹ di bàbàrà débi tí yóò fi ṣèdíwọ́ fún bí a ti ń bójú tó àwọn ojúṣe pàtàkì. (Mátíù 23:28; Lúùkù 12:22, 23) Bíbélì sì fi hàn pé Ọlọ́run kò béèrè pé kí a gbààwẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni kò ka gbígbààwẹ̀ léèwọ̀ fún wa.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ìwọ́ ha mọ ìdí tí Jésù fi gbààwẹ̀ fún 40 ọjọ́ lẹ́yìn ìbatisí rẹ̀ bí?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́