ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • jy orí 34 ojú ìwé 82-ojú ìwé 83 ìpínrọ̀ 6
  • Jésù Yan Àwọn Àpọ́sítélì Méjìlá

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jésù Yan Àwọn Àpọ́sítélì Méjìlá
  • Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Yíyan Awọn Apọsiteli Rẹ̀
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
  • Àwọn Tó Di Ọmọ Ẹ̀yìn Jésù
    Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà
  • Jésù Kọ́ Àwọn Èèyàn Lórí Òkè
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • Jésù Yan Àwọn Àpọ́sítélì Méjìlá
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
Àwọn Míì
Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
jy orí 34 ojú ìwé 82-ojú ìwé 83 ìpínrọ̀ 6
Jésù lọ sórí òkè kan

ORÍ 34

Jésù Yan Àwọn Àpọ́sítélì Méjìlá

MÁÀKÙ 3:13-19 LÚÙKÙ 6:12-16

  • ÀWỌN ÀPỌ́SÍTÉLÌ MÉJÌLÁ

Ó ti tó nǹkan bí ọdún kan àtààbọ̀ báyìí tí Jòhánù Arinibọmi ti kéde fáwọn èèyàn pé Jésù ni Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run. Bí Jésù ṣe bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, àwọn ọkùnrin mélòó kan tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ di ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Lára wọn ni Áńdérù, Símónì Pétérù, Jòhánù, ó ṣeé ṣe kí Jémíìsì náà wà lára wọn (ìyẹn arákùnrin Jòhánù), Fílípì àti Bátólómíù (tó tún ń jẹ́ Nàtáníẹ́lì). Nígbà tó yá, àwọn míì náà bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ lé Kristi.—Jòhánù 1:45-47.

Ó ti wá tó àkókò báyìí tí Jésù máa yan àwọn àpọ́sítélì rẹ̀. Àwọn ló máa jẹ́ alábàáṣiṣẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́, ó sì máa dá wọn lẹ́kọ̀ọ́ lákànṣe. Àmọ́ kó tó yàn wọ́n, ó lọ sórí òkè kan, bóyá èyí tó wà nítòsí Òkun Gálílì, tí kò jìnnà sí Kápánáúmù. Gbogbo òru mọ́jú ló fi gbàdúrà, ó ṣeé ṣe kó bẹ Jèhófà pé kó fún òun ní ọgbọ́n, kó sì tọ́ òun sọ́nà. Nígbà tó dọjọ́ kejì, ó pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ jọ, ó sì yan méjìlá (12) lára wọn láti di àpọ́sítélì.

Jésù yan àwọn mẹ́fà tá a dárúkọ ṣáájú àti Mátíù tó pè ní ọ́fíìsì àwọn agbowó orí. Àwọn márùn-ún yòókù ni Júdásì (tó tún ń jẹ́ Tádéọ́sì “ọmọ Jémíìsì”), Símónì tó jẹ́ Kánánéánì, Tọ́másì, Jémíìsì ọmọ Áfíọ́sì àti Júdásì Ìsìkáríọ́tù.—Mátíù 10:2-4; Lúùkù 6:16.

Jésù gbàdúrà kó tó yan àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ méjìlá

Ó ṣe díẹ̀ táwọn méjìlá yìí ti ń bá Jésù rìnrìn àjò, ó sì dájú pé ó mọ̀ wọ́n dáadáa. Mọ̀lẹ́bí rẹ̀ tiẹ̀ làwọn kan lára wọn. Bí àpẹẹrẹ, kò sí àní-àní pé ìbátan tímọ́tímọ́ Jésù ni Jémíìsì àti Jòhánù tí wọ́n jẹ́ tẹ̀gbọ́n-tàbúrò. Tó bá sì jẹ́ pé òótọ́ làwọn kan sọ pé arákùnrin ni Áfíọ́sì jẹ́ sí Jósẹ́fù alágbàtọ́ Jésù, á jẹ́ pé mọ̀lẹ́bí Jésù ni àpọ́sítélì Jémíìsì ọmọ Áfíọ́sì.

Kò ṣòro rárá fún Jésù láti rántí orúkọ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀. Àmọ́ ṣé ìwọ náà lè dárúkọ wọn? Jẹ́ ká ṣe ohun kan tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Símónì méjì ló wà, Jémíìsì méjì àti Júdásì méjì. Símónì (Pétérù) ní arákùnrin kan tó ń jẹ́ Áńdérù, Jémíìsì (ọmọ Sébédè) náà sì ní arákùnrin kan tó ń jẹ́ Jòhánù. Ìyẹn ti jẹ́ ká mọ orúkọ mẹ́jọ lára wọn. Àwọn mẹ́rin yòókù ni agbowó orí kan (Mátíù), èyí tó ṣiyèméjì nígbà tó yá (Tọ́másì), èyí tí wọ́n pè lábẹ́ igi (Nàtáníẹ́lì) àti ọ̀rẹ́ Nàtáníẹ́lì (Fílípì).

Gálílì tó jẹ́ agbègbè ìbílẹ̀ Jésù ni mọ́kànlá lára àwọn àpọ́sítélì náà ti wá. Kánà ni Nàtáníẹ́lì ti wá. Bẹtisáídà ni Fílípì, Pétérù àti Áńdérù ti wá. Nígbà tó yá, Pétérù àti Áńdérù kó lọ sí Kápánáúmù, níbi tó ṣeé ṣe kí Mátíù máa gbé. Jémíìsì àti Jòhánù náà ń gbé ní Kápánáúmù tàbí nítòsí ibẹ̀, wọ́n sì ń ṣe òwò ẹja pípa níbẹ̀. Ó jọ pé Júdásì Ìsìkáríọ́tù tó da Jésù níkẹyìn nìkan ni àpọ́sítélì tó wá láti Jùdíà.

  • Ìpinnu tó ṣe pàtàkì wo ni Jésù ṣe lẹ́yìn tó gbàdúrà ní gbogbo òru mọ́jú?

  • Àwọn wo ni àpọ́sítélì Jésù, báwo lo sì ṣe lè rántí orúkọ wọn?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́