Ẹ̀KỌ́ 80
Jésù Yan Àwọn Àpọ́sítélì Méjìlá
Ní báyìí tí Jésù ti ń wàásù fún nǹkan bí ọdún kan àtààbọ̀, ó ti tó àkókò fún un láti yan àwọn tí wọ́n á jọ máa ṣiṣẹ́, ìpinnu ńlá sì nìyẹn. Àwọn wo ló wá máa yàn? Àwọn wo ló máa dá lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè máa bójú tó ìjọ Kristẹni? Jésù ò fẹ́ dá ṣe àwọn ìpinnu yẹn, ó fẹ́ kí Jèhófà tọ́ òun sọ́nà. Torí náà, ó lọ sórí òkè kan kó lè dá wà, ó sì gbàdúrà láti òru mọ́jú. Nígbà tílẹ̀ mọ́, Jésù pe àwọn kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀, ó sì yan méjìlá (12) lára wọn láti di àpọ́sítélì. Èwo nínú wọn lo rántí orúkọ ẹ̀? Ó dáa, orúkọ wọn ni Pétérù, Áńdérù, Jémíìsì, Jòhánù, Fílípì, Bátólómíù, Tọ́másì, Mátíù, Jémíìsì ọmọ Áfíọ́sì, Tádéọ́sì, Símónì àti Júdásì Ìsìkáríọ́tù.
Áńdérù, Pétérù, Fílípì, Jémíìsì
Àwọn Méjìlá (12) yìí láá máa rìnrìn àjò pẹ̀lú Jésù. Lẹ́yìn tí Jésù ti dá wọn lẹ́kọ̀ọ́, ó rán wọn jáde pé kí wọ́n lọ wàásù. Jèhófà fún wọn lágbára láti lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde kí wọ́n sì mú àwọn aláìsàn lára dá.
Jòhánù, Mátíù, Bátólómíù, Tọ́másì
Jésù pe àwọn Méjìlá (12) yìí ní ọ̀rẹ́ òun, ó sì fọkàn tán wọn. Àwọn Farisí gbà pé àwọn àpọ́sítélì yẹn ò lọ síléèwé àti pé tálákà ni wọ́n. Àmọ́, Jésù kọ́ wọn dáadáa kí wọ́n lè ṣiṣẹ́ wọn láṣeyọrí. Àwọn ló wà pẹ̀lú ẹ̀ láwọn àsìkò tó ṣe pàtàkì jù nígbèésí ayé ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n wà pẹ̀lú Jésù kó tó kú, wọ́n sì tún wà pẹ̀lú ẹ̀ lẹ́yìn tó jíǹde. Gálílì tó jẹ́ ìlú Jésù lèyí tó pọ̀ jù lára wọn ti wá, àwọn kan sì ti níyàwó.
Jémíìsì ọmọ Áfíọ́sì, Júdásì Ìsìkáríọ́tù, Tádéọ́sì, Símónì
Àwọn àpọ́sítélì yìí kì í ṣe ẹni pípé, torí náà wọ́n máa ń ṣe àṣìṣe. Nígbà míì, wọ́n máa ń sọ̀rọ̀ láìronú, wọ́n máa ń ṣe àwọn ìpinnu tí kò dáa. Ìgbà míì wà tí wọn kì í ní sùúrù, wọ́n sì máa ń jiyàn nípa ẹni tó yẹ kó jẹ́ ọ̀gá láàárín wọn. Àmọ́, èèyàn dáadáa ni wọ́n, wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Àwọn ló máa bẹ̀rẹ̀ ìjọ Kristẹni lẹ́yìn tí Jésù bá lọ sí ọ̀run.
“Mo pè yín ní ọ̀rẹ́, torí pé mo ti jẹ́ kí ẹ mọ gbogbo ohun tí mo gbọ́ látọ̀dọ̀ Baba mi.”—Jòhánù 15:15