ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • jy orí 55 ojú ìwé 134-ojú ìwé 135 ìpínrọ̀ 10
  • Ọ̀rọ̀ Jésù Ya Ọ̀pọ̀ Èèyàn Lẹ́nu

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọ̀rọ̀ Jésù Ya Ọ̀pọ̀ Èèyàn Lẹ́nu
  • Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọ̀pọ̀ Ọmọ-ẹhin Pada Lẹhin Jesu
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
  • Kí Ló Yẹ Kó O Ṣe Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Jésù “Ni Oúnjẹ Ìyè”
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
Àwọn Míì
Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
jy orí 55 ojú ìwé 134-ojú ìwé 135 ìpínrọ̀ 10
Nígbà tí Jésù ń bá àwọn àpọ́sítélì méjìlá sọ̀rọ̀, Júdásì ń wo ibòmíì torí pé ọkàn rẹ̀ ò sí níbẹ̀; àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó kù ń sọ̀rọ̀ wúyẹ́wúyẹ́ láàárín ara wọn bí wọ́n ṣe ń kúrò lọ́dọ̀ Jésù

ORÍ 55

Ọ̀rọ̀ Jésù Ya Ọ̀pọ̀ Èèyàn Lẹ́nu

JÒHÁNÙ 6:48-71

  • WỌ́N GBỌ́DỌ̀ JẸ ẸRAN ARA RẸ̀ KÍ WỌ́N SÌ MU Ẹ̀JẸ̀ RẸ̀

  • Ọ̀PỌ̀ LÓ KỌSẸ̀, WỌN Ò SÌ TẸ̀ LÉ JÉSÙ MỌ́

Nínú sínágọ́gù tó wà ní Kápánáúmù, Jésù ń kọ́ àwọn èèyàn nípa bí òun ṣe jẹ́ oúnjẹ tó sọ̀ kalẹ̀ wá láti ọ̀run. Jésù ti kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ yìí fáwọn tó wá láti apá ìlà oòrùn Òkun Gálílì, ìyẹn àwọn tó jẹ lára búrẹ́dì àti ẹja tó pèsè.

Ó wá ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “Àwọn baba ńlá yín jẹ mánà ní aginjù, síbẹ̀ wọ́n kú.” Ó wá sọ pé oúnjẹ tóun fẹ́ fún wọn yàtọ̀ síyẹn, ó ní: “Èmi ni oúnjẹ ààyè tó sọ̀ kalẹ̀ wá láti ọ̀run. Tí ẹnikẹ́ni bá jẹ nínú oúnjẹ yìí, ó máa wà láàyè títí láé; àti pé ní tòótọ́, ẹran ara mi ni oúnjẹ tí màá fúnni nítorí ìyè ayé.”—Jòhánù 6:48-51.

Nígbà ìrúwé ọdún 30 S.K., Jésù sọ fún Nikodémù pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé gan-an débi pé ó fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni kó lè gba gbogbo èèyàn là. Jésù jẹ́ kó mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì ká jẹ ẹran ara òun, lédè míì ká lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà tóun máa san. Ìyẹn nìkan ló sì máa jẹ́ ká ní ìyè àìnípẹ̀kun.

Àmọ́, àwọn èèyàn náà ò gba ohun tí Jésù sọ. Wọ́n ń bi ara wọn pé: “Báwo ni ọkùnrin yìí ṣe máa fún wa ní ẹran ara rẹ̀ jẹ?” (Jòhánù 6:52) Jésù fẹ́ kó yé wọn pé kì í ṣe ẹran ara òun gan-an ni wọ́n máa jẹ, àpẹẹrẹ lásán nìyẹn kàn jẹ́. Ohun tó sọ lẹ́yìn náà sì fi hàn bẹ́ẹ̀.

Ó ní: “Láìjẹ́ pé ẹ jẹ ẹran ara Ọmọ èèyàn, tí ẹ sì mu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ẹ ò ní ìyè kankan nínú ara yín. Ẹnikẹ́ni tó bá ń jẹ ẹran ara mi, tó sì ń mu ẹ̀jẹ̀ mi máa ní ìyè àìnípẹ̀kun, . . . torí pé oúnjẹ tòótọ́ ni ẹran ara mi, ohun mímu tòótọ́ sì ni ẹ̀jẹ̀ mi. Ẹnikẹ́ni tó bá ń jẹ ẹran ara mi, tó sì ń mu ẹ̀jẹ̀ mi wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú mi.”—Jòhánù 6:53-56.

Ẹ fojú inú wo bí ọ̀rọ̀ yẹn ṣe máa rí lára àwọn Júù tó wà níbẹ̀! Wọ́n lè máa ronú pé ṣe ni Jésù ní káwọn máa jẹ èèyàn tàbí káwọn máa mu ẹ̀jẹ̀, ìyẹn sì ta ko Òfin Mósè. (Jẹ́nẹ́sísì 9:4; Léfítíkù 17:10, 11) Àmọ́, Jésù ò ní kí wọ́n wá jẹ ẹran ara òun gangan tàbí kí wọ́n wá mu ẹ̀jẹ̀ òun. Ohun tó ń sọ ni pé gbogbo ẹni tó bá fẹ́ ní ìyè àìnípẹ̀kun gbọ́dọ̀ lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà tóun máa san nígbà tóun bá fi ara pípé àti ẹ̀jẹ̀ òun rúbọ. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn ò lóye ohun tó sọ yìí. Kódà, àwọn kan tiẹ̀ sọ pé: “Ọ̀rọ̀ yìí ń dẹ́rù bani; kò ṣeé gbọ́ sétí!”—Jòhánù 6:60.

Jésù kíyè sí i pé ọ̀rọ̀ náà mú kí díẹ̀ lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn máa kùn, torí náà ó bi wọ́n pé: “Ṣé ó mú yín kọsẹ̀ ni? Tí ẹ bá wá rí Ọmọ èèyàn tó ń gòkè lọ sí ibi tó wà tẹ́lẹ̀ ńkọ́? . . . Ẹ̀mí àti ìyè ni àwọn ọ̀rọ̀ tí mo sọ fún yín. Àmọ́ àwọn kan wà nínú yín tí kò gbà gbọ́.” Torí náà, ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn fi í sílẹ̀, wọn ò sì bá a rìn mọ́.—Jòhánù 6:61-64.

Jésù wá bi àwọn àpọ́sítélì méjìlá (12) náà pé: “Ẹ̀yin ò fẹ́ lọ ní tiyín, àbí ẹ fẹ́ lọ?” Pétérù dá a lóhùn pé: “Olúwa, ọ̀dọ̀ ta la máa lọ? Ìwọ lo ní àwọn ọ̀rọ̀ ìyè àìnípẹ̀kun. A ti gbà gbọ́, a sì ti mọ̀ pé ìwọ ni Ẹni Mímọ́ Ọlọ́run.” (Jòhánù 6:67-69) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Pétérù àtàwọn àpọ́sítélì yòókù ò tíì lóye ohun tí Jésù sọ, síbẹ̀ ọ̀rọ̀ tí Pétérù sọ yìí fi hàn pé ó jẹ́ adúróṣinṣin.

Ohun tí Pétérù sọ yẹn múnú Jésù dùn, àmọ́ Jésù sọ pé: “Ẹ̀yin méjìlá (12) yìí ni mo yàn, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Síbẹ̀, abanijẹ́ ni ọ̀kan nínú yín.” (Jòhánù 6:70) Ọ̀rọ̀ Júdásì Ìsìkáríọ́tù ló ń sọ. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìgbà yẹn ni Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í fura sí i pé èròkerò ti ń gbilẹ̀ lọ́kàn Júdásì.

Síbẹ̀, inú Jésù dùn pé Pétérù àtàwọn àpọ́sítélì yòókù ò pa òun tì, wọn ò sì yéé wàásù ìhìn rere.

  • Báwo ni Jésù ṣe fún àwọn èèyàn ní ẹran ara ẹ̀, báwo lẹnì kan sì ṣe lè jẹ ẹ́?

  • Kí nìdí tó fi ya àwọn èèyàn lẹ́nu nígbà tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa ẹran àti ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, àmọ́ kí ni Jésù ní lọ́kàn?

  • Kí ni Pétérù sọ nígbà táwọn èèyàn ò tẹ̀ lé Jésù mọ́?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́