ORÍ 77
Jésù Sọ̀rọ̀ Nípa Ọrọ̀
ÀPÈJÚWE ỌKÙNRIN ỌLỌ́RỌ̀ KAN
JÉSÙ SỌ̀RỌ̀ NÍPA ẸYẸ ÌWÒ ÀTI ÒDÒDÓ LÍLÌ
“AGBO KÉKERÉ” TÓ MÁA BÁ JÉSÙ JỌBA
Jésù ò tíì kúrò nílé Farisí kan tó pè é wá jẹun, bẹ́ẹ̀ lọ̀pọ̀ èèyàn ń dúró dè é níta. Ohun kan náà ló ṣẹlẹ̀ nígbà tó wà ní Gálílì. (Máàkù 1:33; 2:2; 3:9) Ní Jùdíà tó tún wà yìí, ọ̀pọ̀ ló fẹ́ rí i tí wọ́n sì fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, ohun tí wọ́n ṣe yìí yàtọ̀ pátápátá sí tàwọn Farisí tó wà pẹ̀lú Jésù.
Jésù wá kìlọ̀ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ ṣọ́ra fún ìwúkàrà àwọn Farisí, ìyẹn àgàbàgebè.” Jésù ti sọ̀rọ̀ yìí fún wọn tẹ́lẹ̀, àmọ́ ohun táwọn Farisí yẹn ṣe mú kó túbọ̀ tẹ ìkìlọ̀ yẹn mọ́ wọn létí. (Lúùkù 12:1; Máàkù 8:15) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn Farisí yẹn ń gbìyànjú láti bo ìwà ìkà wọn mọ́lẹ̀ bí wọ́n ṣe ń ṣe bíi pé àwọn mọ́, síbẹ̀ ó yẹ kí àṣírí ìwà ìkà wọn tú. Jésù wá sọ pé: “Kò sí ohun kan tí a rọra tọ́jú tí a ò ní ṣí payá, kò sì sí ohun tó jẹ́ àṣírí tí a ò ní mọ̀.”—Lúùkù 12:2.
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn ará Jùdíà ló pọ̀ jù lára àwọn èrò tó wá rí Jésù, wọ́n sì lè má sí níbẹ̀ nígbà tí Jésù ń kọ́ àwọn èèyàn ní Gálílì. Torí náà, Jésù tún àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ. Ó sọ pé: “Ẹ má bẹ̀rù àwọn tó ń pa ara, àmọ́ tí wọn ò lè ṣe ohunkóhun mọ́ lẹ́yìn èyí.” (Lúùkù 12:4) Jésù ti kọ́kọ́ sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé ó ṣe pàtàkì kí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run pé ó máa pèsè ohun tí wọ́n nílò, síbẹ̀ ó tún kókó yẹn sọ. Ó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ó yẹ kí wọ́n gba Ọmọ èèyàn gbọ́, kí wọ́n sì gbà pé Ọlọ́run lè ran àwọn lọ́wọ́.—Mátíù 10:19, 20, 26-33; 12:31, 32.
Àsìkò yẹn ni ọkùnrin kan láàárín èrò wá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ohun tó ń jẹ ẹ́ lọ́kàn, ó ní: “Olùkọ́, sọ fún arákùnrin mi kó pín ogún fún mi.” (Lúùkù 12:13) Ohun tí Òfin sọ ni pé kí ọkùnrin tó jẹ́ àkọ́bí gba ìpín méjì nínú ogún, kò sídìí tó fi yẹ kí ìyẹn fa ìjà. (Diutarónómì 21:17) Àmọ́, ó jọ pé ṣe ni ọkùnrin yìí fẹ́ gbà ju ohun tó yẹ kó gbà lọ. Ni Jésù bá fọgbọ́n dá a lóhùn láìgbè sẹ́yìn ẹnikẹ́ni, ó ní: “Ọkùnrin yìí, ta ló yàn mí ṣe adájọ́ tàbí alárinà láàárín ẹ̀yin méjèèjì?”—Lúùkù 12:14.
Jésù wá sọ fún gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ pé: “Ẹ la ojú yín sílẹ̀, kí ẹ sì máa ṣọ́ra fún onírúurú ojúkòkòrò, torí pé tí ẹnì kan bá tiẹ̀ ní nǹkan rẹpẹtẹ, àwọn ohun tó ní kò lè fún un ní ìwàláàyè.” (Lúùkù 12:15) Kò sí bí ẹnì kan ṣe lè lówó tó, á ṣáà kú lọ́jọ́ kan, á sì fi gbogbo ohun tó ní sílẹ̀. Jésù wá fi àpèjúwe kan tẹnu mọ́ kókó tó ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ tán yìí, àpèjúwe yẹn jẹ́ káwọn èèyàn rí ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí wọ́n ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run, ó ní:
“Ilẹ̀ ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan méso jáde dáadáa. Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í rò ó lọ́kàn ara rẹ̀ pé, ‘Kí ni kí n ṣe báyìí tí mi ò ní ibì kankan tí màá kó irè oko mi jọ sí?’ Torí náà, ó sọ pé, ‘Ohun tí màá ṣe nìyí: Màá ya àwọn ilé ìkẹ́rùsí mi lulẹ̀, màá sì kọ́ àwọn tó tóbi, ibẹ̀ ni màá kó gbogbo ọkà mi àti gbogbo ẹrù mi jọ sí, màá sì sọ fún ara mi pé: “O ní ọ̀pọ̀ nǹkan rere tí mo ti tò jọ fún ọ̀pọ̀ ọdún; fọkàn balẹ̀, máa jẹ, máa mu, máa gbádùn ara ẹ.”’ Àmọ́ Ọlọ́run sọ fún un pé, ‘Aláìlóye, òru òní ni wọ́n máa béèrè ẹ̀mí rẹ lọ́wọ́ rẹ. Ta ló máa wá ni àwọn ohun tí o ti tò jọ?’ Bẹ́ẹ̀ ló máa rí fún ẹni tó bá ń to ìṣúra jọ fún ara rẹ̀ àmọ́ tí kò ní ọrọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run.”—Lúùkù 12:16-21.
Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí kan gbogbo àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ títí kan àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, torí pé wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí í ronú àtikó ọrọ̀ jọ. Kòókòó-jàn-án-jàn-án ojoojúmọ́ sì lè gbà wọ́n lọ́kàn débi pé wọn ò ní ráyè sin Jèhófà. Ìdí nìyẹn tí Jésù tún fi fún wọn ní ìmọ̀ràn tó ti fún wọn ní nǹkan bí ọdún kan ààbọ̀ sẹ́yìn nígbà tó ń ṣe Ìwàásù Lórí Òkè, ó ní:
“Ẹ yéé ṣàníyàn nípa ẹ̀mí yín, ní ti ohun tí ẹ máa jẹ tàbí nípa ara yín, ní ti ohun tí ẹ máa wọ̀. . . . Ẹ wo àwọn ẹyẹ ìwò: Wọn kì í fúnrúgbìn, wọn kì í sì í kárúgbìn; wọn ò ní abà tàbí ilé ìkẹ́rùsí; síbẹ̀ Ọlọ́run ń bọ́ wọn. Ṣé ẹ ò wá níye lórí gan-an ju àwọn ẹyẹ lọ ni? . . . Ẹ ronú nípa bí àwọn òdòdó lílì ṣe ń dàgbà: Wọn kì í ṣe làálàá, wọn kì í sì í rànwú; àmọ́ mò ń sọ fún yín pé, a ò ṣe Sólómọ́nì pàápàá lọ́ṣọ̀ọ́ nínú gbogbo ògo rẹ̀ bí ọ̀kan lára àwọn yìí. . . . Torí náà, ẹ yéé wá ohun tí ẹ máa jẹ àti ohun tí ẹ máa mu, ẹ má sì jẹ́ kí àníyàn kó yín lọ́kàn sókè mọ́ . . . Baba yín mọ̀ pé ẹ nílò àwọn nǹkan yìí. . . . Ẹ máa wá Ìjọba rẹ̀, a sì máa fi àwọn nǹkan yìí kún un fún yín.”—Lúùkù 12:22-31; Mátíù 6:25-33.
Àwọn wo ni kó máa wá Ìjọba Ọlọ́run? Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé àwùjọ èèyàn kékeré kan tó jẹ́ olóòótọ́ ló máa ṣe bẹ́ẹ̀, Bíbélì pè wọ́n ní “agbo kékeré.” Tó bá yá, àwọn ọmọ ẹ̀yìn máa mọ̀ pé ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) ni iye wọn. Kí ló wà nípamọ́ fún wọn? Jésù fi dá wọn lójú pé: “Baba yín ti fọwọ́ sí i láti fún yín ní Ìjọba náà.” Àwùjọ yìí ò ní máa lé ohun tí ayé ń lé, kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó máa gbà wọ́n lọ́kàn ni bí wọ́n á ṣe ní “ìṣúra tí kò lè kùnà láé sí ọ̀run,” níbi tí wọ́n ti máa jọba pẹ̀lú Kristi.—Lúùkù 12:32-34.