ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • jy orí 115 ojú ìwé 266-ojú ìwé 267 ìpínrọ̀ 3
  • Ìrékọjá Tí Jésù Máa Ṣe Kẹ́yìn Ń Sún Mọ́lé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìrékọjá Tí Jésù Máa Ṣe Kẹ́yìn Ń Sún Mọ́lé
  • Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìrékọjá Ìgbẹ̀hìn fun Jesu Kù Sí Dẹ̀dẹ̀
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
  • ‘Èyí Yóò Jẹ́ Ìrántí Fún Yín’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Mímú Àwọn Ọjọ́ Tí Jésù Lò Kẹ́yìn Lórí Ilẹ̀ Ayé Wá sí Ìrántí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
Àwọn Míì
Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
jy orí 115 ojú ìwé 266-ojú ìwé 267 ìpínrọ̀ 3
Júdásì lọ rí àwọn aṣáájú ìsìn, ó sì béèrè ohun tí wọ́n máa fún òun kí òun lè sọ bí wọ́n ṣe máa mú Jésù

ORÍ 115

Ìrékọjá Tí Jésù Máa Ṣe Kẹ́yìn ń sún Mọ́lé

MÁTÍÙ 26:1-5, 14-19 MÁÀKÙ 14:1, 2, 10-16 LÚÙKÙ 22:1-13

  • WỌ́N FÚN JÚDÁSÌ ÌSÌKÁRÍỌ́TÙ LÓWÓ KÓ LÈ DA JÉSÙ

  • MÉJÌ LÁRA ÀWỌN ỌMỌ Ẹ̀YÌN JÉSÙ ṢÈTÒ ÌRÉKỌJÁ

Jésù ti dáhùn ìbéèrè tí mẹ́rin lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bi í nípa àmì tó máa fi hàn pé ó ti wà níhìn-ín àti àmì ìparí ètò àwọn nǹkan. Ó sì ti parí ọ̀rọ̀ tó ń bá wọn sọ lórí Òkè Ólífì.

Nísàn 11 ò dẹrùn rárá fún wọn torí àtàárọ̀ ni wọ́n ti ń sọ̀rọ̀, á sì ti rẹ gbogbo wọn! Ó lè jẹ́ ìgbà tí wọ́n ń pa dà sí Bẹ́tánì lọ sùn ni Jésù sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé: “Ẹ mọ̀ pé ní ọjọ́ méjì òní, Ìrékọjá máa wáyé, a sì máa fa Ọmọ èèyàn léni lọ́wọ́, kí wọ́n lè kàn án mọ́gi.”—Mátíù 26:2.

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ nìkan ni wọ́n jọ wà lọ́jọ́ kejì, ìyẹn lọ́jọ́ Wednesday. Lọ́jọ́ Tuesday, Jésù ti bá àwọn aṣáájú ẹ̀sìn wí, ó sì ti tú àṣírí wọn lójú gbogbo èèyàn. Èyí wá mú kàwọn aṣáájú ẹ̀sìn yẹn máa wá bí wọ́n á ṣe pa á. Torí náà, Jésù ò jẹ́ káwọn èèyàn mọ ibi tóun wà ní Nísàn 12 kí nǹkan kan má bàa dí i lọ́wọ́ láti ṣe ayẹyẹ Ìrékọjá nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kejì, ìyẹn ní Nísàn 14.

Àmọ́ kó tó dìgbà Ìrékọjá yẹn, ọkàn àwọn olórí àlùfáà àtàwọn àgbà ọkùnrin ò balẹ̀. Ṣe ni wọ́n kóra jọ sínú àgbàlá Káyáfà àlùfáà àgbà. Kí ni wọ́n fẹ́ ṣe? Inú ló ń bí wọn torí pé Jésù ti ń tú àṣírí wọn. Torí ẹ̀ ni wọ́n ṣe ń gbìmọ̀ pọ̀ láti “fi ọgbọ́n àrékérekè mú Jésù, kí wọ́n sì pa á.” Báwo ni wọ́n ṣe máa mú un, ìgbà wo ni wọ́n á sì rí i mú? Wọ́n ní: “Kì í ṣe nígbà àjọyọ̀, kí ariwo má bàa sọ láàárín àwọn èèyàn.” (Mátíù 26:4, 5) Ẹ̀rù ń bà wọ́n torí ọ̀pọ̀ èèyàn ló fẹ́ràn Jésù.

Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn yẹn ń sọ̀rọ̀ nípa bí wọ́n ṣe máa rí Jésù mú, ẹnu èyí ni wọ́n wà tí àlejò kan fi wọlé. Ló bá di Júdásì Ìsìkáríọ́tù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù. Sátánì ti fi sí i lọ́kàn pé kó dalẹ̀ Ọ̀gá rẹ̀! Júdásì bi wọ́n pé: “Kí lẹ máa fún mi, kí n lè fà á lé yín lọ́wọ́?” (Mátíù 26:15) Ni inú àwọn aṣáájú ẹ̀sìn yẹn bá dùn, “wọ́n sì gbà láti fún un ní owó fàdákà.” (Lúùkù 22:5) Èló ni wọ́n fẹ́ fún un? Tayọ̀tayọ̀ ni wọ́n fi sọ pé àwọn á fún un ní ọgbọ̀n (30) ẹyọ fàdákà. Ọgbọ̀n (30) ṣékélì sì ni iye owó ẹrú kan. (Ẹ́kísódù 21:32) Ohun táwọn aṣáájú ẹ̀sìn ṣe yìí fi hàn pé Jésù ò jọ wọ́n lójú rárá. Ni Júdásì bá bẹ̀rẹ̀ sí í “wá ìgbà tó máa dáa jù láti fà á lé wọn lọ́wọ́ níbi tí kò sí èrò.”—Lúùkù 22:6.

Ìrọ̀lẹ́ Wednesday ni Nísàn 13 bẹ̀rẹ̀, ọjọ́ yìí ló pé ọjọ́ mẹ́fà tí Jésù ti wà ní Bẹ́tánì, alẹ́ ọjọ́ yẹn ló sì máa lò kẹ́yìn níbẹ̀. Tílẹ̀ bá mọ́, wọ́n á ní láti parí ètò tí wọ́n ń ṣe fún Ìrékọjá. Wọ́n máa nílò ọmọ àgùntàn kan tí wọ́n á pa, tí wọ́n á sì yan lódindi nírọ̀lẹ́ Nísàn 14. Ibo ni wọ́n á ti jẹ Ìrékọjá yìí, ta ló sì máa ṣètò ẹ̀? Jésù ò tíì sọ bó ṣe máa rí fún wọn. Torí náà, Júdásì ò tíì lè sọ bí ìrìn Jésù ṣe máa rí fáwọn olórí àlùfáà yẹn.

Pétérù àti Jòhánù tẹ̀ lé ọkùnrin kan tó ru ìṣà omi

Bẹ́tánì ni Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn ṣì wà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ bó ṣe ń dọwọ́ ọ̀sán lọ́jọ́ Thursday ni Jésù rán Pétérù àti Jòhánù níṣẹ́, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ lọ pèsè Ìrékọjá sílẹ̀ fún wa ká lè jẹ ẹ́.” Wọ́n bi í pé: “Ibo lo fẹ́ ká pèsè rẹ̀ sí?” Jésù sọ pé: “Tí ẹ bá ti wọnú ìlú náà, ọkùnrin kan tó ru ìṣà omi máa pàdé yín. Ẹ tẹ̀ lé e lọ sínú ilé tó bá wọ̀. Kí ẹ sì sọ fún ẹni tó ni ilé náà pé, ‘Olùkọ́ ní ká bi ọ́ pé: “Ibo ni yàrá àlejò wà, tí èmi àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn mi ti lè jẹ Ìrékọjá?”’ Ọkùnrin yẹn sì máa fi yàrá ńlá kan hàn yín lókè, tó ti ní àwọn ohun tí a nílò. Ẹ ṣètò rẹ̀ síbẹ̀.”—Lúùkù 22:8-12.

Ó dájú pé ọ̀kan lára àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ló ni ilé yẹn. Ó sì ṣeé ṣe kó ti máa retí pé Jésù á fẹ́ lo ilé òun fún Ìrékọjá. Torí náà, nígbà táwọn ọmọ ẹ̀yìn méjèèjì dé Jerúsálẹ́mù, ohun tí Jésù sọ pé wọ́n máa rí gẹ́lẹ́ ni wọ́n rí. Làwọn méjèèjì bá pa ọmọ àgùntàn náà, tí wọ́n sì yan án. Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n ṣètò ohun tó kù tí wọ́n máa fi ṣe Ìrékọjá náà.

  • Kí ni Jésù ṣe ní ọjọ́ Wednesday Nísàn 12, kí sì nìdí?

  • Kí nìdí tí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn fi pàdé pọ̀, kí sì nìdí tí Júdásì fi lọ rí wọn?

  • Àwọn wo ni Jésù rán lọ sí Jerúsálẹ́mù lọ́jọ́ Thursday, kí ni wọ́n sì ṣe?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́