ORÍ 117
Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa
MÁTÍÙ 26:21-29 MÁÀKÙ 14:18-25 LÚÙKÙ 22:19-23 JÒHÁNÙ 13:18-30
Ọ̀DÀLẸ̀ NI JÚDÁSÌ
JÉSÙ DÁ OÚNJẸ ALẸ́ OLÚWA SÍLẸ̀
Ó ti ń di ọwọ́ ìrọ̀lẹ́, ṣáájú àsìkò yẹn ni Jésù ti kọ́ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ nípa ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ nígbà tó fọ ẹsẹ̀ wọn. Ní báyìí, bóyá lẹ́yìn tí wọ́n jẹ Ìrékọjá tán, ó mẹ́nu ba àsọtẹ́lẹ̀ kan tí Dáfídì sọ, ó ní: “Ẹni tó wà ní àlàáfíà pẹ̀lú mi, tí mo fọkàn tán, ẹni tí a jọ ń jẹun, ti jìn mí lẹ́sẹ̀.” Lẹ́yìn náà, ó sọ pé: “Ọ̀kan nínú yín máa dà mí.”—Sáàmù 41:9; Jòhánù 13:18, 21.
Làwọn àpọ́sítélì rẹ̀ bá ń wo ara wọn, wọ́n sì ń bi í pé: “Olúwa, èmi kọ́ o, àbí èmi ni?” Kódà Júdásì Ìsìkáríọ́tù náà béèrè. Torí pé Jòhánù ló jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ Jésù, Pétérù ní kí Jòhánù bi Jésù pé ta ló máa dà á. Jòhánù wá fẹ̀yìn ti àyà Jésù, ó sì bi í pé: “Olúwa, ta ni?”—Mátíù 26:22; Jòhánù 13:25.
Jésù dáhùn pé: “Ẹni tí mo bá fún ní búrẹ́dì tí mo kì bọ inú abọ́ ni.” Jésù wá mú búrẹ́dì nínú abọ́ tó wà lórí tábìlì, ó sì nà án sí Júdásì. Lẹ́yìn náà, Jésù sọ pé: “Ọmọ èèyàn ń lọ, bí a ṣe kọ ọ́ nípa rẹ̀, àmọ́ ọkùnrin tí a tipasẹ̀ rẹ̀ fi Ọmọ èèyàn léni lọ́wọ́ gbé! Ì bá sàn fún ọkùnrin náà ká ní wọn ò bí i.” (Jòhánù 13:26; Mátíù 26:24) Ni Sátánì bá wọnú Júdásì. Ó ṣe tán, èrò burúkú ti wà lọ́kàn ẹ̀ tẹ́lẹ̀, ó wá túbọ̀ fi ara ẹ̀ fún Èṣù láti ṣe ohun tó fẹ́, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ di “ọmọ ìparun.”—Jòhánù 6:64, 70; 12:4; 17:12.
Jésù sọ fún un pé: “Tètè ṣe ohun tí ò ń ṣe kíákíá.” Torí pé ọwọ́ Júdásì ni àpótí owó máa ń wà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó kù rò pé ṣe ni Jésù ń sọ fún un pé: “‘Ra àwọn nǹkan tí a máa fi ṣe àjọyọ̀ náà’ tàbí pé kó fún àwọn aláìní ní nǹkan.” (Jòhánù 13:27-30) Àmọ́ ṣe ni Júdásì lọ wá bó ṣe máa da Jésù.
Lálẹ́ ọjọ́ yẹn kan náà, Jésù dá ètò oúnjẹ alẹ́ tuntun kan sílẹ̀ bíi ti ayẹyẹ Ìrékọjá. Ó mú búrẹ́dì kan, ó gbàdúrà, ó bù ú, ó sì fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ kí wọ́n jẹ ẹ́. Ó wá sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ara mi, tí a máa fúnni nítorí yín. Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.” (Lúùkù 22:19) Àwọn àpọ́sítélì yẹn gbé búrẹ́dì náà yí ká láàárín ara wọn, wọ́n sì jẹ ẹ́.
Lẹ́yìn ìyẹn, Jésù mú ife wáìnì kan, ó gbàdúrà, ó sì gbé e fún wọn kí wọ́n gbé e yí ká láàárín ara wọn. Gbogbo wọn mu wáìnì náà, Jésù wá sọ pé: “Ife yìí túmọ̀ sí májẹ̀mú tuntun tí a fi ẹ̀jẹ̀ mi dá, tí a máa dà jáde nítorí yín.”—Lúùkù 22:20.
Ṣe ni Jésù fi ohun tó ṣe yẹn sọ báwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ á ṣe máa rántí ikú rẹ̀ lọ́dọọdún ní Nísàn 14. Èyí á sì máa rán wọn létí ohun tí Jésù àti Baba rẹ̀ ṣe kí àwọn tó bá nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run lè bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Ohun tó ṣe yẹn ju ohun tí Ìrékọjá ṣe fáwọn Júù lọ, gbogbo èèyàn ló kàn, tí wọ́n bá ṣáà ti nígbàgbọ́ wọ́n máa gba òmìnira lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú.
Jésù sọ pé wọ́n ‘máa da ẹ̀jẹ̀ òun jáde nítorí ọ̀pọ̀ èèyàn, kí wọ́n lè rí ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀.’ Àwọn àpọ́sítélì Jésù tó jẹ́ olóòótọ́ àtàwọn èèyàn míì wà lára àwọn tó máa rí ìdáríjì gbà. Àwọn ló máa wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú Ìjọba Baba rẹ̀.—Mátíù 26:28, 29.