ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • jy orí 135 ojú ìwé 306-ojú ìwé 307 ìpínrọ̀ 5
  • Jésù Fara Han Ọ̀pọ̀ Èèyàn Lẹ́yìn Tó Jíǹde

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jésù Fara Han Ọ̀pọ̀ Èèyàn Lẹ́yìn Tó Jíǹde
  • Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Awọn Ifarahan Siwaju Sii
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
  • Awọn Ifarahan Jesu Siwaju Sii
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Jésù Wọnú Yàrá Kan Tí Wọ́n Tì Pa
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • Jésù Jíǹde!
    Kí Ló Wà Nínú Bíbélì?
Àwọn Míì
Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
jy orí 135 ojú ìwé 306-ojú ìwé 307 ìpínrọ̀ 5
Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó yọ sí Tọ́másì

ORÍ 135

Jésù Fara Han Ọ̀pọ̀ Èèyàn Lẹ́yìn Tó Jíǹde

LÚÙKÙ 24:13-49 JÒHÁNÙ 20:19-29

  • JÉSÙ YỌ SÁWỌN ỌMỌ Ẹ̀YÌN LÓJÚ Ọ̀NÀ Ẹ́MÁỌ́SÌ

  • Ó ṢÀLÀYÉ ÌWÉ MÍMỌ́ FÁWỌN ỌMỌ Ẹ̀YÌN RẸ̀ LÉRALÉRA

  • TỌ́MÁSÌ Ò ṢIYÈMÉJÌ MỌ́

Ní Sunday, Nísàn 16, ara àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ò yá gágá, torí ohun tó ṣẹlẹ̀ níbi tí wọ́n sin Jésù sí ò yé wọn. (Mátíù 28:9, 10; Lúùkù 24:11) Nígbà tó yá, Kíléópà àti ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn kúrò ní Jerúsálẹ́mù, wọ́n ń lọ sí Ẹ́máọ́sì, wọ́n máa rin nǹkan bíi kìlómítà mọ́kànlá (11) kí wọ́n tó débẹ̀.

Bí wọ́n ṣe ń lọ, wọ́n jọ ń sọ àwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀. Lẹnì kan bá rìn bá wọn, ó sì bi wọ́n pé: “Àwọn ọ̀rọ̀ wo lẹ̀ ń bá ara yín fà bí ẹ ṣe ń rìn lọ?” Kíléópà dáhùn pé: “Ṣé àjèjì tó ń dá gbé ní Jerúsálẹ́mù ni ọ́ ni, tó ò fi mọ àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ lẹ́nu ọjọ́ mélòó kan yìí?” Ẹni yẹn wá béèrè pé: “Àwọn nǹkan wo?”—Lúùkù 24:17-19.

Wọ́n ní: “Àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí Jésù ará Násárẹ́tì, . . . àwa ń retí pé ọkùnrin yìí ni ẹni tó máa gba Ísírẹ́lì sílẹ̀.”—Lúùkù 24:19-21.

Kíléópà àti ẹnì kejì rẹ̀ wá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ yẹn. Wọ́n sọ fún un pé àwọn obìnrin kan lọ síbi tí wọ́n sin Jésù sí, àmọ́ wọn ò bá òkú rẹ̀ níbẹ̀. Wọ́n tún sọ pé àwọn obìnrin yẹn rí ohun àrà kan tó ṣẹlẹ̀, wọ́n rí àwọn áńgẹ́lì tó sọ fún wọn pé Jésù ti jíǹde. Nígbà táwọn míì sì lọ yẹ ibojì náà wò, wọ́n “bá ibẹ̀ bí àwọn obìnrin náà ṣe sọ gẹ́lẹ́.”—Lúùkù 24:24.

Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn ò yé àwọn ọmọ ẹ̀yìn méjì yìí rárá. Ni ọkùnrin yẹn bá tọ́ wọn sọ́nà, ó sì tún èrò wọn ṣe, ó fi ìdánilójú sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin aláìlóye, tí ọkàn yín ò tètè gba gbogbo ohun tí àwọn wòlíì sọ gbọ́! Ṣé kò pọn dandan kí Kristi jìyà àwọn nǹkan yìí, kó sì wọnú ògo rẹ̀ ni?” (Lúùkù 24:25, 26) Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàlàyé oríṣiríṣi nǹkan tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa Kristi.

Nígbà tó yá, àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta dé ìtòsí Ẹ́máọ́sì. Ọ̀rọ̀ tí ọkùnrin yẹn ń sọ ń dùn mọ́ àwọn méjèèjì, ni wọ́n bá sọ fún un pé: “Dúró sọ́dọ̀ wa, torí ó ti ń di ọwọ́ alẹ́, ọjọ́ sì ti lọ.” Ó gbà láti dúró, wọ́n sì jọ jẹun. Bí wọ́n ṣe fẹ́ jẹun, ọkùnrin náà gbàdúrà, ó bu búrẹ́dì, ó sì fún wọn. Bí wọ́n ṣe dá a mọ̀ nìyẹn pé Jésù ni, ló bá pòórá. (Lúùkù 24:29-31) Ó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá dá wọn lójú pé Jésù ti jíǹde!

Inú àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà dùn, wọ́n ń sọ bó ṣe rí lára wọn, wọ́n ní: “Àbí ẹ ò rí i bí ọkàn wa ṣe ń jó fòfò nínú wa bó ṣe ń bá wa sọ̀rọ̀ lójú ọ̀nà, tó ń ṣàlàyé Ìwé Mímọ́ fún wa ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́?” (Lúùkù 24:32) Kíá ni wọ́n pa dà sí Jerúsálẹ́mù kí wọ́n lè ròyìn ohun tó ṣẹlẹ̀ fáwọn àpọ́sítélì, àmọ́ wọ́n tún rí àwọn míì lọ́dọ̀ wọn. Kí Kíléópà àti èkejì rẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ sí í ròyìn ohun tí wọ́n rí, wọ́n gbọ́ táwọn yòókù sọ pé: “Ní tòótọ́, a ti gbé Olúwa dìde, ó sì fara han Símónì!” (Lúùkù 24:34) Àwọn náà wá sọ bí Jésù ṣe fara hàn wọ́n. Wọ́n jẹ́rìí sí i pé Jésù ti jíǹde lóòótọ́.

Bí Jésù tún ṣe yọ sí wọn lójijì nìyẹn! Lẹ̀rù bá ba gbogbo wọn! Ó yà wọ́n lẹ́nu gan-an torí pé wọ́n ti tilẹ̀kùn pa. Ohun tó sì jẹ́ kí wọ́n tilẹ̀kùn ni pé ẹ̀rù àwọn Júù ń bà wọ́n. Àmọ́ Jésù rèé láàárín wọn yìí. Ó wá fi ohùn tútù sọ fún wọn pé: “Àlàáfíà fún yín o.” Àmọ́ ẹ̀rù ń bà wọ́n, ‘wọ́n rò pé ẹ̀mí làwọn ń rí,’ ohun tí wọ́n ń rò tẹ́lẹ̀ náà sì nìyẹn.—Lúùkù 24:36, 37; Mátíù 14:25-27.

Kí Jésù lè jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé wọn ò rí ìran abàmì , pé òun gangan ni wọ́n rí, ó fi ọwọ́ àti ẹsẹ̀ rẹ̀ hàn wọ́n, ó ní: “Kí ló dé tí ọkàn yín ò balẹ̀, kí sì nìdí tí ẹ fi bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyèméjì lọ́kàn yín? Ẹ wo ọwọ́ mi àti ẹsẹ̀ mi, kí ẹ lè mọ̀ pé èmi náà ni; ẹ fọwọ́ kàn mí kí ẹ lè rí i, torí pé ẹ̀mí ò ní ẹran ara àti egungun bí ẹ ṣe rí i pé èmi ní.” (Lúùkù 24:36-39) Lóòótọ́, inú wọn dùn gan-an, ẹnu sì yà wọ́n, àmọ́ wọ́n ṣì ń lọ́ra láti gbà gbọ́.

Jésù tún ṣe nǹkan míì kó lè jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òun gangan ni. Ó bi wọ́n pé: “Ṣé ẹ ní nǹkan jíjẹ níbẹ̀?” Wọ́n fún un ní ẹja yíyan kan, ó sì jẹ ẹ́. Ó wá sọ pé: “Àwọn ọ̀rọ̀ tí mo bá yín sọ nìyí, nígbà tí mo ṣì wà lọ́dọ̀ yín [kí n tó kú], pé gbogbo ohun tí a kọ nípa mi nínú Òfin Mósè àti nínú ìwé àwọn Wòlíì àti Sáàmù gbọ́dọ̀ ṣẹ.”—Lúùkù 24:41-44.

Jésù ti ṣàlàyé ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ fún Kíléópà àti èkejì rẹ̀, ó tún wá ṣàlàyé fún gbogbo àwọn tó kóra jọ síbẹ̀ pé: “Ohun tí a kọ nìyí: pé Kristi máa jìyà, ó sì máa dìde láàárín àwọn òkú ní ọjọ́ kẹta, àti pé ní gbogbo orílẹ̀-èdè, bẹ̀rẹ̀ láti Jerúsálẹ́mù, a máa wàásù ní orúkọ rẹ̀ pé kí àwọn èèyàn ronú pìwà dà kí wọ́n lè rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ máa jẹ́ ẹlẹ́rìí àwọn nǹkan yìí.”—Lúùkù 24:46-48.

Fún ìdí kan, Tọ́másì ò sí níbẹ̀ lọ́jọ́ yẹn. Láwọn ọjọ́ tó tẹ̀ lé e, ṣe làwọn yòókù fayọ̀ sọ fún un pé: “A ti rí Olúwa!” Àmọ́ Tọ́másì sọ pé: “Láìjẹ́ pé mo rí àpá ìṣó ní ọwọ́ rẹ̀, tí mo ki ìka mi bọ àpá ìṣó náà, tí mo sì ki ọwọ́ mi bọ ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, mi ò ní gbà gbọ́ láé.”—Jòhánù 20:25.

Lẹ́yìn ọjọ́ kẹjọ, àwọn ọmọ ẹ̀yìn tún pàdé nínú ilé kan, wọ́n tilẹ̀kùn pa, àmọ́ Tọ́másì wà níbẹ̀ lọ́tẹ̀ yìí. Ni Jésù bá tún yọ sí wọn, ó sì kí wọn pé: “Àlàáfíà fún yín o.” Jésù wá yíjú sí Tọ́másì, ó ní: “Fi ìka rẹ síbí, kí o sì wo ọwọ́ mi, ki ọwọ́ rẹ bọ ẹ̀gbẹ́ mi, kí o má sì ṣiyèméjì mọ́, àmọ́ kí o gbà gbọ́.” Ni Tọ́másì bá kígbe pé: “Olúwa mi àti Ọlọ́run mi!” (Jòhánù 20:26-28) Ní báyìí, ó ti wá dá Tọ́másì lójú pé Jésù ti jíǹde, ó sì ti di ẹ̀dá ẹ̀mí tó jẹ́ aṣojú Jèhófà Ọlọ́run.

Jésù sọ pé: “Ṣé o ti wá gbà gbọ́ torí pé o rí mi? Aláyọ̀ ni àwọn tí kò rí, síbẹ̀ tí wọ́n gbà gbọ́.”—Jòhánù 20:29.

  • Kí ni ọkùnrin kan béèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn méjì tó ń lọ sí Ẹ́máọ́sì?

  • Kí ló mú kí ọkàn àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà máa jó fòfò?

  • Nígbà tí Kíléópà àti èkejì rẹ̀ pa dà sí Jerúsálẹ́mù, ìròyìn ayọ̀ wo ni wọ́n gbọ́, kí ló sì ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà?

  • Kí ló mú kó dá Tọ́másì lójú pé Jésù ti jíǹde?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́