ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 4/1 ojú ìwé 14-15
  • Awọn Ifarahan Jesu Siwaju Sii

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Awọn Ifarahan Jesu Siwaju Sii
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Awọn Ifarahan Siwaju Sii
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
  • Jésù Fara Han Ọ̀pọ̀ Èèyàn Lẹ́yìn Tó Jíǹde
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Jésù Wọnú Yàrá Kan Tí Wọ́n Tì Pa
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • Jésù Jíǹde!
    Kí Ló Wà Nínú Bíbélì?
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 4/1 ojú ìwé 14-15

Igbesi-aye ati Iṣẹ-ojiṣẹ Jesu

Awọn Ifarahan Jesu Siwaju Sii

ỌKAN awọn ọmọ-ẹhin ṣi rẹwẹsi sibẹ. Wọn ko loye ijẹpataki iboji ṣiṣofo naa, bẹẹ si ni wọn kò gba irohin awọn obinrin naa gbọ́. Nigba ti o ya ni ọjọ Sunday, Kleopa ati ọmọ-ẹhin miiran fi Jerusalẹmu silẹ lọ si Ẹmausi, nibi ti o jinna tó nǹkan bii ibusọ meje.

Ní oju ọna, nigba ti wọn njiroro awọn iṣẹlẹ ọjọ naa, ajeji kan darapọ mọ́ wọn. O beere pe, “Ki ni kókó ọrọ wọnyi ti ẹ njiyan le lori laaarin araayin bi ẹ ti nrin lọ?”

Awọn ọmọ-ẹhin naa duro, oju wọn rẹwẹsi, Kleopa si fesipada pe: “Iwọ ha ngbe gẹgẹ bi atipo ní iwọ nikan ní Jerusalẹmu nipa bẹẹ tí o kò mọ awọn nǹkan ti wọn ti ṣẹlẹ ninu rẹ̀ ni awọn ọjọ wọnyi?”

O beere pe, “Awọn nǹkan wo?”

Wọn dahun pe, “Awọn nǹkan nipa Jesu ti Nasarẹti.” ‘Awọn olori alufaa wa ati awọn oluṣakoso fi í lé idajọ iku lọwọ tí wọn sì kàn án mọ́gi. Ṣugbọn awa nreti pe [ọkunrin] yii ni ẹni naa ti a kadara lati dá Israẹli nídè.’

Kleopa ati alabaakẹgbẹ rẹ̀ ṣalaye awọn iṣẹlẹ ayanilẹnu ọjọ naa—irohin nipa iran ti o ga ju ti ẹda lọ ti awọn angẹli ati iboji ṣiṣofo—ṣugbọn lẹhin naa wọn jẹwọ iṣekayefi wọn nipa itumọ awọn nǹkan wọnyi. Ajeji naa ba wọn wi kikankikan pe: “Óò ẹyin alailoye ti ẹ si lọra ni ọkan aya lati gba gbogbo ohun ti awọn wolii sọ gbọ, ko ha jẹ́ ọranyan fun Kristi lati jiya nǹkan wọnyi ki o si wọ inú ogo rẹ̀?” Lẹhin naa oun tumọ awọn ayọka lati inú ọrọ ẹsẹ iwe mímọ́ ti o niiṣe pẹlu Kristi fun wọn.

Nikẹhin wọn de eti Ẹmausi, ajeji naa ṣe bii ẹni ti o ṣi nba irin-àjò niṣo. Ni fifẹ lati gbọ sii, awọn ọmọ-ẹhin naa rọ̀ ọ́ pe: “Duro pẹlu wa, nitori o ti nsunmọ alẹ ọjọ si ti rọ̀.” Nitori naa o duro fun ounjẹ. Bi o ti gbadura ti o si bu akara ti o si nà án si wọn, wọn mọ̀ daju pe oun niti gidi ni Jesu ti o gbé ara ẹda eniyan wọ. Ṣugbọn lẹhin naa oun nù mọ́ wọn loju.

Nisinsinyi wọn loye idi ti ajeji naa fi mọ pupọ tobẹẹ! Wọn beere pe, “Ọkan aya wa kò ha gbina bi o ti nba wa sọrọ ni oju ọna, ti o si nṣi awọn Iwe Mimọ payá fun wa ni kikun?” Laijafara, wọn dide wọn sì yara pada lọ si Jerusalẹmu, nibi ti wọn ti ri awọn apọsteli ati awọn wọnni tí wọn pejọ pẹlu wọn. Ṣaaju ki Kleopa ati ẹnikeji rẹ̀ tó le sọ ohun kan, awọn yooku ti rohin pẹlu irusoke pe: “Niti tootọ a ti ji Oluwa dide o si fi ara han Simoni!” Lẹhin naa awọn meji naa rohin bi Jesu ti farahan wọn pẹlu. Eyi jẹ́ igba kẹrin laaarin ọjọ naa ti oun ti farahan awọn ẹni ọtọọtọ laaarin awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀.

Bi o tilẹ jẹ pe awọn ilẹkun ni a tipa nitori pe awọn ọmọ-ẹhin wà ninu ibẹru awọn Juu, lojiji Jesu wá farahan ni ìgbà karun-un. O duro laaarin wọn gan-an o si wipe: “Alaafia fun yin.” A dáyà já wọn, ni rironu pe wọn ti ri ẹmi kan. Nitori naa, ni ṣiṣalaye pe oun kii ṣe ìran abàmì, Jesu wipe: “Eeṣe ti ẹ fi ńdààmú, eesitiṣe ti iyemeji fi dide ninu ọkan-aya yin? Ẹ wo awọn ọwọ́ mi ati awọn ẹsẹ̀ mi, pe emi funraami ni; ẹ fọwọba mi ki ẹ si ri, nitori ẹmi kò ni ẹran ati egungun gan-an gẹgẹ bi ẹ ti ri pe emi ni.” Sibẹ, wọn lọra lati gbagbọ nitori pe wiwalaaye rẹ̀ dabi àlá.

Lati ran wọn lọwọ lati loye pe oun ni Jesu nitootọ, o beere pe: “Ẹ ni ohun kan nibẹ lati jẹ bí?” Lẹhin titẹwọgba ègé ẹja sísè ti o si njẹ ẹ, o bẹrẹ sii kọ wọn, ni wiwi pe: “Iwọnyi ni ọrọ mi ti mo sọ fun yin nigba ti mọ ṣi wa pẹlu yin [ṣaaju iku mi], pe gbogbo nǹkan ti a ti kọ sinu ofin Mose ati ninu awọn Wolii ati awọn Saamu nipa mi ni a gbọdọ múṣẹ.”

Nitootọ, ni biba ohun ti o jásí ikẹkọọ Bibeli lọ pẹlu wọn, Jesu kọ wọn pe: “Ni ọ̀nà yii ni a ti kọ ọ́ pe Kristi yoo jiya yoo si dide laaarin awọn oku ni ọjọ kẹta, ati lori ipilẹ orukọ rẹ a o waasu ironupiwada fun idariji ẹṣẹ ninu gbogbo awọn orilẹ-ede—bẹrẹ lati Jerusalẹmu, ẹyin yoo jẹ́ Ẹlẹrii awọn nǹkan wọnyi.”

Fun idi kan Tomasi kò wá si ipade irọlẹ ọjọ Sunday pataki yii. Nitori naa ni awọn ọjọ ti o tẹle e, awọn yooku fi idunnu sọ fun un pe: “Awa ti ri Oluwa!”

Tomasi yarí pe, “Ayafi bi emi ba rí àpá iṣo ni ọwọ rẹ̀ ti mo si ki ika ọwọ mi bọ àpá iṣo naa ti mo si ki ọwọ mi bọ ẹgbẹ rẹ̀, dajudaju emi ki yoo gbagbọ.”

O dara, ni ọjọ mẹjọ lẹhin naa awọn ọmọ-ẹhin tun pade ninu ile. Nisinsinyi Tomasi wà pẹlu wọn. Bi o tilẹ jẹ pe ilẹkun ni a tipa, Jesu duro laaarin wọn lẹẹkansii o si wipe: “Alaafia fun yin.” Lẹhin naa, ni yiyijusi Tomasi, o kesi i pe: “Fi ika ọwọ rẹ sihin-in, si wo o awọn ọwọ mi, si mu ọwọ rẹ ki o si kì í bọ ẹgbẹ mi, ki o si dẹkun jijẹ alaigbagbọ ṣugbọn di onigbagbọ.”

Tomasi ké soke pe, “Oluwa mi ati Ọlọrun mi!”

Jesu beere pe, “Nitori pe iwọ ti ri mi ṣe iwọ ti gbagbọ? Alayọ ni awọn wọnni ti ko rí ti wọn sì gbagbọ.” Luuku 24:11, 13-48; Johanu 20:19-29.

◆ Awọn iwadii wo ni ajeji kan ṣe lọdọ awọn ọmọ-ẹhin meji loju ọna sí Ẹmausi?

◆ Ki ni ajeji naa sọ ti o mu ki ọkan-aya awọn ọmọ-ẹhin gbina ninu wọn?

◆ Bawo ni awọn ọmọ-ẹhin ṣe loye pe Jesu ni ajeji naa?

◆ Nigba ti Kleopa ati ekeji rẹ pada sí Jerusalẹmu, irohin arunisoke wo ni wọn gbọ?

◆ Ifarahan karun un wo ni Jesu ṣe fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, ki ni o si waye lakooko naa?

◆ Ki ni o ṣẹlẹ ni ọjọ kẹjọ lẹhin ifarahan karun un ti Jesu, bawo si ni Tomasi ṣe ni idaniloju nikẹhin pe Jesu ti walaaaye?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́